Est 3:8-15

Est 3:8-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

Hamani si sọ fun Ahaswerusi ọba pe, awọn enia kan fọn kakiri, nwọn si tuka lãrin awọn enia ni gbogbo ìgberiko ijọba rẹ, ofin wọn si yatọ si ti gbogbo enia; bẹ̃ni nwọn kò si pa ofin ọba mọ́; nitorina kò yẹ fun ọba lati da wọn si. Bi o ba wù ọba, jẹ ki a kọwe rẹ̀ pe, ki a run wọn: emi o si wọ̀n ẹgbãrun talenti fadaka fun awọn ti a fi iṣẹ na rán, ki nwọn ki o le mu u wá sinu ile iṣura ọba. Ọba si bọ́ oruka rẹ̀ kuro li ọwọ rẹ̀, o si fi fun Hamani, ọmọ Medata, ara Agagi, ọta awọn Ju. Ọba si wi fun Hamani pe, a fi fadaka na bùn ọ, ati awọn enia na pẹlu, lati fi wọn ṣe bi o ti dara loju rẹ. Nigbana li a pè awọn akọwe ọba ni ọjọ kẹtala, oṣù kini, a si kọwe gẹgẹ bi gbogbo ohun ti Hamani ti pa li aṣẹ fun awọn bãlẹ ọba, ati fun awọn onidajọ ti o njẹ olori gbogbo ìgberiko, ati fun awọn olori olukuluku enia ìgberiko gbogbo, gẹgẹ bi ikọwe rẹ̀, ati fun olukuluku enià gẹgẹ bi ède rẹ̀, li orukọ Ahaswerusi ọba li a kọ ọ, a si fi oruka ọba ṣe edidi rẹ̀. A si fi iwe na rán awọn òjiṣẹ si gbogbo ìgberiko ọba, lati parun, lati pa, ati lati mu ki gbogbo enia Juda, ati ọ̀dọ ati arugbo, awọn ọmọde, ati awọn obinrin ki o ṣegbe ni ọjọ kan, ani li ọjọ kẹtala, oṣù kejila, ti iṣe oṣù Adari, ati lati kó ohun iní wọn fun ijẹ. Ọ̀ran iwe na ni lati paṣẹ ni gbogbo igberiko, lati kede rẹ̀ fun gbogbo enia, ki nwọn ki o le mura de ọjọ na. Awọn ojiṣẹ na jade lọ, nwọn si yara, nitori aṣẹ ọba ni, a si pa aṣẹ na ni Ṣuṣani ãfin. Ati ọba ati Hamani joko lati mu ọti; ṣugbọn ilu Ṣuṣani dãmu.

Est 3:8-15 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà náà ni Hamani lọ bá Ahasu-erusi ọba, ó sọ fún un pé, “Àwọn eniyan kan wà tí wọ́n fọ́n káàkiri ààrin àwọn eniyan ati ní gbogbo agbègbè ìjọba rẹ; òfin wọn kò bá ti gbogbo eniyan mu, wọn kò sì pa àṣẹ ọba mọ́. Kò dára kí o gbà wọ́n láàyè ninu ìjọba rẹ. Bí ó bá dùn mọ́ Kabiyesi ninu, jẹ́ kí àṣẹ kan jáde lọ láti pa wọ́n run. N óo sì gbé ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n talẹnti fadaka fún àwọn tí a bá fi iṣẹ́ náà rán, kí wọ́n gbé e sí ilé ìṣúra ọba.” Ọba bọ́ òrùka àṣẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀, ó fún Hamani, ọmọ Hamedata, ará Agagi, ọ̀tá àwọn Juu. Ọba sọ fún un pé, “Má wulẹ̀ san owó kankan, àwọn eniyan náà wà ní ìkáwọ́ rẹ, lọ ṣe wọ́n bí o bá ti fẹ́.” Ní ọjọ́ kẹtala, oṣù kinni, Hamani pe àwọn akọ̀wé ọba jọ, wọ́n sì kọ gbogbo àṣẹ tí Hamani pa sinu ìwé. Wọ́n fi ìwé náà ranṣẹ sí àwọn gomina agbègbè ati àwọn olórí àwọn eniyan ati sí àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan ati ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn. Wọ́n kọ ìwé náà ní orúkọ ọba, wọ́n sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì rẹ̀. Wọ́n fi àwọn ìwé náà rán àwọn òjíṣẹ́ sí gbogbo agbègbè ọba pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn Juu run, ati kékeré ati àgbà, ati obinrin ati ọmọde ní ọjọ́ kan náà, tíí ṣe ọjọ́ kẹtala oṣù kejila oṣù Adari, kí wọ́n sì kó gbogbo ohun ìní wọn. Wọ́n níláti sọ ohun tí ó wà ninu ìwé náà di òfin ní gbogbo ìgbèríko, kí wọ́n sì sọ fún gbogbo eniyan, kí wọ́n lè múra sílẹ̀ de ọjọ́ náà. Wọ́n pa àṣẹ náà ní Susa tíí ṣe olú-ìlú, àwọn òjíṣẹ́ sì yára mú un lọ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba. Lẹ́yìn náà, Hamani ati ọba jókòó láti mu ọtí, ṣugbọn gbogbo ìlú Susa wà ninu ìdààmú.

Est 3:8-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

Nígbà náà ni Hamani sọ fún ọba Ahaswerusi pé, “Àwọn ènìyàn kan wà tí wọ́n fọ́nká tí wọ́n sì túká ní ara àwọn ènìyàn ní gbogbo àgbáyé ìjọba rẹ̀ tí ìṣe wọn yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn tókù tí wọn kò sì pa òfin ọba mọ́; èyí kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti gbà fún wọn bẹ́ẹ̀. Tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, kí a gbé òfin kan jáde tí yóò pa wọ́n run, èmi yóò sì fi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tálẹ́ǹtì fàdákà sínú ìṣúra ọba fún àwọn ọkùnrin tí wọn o ṣe iṣẹ́ náà.” Nítorí náà, ọba sì bọ́ òrùka èdìdì tí ó wà ní ìka rẹ̀, ó sì fi fún Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, ọ̀tá àwọn Júù. Ọba sọ fún Hamani pé, “Pa owó náà mọ́, kí o sì ṣe ohun tí ó wù ọ́ fún àwọn ènìyàn náà.” Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹtàlá oṣù kìn-ín-ní àkọ́kọ́, wọ́n pe àwọn akọ̀wé ọba jọ. Wọ́n kọ ọ́ ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn gbogbo èyí tí Hamani ti pàṣẹ sí àwọn akọ̀wé ọba, sí baálẹ̀ ìgbèríko kọ̀ọ̀kan àti àwọn ọlọ́lá àwọn onírúurú ènìyàn. A kọ èyí ní orúkọ ọba Ahaswerusi fúnra rẹ̀ ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀. A sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ìgbèríko ọba pẹ̀lú àṣẹ láti parun, láti pa gbogbo àwọn Júù èwe àti àgbà, obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́—ní ọjọ́ kan kí wọn sì parẹ́, ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, oṣù Addari kí a sì kó àwọn ohun ìní wọn. Kí ẹ mú àdàkọ ìwé náà kí a tẹ̀ ẹ́ jáde bí òfin ní gbogbo ìgbèríko kí ó sì di mí mọ̀ fún àwọn ènìyàn ìlú nítorí kí wọ́n le múra fún ọjọ́ náà. Àwọn ìránṣẹ́ náà sì jáde, wọ́n tẹ̀síwájú nípa àṣẹ ọba, ìkéde náà sì jáde ní ilé ìṣọ́ ti Susa. Ọba àti Hamani jókòó wọ́n ń mu, ṣùgbọ́n ìlú Susa wà nínú ìdààmú.