Est 3:1-5
Est 3:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
LẸHIN nkan wọnyi ni Ahaswerusi ọba gbe Hamani, ọmọ Medata, ara Agagi ga, o si gbe e lekè, o si fi ijoko rẹ̀ lekè gbogbo awọn ijoye ti o wà pẹlu rẹ̀. Gbogbo awọn iranṣẹ ọba, ti nwọn wà li ẹnu ọ̀na ọba, kunlẹ nwọn si wolẹ fun Hamani: nitori ọba ti paṣẹ bẹ̃ nitori rẹ̀. Ṣugbọn Mordekai kò kunlẹ, bẹ̃ni kò si wolẹ fun u. Nigbana ni awọn iranṣẹ ọba, ti nwọn wà li ẹnu ọ̀na ọba, wi fun Mordekai pe, ẽṣe ti iwọ fi nré ofin ọba kọja? O si ṣe, nigbati nwọn wi fun u lojojumọ, ti on kò si gbọ́ ti wọn, nwọn sọ fun Hamani, lati wò bi ọ̀ran Mordekai yio ti le ri: nitori on ti wi fun wọn pe, enia Juda ni on. Nigbati Hamani si ri pe, Mordekai kò kunlẹ, bẹ̃ni kò wolẹ fun on, nigbana ni Hamani kún fun ibinu.
Est 3:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ahasu-erusi ọba gbé Hamani, ọmọ Hamedata, ará Agagi, ga ju gbogbo àwọn ìjòyè yòókù lọ. Gbogbo àwọn olóyè ní ẹnu ọ̀nà ààfin ọba a sì máa foríbalẹ̀ láti bu ọlá fún Hamani, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, ṣugbọn Modekai kò jẹ́ foríbalẹ̀ kí ó bu ọlá fún Hamani. Àwọn olóyè kan ninu wọn bi Modekai léèrè pé, “Kí ló dé tí o fi ń tàpá sí àṣẹ ọba?” Ojoojumọ ni wọ́n ń kìlọ̀ fún un, ṣugbọn kò gbọ́. Nítorí náà, wọ́n lọ sọ fún Hamani, wọ́n fẹ́ mọ̀ bóyá ohun tí Modekai sọ ni yóo ṣẹ, nítorí ó sọ fún wọn pé Juu ni òun. Nígbà tí Hamani rí i pé Modekai kọ̀, kò foríbalẹ̀ fún òun, inú bí i pupọ.
Est 3:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ọba Ahaswerusi dá Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi lọ́lá, ọba gbé e ga, ó si fún un ní àga ọlá tí ó ju ti gbogbo àwọn ọlọ́lá tókù lọ. Gbogbo àwọn ìjòyè ọba tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà ọba wọn kúnlẹ̀ wọ́n sì fi ọlá fun Hamani, nítorí ọba ti pàṣẹ èyí nípa tirẹ̀. Ṣùgbọ́n Mordekai kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún un. Nígbà náà ni àwọn ìjòyè ọba tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà béèrè lọ́wọ́ Mordekai pé, “Èéṣe tí ìwọ kò ṣe pa àṣẹ ọba mọ́.” Ní ojoojúmọ́ ni wọ́n máa n sọ fún un ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, wọ́n sọ fún Hamani nípa rẹ̀ láti wò ó bóyá ó lè gba irú ìwà tí Mordekai ń hù yìí, nítorí tí ó ti sọ fún wọn pé Júù ni òun. Nígbà tí Hamani rí i pé Mordekai kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún òun, ó bínú.