Est 3:1-12
Est 3:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
LẸHIN nkan wọnyi ni Ahaswerusi ọba gbe Hamani, ọmọ Medata, ara Agagi ga, o si gbe e lekè, o si fi ijoko rẹ̀ lekè gbogbo awọn ijoye ti o wà pẹlu rẹ̀. Gbogbo awọn iranṣẹ ọba, ti nwọn wà li ẹnu ọ̀na ọba, kunlẹ nwọn si wolẹ fun Hamani: nitori ọba ti paṣẹ bẹ̃ nitori rẹ̀. Ṣugbọn Mordekai kò kunlẹ, bẹ̃ni kò si wolẹ fun u. Nigbana ni awọn iranṣẹ ọba, ti nwọn wà li ẹnu ọ̀na ọba, wi fun Mordekai pe, ẽṣe ti iwọ fi nré ofin ọba kọja? O si ṣe, nigbati nwọn wi fun u lojojumọ, ti on kò si gbọ́ ti wọn, nwọn sọ fun Hamani, lati wò bi ọ̀ran Mordekai yio ti le ri: nitori on ti wi fun wọn pe, enia Juda ni on. Nigbati Hamani si ri pe, Mordekai kò kunlẹ, bẹ̃ni kò wolẹ fun on, nigbana ni Hamani kún fun ibinu. O si jẹ abùku loju rẹ̀ lati gbe ọwọ le Mordekai nikan; nitori nwọn ti fi awọn enia Mordekai hàn a: nitorina gbogbo awọn Ju ti o wà ni gbogbo ijọba Ahaswerusi, ni Hamani wá ọ̀na lati parun, ani awọn enia Mordekai. Li oṣù kini, eyinì ni oṣù Nisani, li ọdun kejila ijọba Ahaswerusi, nwọn da purimu, eyinì ni, ìbo, niwaju Hamani, lati ọjọ de ọjọ, ati lati oṣù de oṣù lọ ide oṣù kejila, eyinì ni oṣù Adari. Hamani si sọ fun Ahaswerusi ọba pe, awọn enia kan fọn kakiri, nwọn si tuka lãrin awọn enia ni gbogbo ìgberiko ijọba rẹ, ofin wọn si yatọ si ti gbogbo enia; bẹ̃ni nwọn kò si pa ofin ọba mọ́; nitorina kò yẹ fun ọba lati da wọn si. Bi o ba wù ọba, jẹ ki a kọwe rẹ̀ pe, ki a run wọn: emi o si wọ̀n ẹgbãrun talenti fadaka fun awọn ti a fi iṣẹ na rán, ki nwọn ki o le mu u wá sinu ile iṣura ọba. Ọba si bọ́ oruka rẹ̀ kuro li ọwọ rẹ̀, o si fi fun Hamani, ọmọ Medata, ara Agagi, ọta awọn Ju. Ọba si wi fun Hamani pe, a fi fadaka na bùn ọ, ati awọn enia na pẹlu, lati fi wọn ṣe bi o ti dara loju rẹ. Nigbana li a pè awọn akọwe ọba ni ọjọ kẹtala, oṣù kini, a si kọwe gẹgẹ bi gbogbo ohun ti Hamani ti pa li aṣẹ fun awọn bãlẹ ọba, ati fun awọn onidajọ ti o njẹ olori gbogbo ìgberiko, ati fun awọn olori olukuluku enia ìgberiko gbogbo, gẹgẹ bi ikọwe rẹ̀, ati fun olukuluku enià gẹgẹ bi ède rẹ̀, li orukọ Ahaswerusi ọba li a kọ ọ, a si fi oruka ọba ṣe edidi rẹ̀.
Est 3:1-12 Yoruba Bible (YCE)
Ahasu-erusi ọba gbé Hamani, ọmọ Hamedata, ará Agagi, ga ju gbogbo àwọn ìjòyè yòókù lọ. Gbogbo àwọn olóyè ní ẹnu ọ̀nà ààfin ọba a sì máa foríbalẹ̀ láti bu ọlá fún Hamani, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, ṣugbọn Modekai kò jẹ́ foríbalẹ̀ kí ó bu ọlá fún Hamani. Àwọn olóyè kan ninu wọn bi Modekai léèrè pé, “Kí ló dé tí o fi ń tàpá sí àṣẹ ọba?” Ojoojumọ ni wọ́n ń kìlọ̀ fún un, ṣugbọn kò gbọ́. Nítorí náà, wọ́n lọ sọ fún Hamani, wọ́n fẹ́ mọ̀ bóyá ohun tí Modekai sọ ni yóo ṣẹ, nítorí ó sọ fún wọn pé Juu ni òun. Nígbà tí Hamani rí i pé Modekai kọ̀, kò foríbalẹ̀ fún òun, inú bí i pupọ. Nígbà tí ó mọ̀ pé Juu ni, ó kà á sí ohun kékeré láti pa Modekai nìkan, nítorí náà, ó pinnu láti pa gbogbo àwọn Juu tí wọ́n jẹ́ eniyan Modekai run, ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ahasu-erusi. Ní ọdún kejila ìjọba Ahasu-erusi, Hamani pinnu láti yan ọjọ́ tí ó wọ̀, nítorí náà, ní oṣù kinni tíí ṣe oṣù Nisani, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́ gègé tí wọn ń pè ní Purimu, níwájú Hamani láti ọjọ́ dé ọjọ́ ati láti oṣù dé oṣù, títí dé oṣù kejila tíí ṣe oṣù Adari. Nígbà náà ni Hamani lọ bá Ahasu-erusi ọba, ó sọ fún un pé, “Àwọn eniyan kan wà tí wọ́n fọ́n káàkiri ààrin àwọn eniyan ati ní gbogbo agbègbè ìjọba rẹ; òfin wọn kò bá ti gbogbo eniyan mu, wọn kò sì pa àṣẹ ọba mọ́. Kò dára kí o gbà wọ́n láàyè ninu ìjọba rẹ. Bí ó bá dùn mọ́ Kabiyesi ninu, jẹ́ kí àṣẹ kan jáde lọ láti pa wọ́n run. N óo sì gbé ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n talẹnti fadaka fún àwọn tí a bá fi iṣẹ́ náà rán, kí wọ́n gbé e sí ilé ìṣúra ọba.” Ọba bọ́ òrùka àṣẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀, ó fún Hamani, ọmọ Hamedata, ará Agagi, ọ̀tá àwọn Juu. Ọba sọ fún un pé, “Má wulẹ̀ san owó kankan, àwọn eniyan náà wà ní ìkáwọ́ rẹ, lọ ṣe wọ́n bí o bá ti fẹ́.” Ní ọjọ́ kẹtala, oṣù kinni, Hamani pe àwọn akọ̀wé ọba jọ, wọ́n sì kọ gbogbo àṣẹ tí Hamani pa sinu ìwé. Wọ́n fi ìwé náà ranṣẹ sí àwọn gomina agbègbè ati àwọn olórí àwọn eniyan ati sí àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan ati ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn. Wọ́n kọ ìwé náà ní orúkọ ọba, wọ́n sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì rẹ̀.
Est 3:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ọba Ahaswerusi dá Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi lọ́lá, ọba gbé e ga, ó si fún un ní àga ọlá tí ó ju ti gbogbo àwọn ọlọ́lá tókù lọ. Gbogbo àwọn ìjòyè ọba tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà ọba wọn kúnlẹ̀ wọ́n sì fi ọlá fun Hamani, nítorí ọba ti pàṣẹ èyí nípa tirẹ̀. Ṣùgbọ́n Mordekai kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún un. Nígbà náà ni àwọn ìjòyè ọba tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà béèrè lọ́wọ́ Mordekai pé, “Èéṣe tí ìwọ kò ṣe pa àṣẹ ọba mọ́.” Ní ojoojúmọ́ ni wọ́n máa n sọ fún un ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, wọ́n sọ fún Hamani nípa rẹ̀ láti wò ó bóyá ó lè gba irú ìwà tí Mordekai ń hù yìí, nítorí tí ó ti sọ fún wọn pé Júù ni òun. Nígbà tí Hamani rí i pé Mordekai kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún òun, ó bínú. Síbẹ̀ kò mọ irú ènìyàn tí Mordekai jẹ́, ó kẹ́gàn láti pa Mordekai nìkan. Dípò bẹ́ẹ̀ Hamani ń wá láti pa gbogbo ènìyàn Mordekai run, àwọn Júù jákèjádò gbogbo ìjọba Ahaswerusi. Ní ọdún kejìlá ọba Ahaswerusi, ní oṣù kìn-ín-ní, èyí ni oṣù Nisani, wọ́n da puri (èyí tí í ṣe, ìbò) ní iwájú Hamani láti yan ọjọ́ kan àti oṣù, ìbò náà sì wáyé ní oṣù kejìlá, oṣù Addari. Nígbà náà ni Hamani sọ fún ọba Ahaswerusi pé, “Àwọn ènìyàn kan wà tí wọ́n fọ́nká tí wọ́n sì túká ní ara àwọn ènìyàn ní gbogbo àgbáyé ìjọba rẹ̀ tí ìṣe wọn yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn tókù tí wọn kò sì pa òfin ọba mọ́; èyí kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti gbà fún wọn bẹ́ẹ̀. Tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, kí a gbé òfin kan jáde tí yóò pa wọ́n run, èmi yóò sì fi ẹgbàárùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà sínú ìṣúra ọba fún àwọn ọkùnrin tí wọn o ṣe iṣẹ́ náà.” Nítorí náà ọba sì bọ́ òrùka dídán (èdìdì) tí ó wà ní ìka rẹ̀ ó sì fi fún Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, ọ̀tá àwọn Júù. Ọba sọ fún Hamani pé, “pa owó náà mọ́, kí o sì ṣe ohun tí ó wù ọ́ fún àwọn ènìyàn náà.” Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹtàlá oṣù kìn-ín-ní àkọ́kọ́, wọ́n pe àwọn akọ̀wé ọba jọ. Wọ́n kọ ọ́ ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn gbogbo èyí tí Hamani ti pàṣẹ sí àwọn akọ̀wé ọba, sí baálẹ̀ ìgbèríko kọ̀ọ̀kan àti àwọn ọlọ́lá àwọn onírúurú ènìyàn. A kọ èyí ní orúkọ ọba Ahaswerusi fúnrarẹ̀ ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀.