Est 3:8
Est 3:8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Hamani si sọ fun Ahaswerusi ọba pe, awọn enia kan fọn kakiri, nwọn si tuka lãrin awọn enia ni gbogbo ìgberiko ijọba rẹ, ofin wọn si yatọ si ti gbogbo enia; bẹ̃ni nwọn kò si pa ofin ọba mọ́; nitorina kò yẹ fun ọba lati da wọn si.
Pín
Kà Est 3Est 3:8 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni Hamani lọ bá Ahasu-erusi ọba, ó sọ fún un pé, “Àwọn eniyan kan wà tí wọ́n fọ́n káàkiri ààrin àwọn eniyan ati ní gbogbo agbègbè ìjọba rẹ; òfin wọn kò bá ti gbogbo eniyan mu, wọn kò sì pa àṣẹ ọba mọ́. Kò dára kí o gbà wọ́n láàyè ninu ìjọba rẹ.
Pín
Kà Est 3Est 3:8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni Hamani sọ fún ọba Ahaswerusi pé, “Àwọn ènìyàn kan wà tí wọ́n fọ́nká tí wọ́n sì túká ní ara àwọn ènìyàn ní gbogbo àgbáyé ìjọba rẹ̀ tí ìṣe wọn yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn tókù tí wọn kò sì pa òfin ọba mọ́; èyí kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti gbà fún wọn bẹ́ẹ̀.
Pín
Kà Est 3