Est 2:7-11
Est 2:7-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
On li o si tọ́ Hadassa dagba, eyini ni Esteri, ọmọbinrin arakunrin baba rẹ̀: nitori kò ni baba, bẹ̃ni kò si ni iya, wundia na si li ẹwà, o si dara lati wò; ẹniti, nigbati baba ati iya rẹ̀ ti kú tan, Mordekai mu u ṣe ọmọbinrin ontikalarẹ̀, O si ṣe, nigbati a gbọ́ ofin ọba, ati aṣẹ rẹ̀, nigbati a si ṣà ọ̀pọlọpọ wundia jọ si Ṣuṣani ãfin, si ọwọ Hegai, a si mu Esteri wá si ile ọba pẹlu si ọwọ Hegai, olutọju awọn obinrin. Wundia na si wù u, o si ri ojurere gbà lọdọ rẹ̀; o si yara fi elo ìwẹnumọ́ rẹ̀ fun u, ati ipin onjẹ ti o jẹ tirẹ̀, ati obinrin meje ti a yàn fun u lati ile ọba wá: on si ṣi i lọ ati awọn wundia rẹ̀ si ibi ti o dara jù ni ile awọn obinrin. Esteri kò ti ifi awọn enia rẹ̀, tabi awọn ibatan rẹ̀ hàn; nitori Mordekai paṣẹ fun u ki o máṣe fi hàn. Mordekai a si ma rìn lojojumọ niwaju àgbala ile awọn obinrin, lati mọ̀ alafia Esteri, ati bi yio ti ri fun u.
Est 2:7-11 Yoruba Bible (YCE)
Modekai ń tọ́ ọmọbinrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hadasa tabi Ẹsita. Ọmọ yìí jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ṣugbọn kò ní òbí mọ́. Ọmọ náà lẹ́wà gidigidi. Modekai mú un sọ́dọ̀ bí ọmọ ara rẹ̀, lẹ́yìn tí baba ati ìyá rẹ̀ ti kú. Nígbà tí ọba pàṣẹ, tí wọ́n kéde rẹ̀, tí wọ́n sì mú ọpọlọpọ wundia wá sí ààfin, ní Susa, ní abẹ́ ìtọ́jú Hegai, tí ń tọ́jú àwọn ayaba, Ẹsita wà pẹlu wọn ní ààfin ní abẹ́ ìtọ́jú rẹ̀. Ẹsita wú Hegai lórí, inú rẹ̀ dùn sí i pupọ. Ó fún un ní nǹkan ìpara ati oúnjẹ kíákíá. Ó tún fún un ní àwọn ọmọbinrin meje ninu àwọn iranṣẹbinrin tí wọ́n wà ní ààfin. Ó fún Ẹsita ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ ní ibi tí ó dára jùlọ ní ibi tí àwọn ayaba ń gbé. Ẹsita kò sọ inú ẹ̀yà tí òun ti wá, tabi ìdílé rẹ̀, fún ẹnikẹ́ni nítorí pé Modekai ti kìlọ̀ fún un pé kí ó má ṣe sọ nǹkankan nípa rẹ̀. Lojoojumọ ni Modekai máa ń rìn sókè sódò níwájú àgbàlá ibi tí àwọn ayaba ń gbé, láti bèèrè alaafia Ẹsita, ati bí ó ti ń ṣe sí.
Est 2:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mordekai ní arákùnrin kan ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hadassa, ẹni tí ó tọ́ dàgbà nítorí tí kò ní baba bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ìyá. Obìnrin yìí, ẹni tí a tún mọ̀ sí Esteri, ó dára ó sì lẹ́wà, Mordekai mú u gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ nígbà tí baba àti ìyá rẹ̀ ti kú. Nígbà tí a ti kéde òfin àti àṣẹ ọba, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọbìnrin ni a kó wá sí ilé ti ìṣọ́ Susa, sí abẹ́ ìtọ́jú Hegai. A sì mú Esteri náà wá sí ààfin ọba pẹ̀lú, a fà á lé Hegai lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ alábojútó ilé àwọn obìnrin. Ọmọbìnrin náà sì wù ú, ó sì rí ojúrere rẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó pèsè àwọn ohun tí ó dára àti oúnjẹ pàtàkì fún un. Ó sì yan àwọn ìránṣẹ́bìnrin wúńdíá méje láti ààfin ọba òun àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà lọ sí ibi tí ó dára jù nínú ilé àwọn obìnrin. Esteri kò tí ì sọ nípa àwọn ènìyàn àti ìdílé e rẹ̀, nítorí Mordekai ti pàṣẹ fún un pé kí ó má ṣe sọ ọ́. Ní ojoojúmọ́ ni Mordekai máa ń rìn ní iwájú ilé àwọn obìnrin láti wo bí Esteri ṣe wà ní àlàáfíà àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i.