Est 2:1-18
Est 2:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
LẸHIN nkan wọnyi, nigbati ibinu Ahaswerusi ọba wa tuka, o ranti Faṣti, ati ohun ti o ti ṣe, ati aṣẹ ti a ti pa nitori rẹ̀. Nigbana ni awọn ọmọ-ọdọ ọba, ti nṣe iranṣẹ fun u, wi pe, jẹ ki a wá awọn wundia ti o li ẹwà fun ọba. Ki ọba ki o si yàn olori ni gbogbo ìgberiko ijọba rẹ̀, ki nwọn ki o le ṣà awọn wundia ti o li ẹwà jọ wá si Ṣuṣani ãfin, si ile awọn obinrin, si ọdọ Hegai, ìwẹfa ọba olutọju awọn obinrin; ki a si fi elo ìwẹnumọ́ wọn fun wọn: Ki wundia na ti o ba wù ọba ki o jẹ ayaba ni ipò Faṣti. Nkan na si dara loju ọba, o si ṣe bẹ̃. Ọkunrin ara Juda kan wà ni Ṣuṣani ãfin, orukọ ẹniti ijẹ Mordekai, ọmọ Jairi, ọmọ Ṣemei, ọmọ Kisi, ara Benjamini. Ẹniti a ti mu lọ lati Jerusalemu pẹlu ìgbekun ti a kó lọ pẹlu Jekoniah, ọba Juda, ti Nebukadnessari, ọba Babeli ti kó lọ. On li o si tọ́ Hadassa dagba, eyini ni Esteri, ọmọbinrin arakunrin baba rẹ̀: nitori kò ni baba, bẹ̃ni kò si ni iya, wundia na si li ẹwà, o si dara lati wò; ẹniti, nigbati baba ati iya rẹ̀ ti kú tan, Mordekai mu u ṣe ọmọbinrin ontikalarẹ̀, O si ṣe, nigbati a gbọ́ ofin ọba, ati aṣẹ rẹ̀, nigbati a si ṣà ọ̀pọlọpọ wundia jọ si Ṣuṣani ãfin, si ọwọ Hegai, a si mu Esteri wá si ile ọba pẹlu si ọwọ Hegai, olutọju awọn obinrin. Wundia na si wù u, o si ri ojurere gbà lọdọ rẹ̀; o si yara fi elo ìwẹnumọ́ rẹ̀ fun u, ati ipin onjẹ ti o jẹ tirẹ̀, ati obinrin meje ti a yàn fun u lati ile ọba wá: on si ṣi i lọ ati awọn wundia rẹ̀ si ibi ti o dara jù ni ile awọn obinrin. Esteri kò ti ifi awọn enia rẹ̀, tabi awọn ibatan rẹ̀ hàn; nitori Mordekai paṣẹ fun u ki o máṣe fi hàn. Mordekai a si ma rìn lojojumọ niwaju àgbala ile awọn obinrin, lati mọ̀ alafia Esteri, ati bi yio ti ri fun u. Njẹ nigbati o kan olukuluku wundia lati wọ̀ ile tọ̀ Ahaswerusi ọba lọ, lẹhin igbati on ba ti gbe oṣù mejila, gẹgẹ bi iṣe awọn obinrin, (nitori bayi ni ọjọ ìwẹnumọ́ wọn pari, oṣù mẹfa ni nwọn fi ikùn òroro ojiá, ati oṣù mẹfa òroro olõrùn didùn, ati pẹlu ohun elo ìwẹnumọ́ awọn obinrin): Bayi ni wundia na iwá si ọdọ ọba; ohunkohun ti o ba bère li a si ifi fun u lati ba a lọ, lati ile awọn obinrin lọ si ile ọba. Li aṣãlẹ on a lọ, ni õrọ ijọ keji on a si pada si ile keji ti awọn obinrin, si ọwọ Ṣaaṣgasi, ìwẹfa, ọba, ti nṣe olutọju awọn obinrin, on kò si gbọdọ wọle tọ̀ ọba wá mọ, bikoṣepe inu ọba ba dùn si i, ti a ba si pè e li orukọ. Njẹ nigbati o kan Esteri, ọmọ Abihaili, arakunrin Mordekai, ẹniti o mu u ṣe ọmọ ara rẹ̀, lati wọle tọ̀ ọba lọ, on kò bère ohunkohun, bikoṣe ohun ti Hegai, ìwẹfa ọba, olutọju awọn obinrin paṣẹ. Esteri si ri ojurere lọdọ gbogbo ẹniti nwò o. Bẹ̃li a mu Esteri wá si ọdọ Ahaswerusi ọba, sinu ile ọba, li oṣù kẹwa, ti iṣe oṣù Tibeti, li ọdun keje ijọba rẹ̀. Ọba si fẹràn Esteri jù gbogbo awọn obinrin lọ, on si ri ore-ọfẹ ati ojurere lọdọ rẹ̀ jù gbogbo awọn wundia na lọ; tobẹ̃ ti o fi gbe ade ọba kà a li ori, o si fi i ṣe ayaba ni ipò Faṣti. Ọba si sè àse nla kan fun gbogbo awọn olori rẹ̀, ati awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ani àse ti Esteri; o si fi isimi fun awọn ìgberiko rẹ̀, o si ṣe itọrẹ gẹgẹ bi ọwọ ọba ti to.
Est 2:1-18 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó yá, tí ibinu ọba rọlẹ̀, ó ranti ohun tí Faṣiti ṣe, ati àwọn àṣẹ tí òun pa nípa rẹ̀. Àwọn iranṣẹ ọba tí wọ́n súnmọ́ ọn tímọ́tímọ́ bá sọ fún un pé, “Jẹ́ kí á wá àwọn wundia tí wọ́n lẹ́wà fún ọba, kí á yan àwọn eniyan ní gbogbo ìgbèríko ìjọba rẹ̀ láti ṣa àwọn wundia tí wọ́n lẹ́wà wá sí ibi tí àwọn ayaba ń gbé ní ààfin, ní Susa, tíí ṣe olú ìlú, kí wọ́n wà lábẹ́ ìtọ́jú Hegai, ìwẹ̀fà ọba, tíí ṣe olùtọ́jú àwọn ayaba, kí á sì fún wọn ní àwọn ohun ìpara, kí wundia tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn jù sì jẹ́ ayaba dípò Faṣiti.” Ìmọ̀ràn yìí dùn mọ́ ọba ninu, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ọkunrin kan, ará Juda láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini wà ní ààfin Susa, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Modekai, ọmọ Jairi, ọmọ Ṣimei, ọmọ Kiṣi. Ó wà lára àwọn tí Nebukadinesari ọba Babiloni kó lẹ́rú láti Jerusalẹmu lọ sí ilẹ̀ Babiloni pẹlu Jekonaya, ọba Juda. Modekai ń tọ́ ọmọbinrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hadasa tabi Ẹsita. Ọmọ yìí jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ṣugbọn kò ní òbí mọ́. Ọmọ náà lẹ́wà gidigidi. Modekai mú un sọ́dọ̀ bí ọmọ ara rẹ̀, lẹ́yìn tí baba ati ìyá rẹ̀ ti kú. Nígbà tí ọba pàṣẹ, tí wọ́n kéde rẹ̀, tí wọ́n sì mú ọpọlọpọ wundia wá sí ààfin, ní Susa, ní abẹ́ ìtọ́jú Hegai, tí ń tọ́jú àwọn ayaba, Ẹsita wà pẹlu wọn ní ààfin ní abẹ́ ìtọ́jú rẹ̀. Ẹsita wú Hegai lórí, inú rẹ̀ dùn sí i pupọ. Ó fún un ní nǹkan ìpara ati oúnjẹ kíákíá. Ó tún fún un ní àwọn ọmọbinrin meje ninu àwọn iranṣẹbinrin tí wọ́n wà ní ààfin. Ó fún Ẹsita ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ ní ibi tí ó dára jùlọ ní ibi tí àwọn ayaba ń gbé. Ẹsita kò sọ inú ẹ̀yà tí òun ti wá, tabi ìdílé rẹ̀, fún ẹnikẹ́ni nítorí pé Modekai ti kìlọ̀ fún un pé kí ó má ṣe sọ nǹkankan nípa rẹ̀. Lojoojumọ ni Modekai máa ń rìn sókè sódò níwájú àgbàlá ibi tí àwọn ayaba ń gbé, láti bèèrè alaafia Ẹsita, ati bí ó ti ń ṣe sí. Kí wundia kankan tó lè lọ rí ọba, ó gbọdọ̀ kọ́ wà ninu ilé fún oṣù mejila, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn obinrin wọn. Oṣù mẹfa ni wọ́n fi ń kun òróró ati òjíá, wọn á sì fi oṣù mẹfa kun òróró olóòórùn dídùn ati ìpara àwọn obinrin. Nígbà tí wundia kan bá ń lọ siwaju ọba, lẹ́yìn tí ó ba ti ṣe gbogbo nǹkan tí ó yẹ, ó lè gba ohunkohun tí ó bá fẹ́ mú lọ láti ilé àwọn ayaba. Yóo lọ sibẹ ní alẹ́, ní òwúrọ̀ yóo pada wá sí ilé keji tí àwọn ayaba ń lò, tí ó wà ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣaaṣigasi, ìwẹ̀fà tí ó ń tọ́jú àwọn obinrin ọba. Kò tún ní pada lọ rí ọba mọ́, àfi bí inú ọba bá dùn sí i tí ó sì ranṣẹ pè é. Nígbà tí ó tó àkókò fún Ẹsita, ọmọ Abihaili ẹ̀gbọ́n Modekai, láti lọ rí ọba, Ẹsita kò bèèrè nǹkankan ju ohun tí Hegai, ìwẹ̀fà ọba tí ń tọ́jú àwọn ayaba, sọ fún un pé kí ó mú lọ. Ẹsita rí ojurere lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n rí i. Wọ́n mú Ẹsita lọ sọ́dọ̀ ọba Ahasu-erusi ní ààfin rẹ̀ ní oṣù Tebeti, tíí ṣe oṣù kẹwaa, ní ọdún keje ìjọba rẹ̀. Ọba fẹ́ràn rẹ̀ ju gbogbo àwọn obinrin yòókù lọ, ó sì rí ojurere ọba ju gbogbo àwọn wundia yòókù lọ. Ọba gbé adé lé e lórí, ó sì fi ṣe ayaba dípò Faṣiti. Ọba bá se àsè ńlá fún àwọn olóyè ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ nítorí Ẹsita. Ó fún gbogbo eniyan ní ìsinmi, ó sì fún wọn ní ọpọlọpọ ẹ̀bùn.
Est 2:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Ahaswerusi ọba sì dáwọ́ ìbínú un rẹ̀ dúró, ó rántí i Faṣti àti ohun tí ó ti ṣe àti àṣẹ tí ó pa nípa tirẹ̀. Nígbà naà ni ìránṣẹ́ ọba tí ó wà ní ọ̀dọ̀ ọ rẹ̀ wí pé, “Jẹ́ kí a wá ọmọbìnrin arẹwà tí kò ì ti mọ ọkùnrin rí fún ọba. Àti pé kí ọba kí ó yan àwọn aláṣẹ ní gbogbo agbègbè ilẹ̀ ọba láti kó gbogbo àwọn arẹwà ọmọbìnrin wọ̀nyí jọ sí ilé àwọn obìnrin ní ilé ìṣọ́ Susa. Kí a kó wọn fún ìtọ́jú Hegai, ìwẹ̀fà ọba, ẹni tí ó ṣe olùtọ́jú àwọn obìnrin; kí a ṣe ìtọ́jú u wọn dáradára. Nígbà naà kí ọmọbìnrin tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn kí ó jẹ́ ayaba dípò Faṣti.” Ìmọ̀ràn yìí tẹ́ ọba lọ́rùn, ó sì tẹ̀lé e. Ó sì ṣe ní ìgbà náà ará a Júù kan wà ní ilé ìṣọ́ ti Susa, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mordekai ọmọ Jairi, ọmọ Ṣimei, ọmọ Kiṣi, ẹ̀yà Benjamini, Ẹni tí Nebukadnessari ọba Babeli ti gbé lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu, lára àwọn tí wọ́n kó ní ìgbèkùn pẹ̀lú ọba Jekoniah ọba Juda. Mordekai ní arákùnrin kan ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hadassa, ẹni tí ó tọ́ dàgbà nítorí tí kò ní baba bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ìyá. Obìnrin yìí, ẹni tí a tún mọ̀ sí Esteri, ó dára ó sì lẹ́wà, Mordekai mú u gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ nígbà tí baba àti ìyá rẹ̀ ti kú. Nígbà tí a ti kéde òfin àti àṣẹ ọba, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọbìnrin ni a kó wá sí ilé ti ìṣọ́ Susa, sí abẹ́ ìtọ́jú Hegai. A sì mú Esteri náà wá sí ààfin ọba pẹ̀lú, a fà á lé Hegai lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ alábojútó ilé àwọn obìnrin. Ọmọbìnrin náà sì wù ú, ó sì rí ojúrere rẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó pèsè àwọn ohun tí ó dára àti oúnjẹ pàtàkì fún un. Ó sì yan àwọn ìránṣẹ́bìnrin wúńdíá méje láti ààfin ọba òun àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà lọ sí ibi tí ó dára jù nínú ilé àwọn obìnrin. Esteri kò tí ì sọ nípa àwọn ènìyàn àti ìdílé e rẹ̀, nítorí Mordekai ti pàṣẹ fún un pé kí ó má ṣe sọ ọ́. Ní ojoojúmọ́ ni Mordekai máa ń rìn ní iwájú ilé àwọn obìnrin láti wo bí Esteri ṣe wà ní àlàáfíà àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i. Kí àkókò tó tó fún obìnrin kọ̀ọ̀kan láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Ahaswerusi, ó ní láti lo ohun èlò tí ń mú ara lẹ́wà tí a yàn fún àwọn obìnrin fún oṣù méjìlá, yóò lo òróró òjìá fún oṣù mẹ́fà, yóò sì lo ohun èlò olóòórùn dídùn tùràrí àti ìpara fún oṣù mẹ́fà pẹ̀lú. Báyìí ni yóò ṣe lọ síwájú ọba: ohunkóhun tí ó bá béèrè ni wọ́n fi fún un láti inú ilé àwọn obìnrin lọ sí ààfin ọba. Ní alẹ́ ni yóò lọ síbẹ̀, tí ó bá sì di òwúrọ̀ yóò padà sí ilé kejì nínú ilé àwọn obìnrin ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣaaṣigasi ìwẹ̀fà ọba ẹni tí ó máa ń ṣe ìtọ́jú àwọn àlè. Òun kò ní lọ sí ọ̀dọ̀ ọba mọ́ àyàfi tí inú ọba bá dùn sí i, tí ó sì ránṣẹ́ pé ó ní orúkọ obìnrin. Nígbà tí ó kan Esteri (ọmọbìnrin tí Mordekai gbà ṣe ọmọ, ọmọbìnrin arákùnrin rẹ̀ tí ó ń jẹ́ Abihaili) láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, wọn kò béèrè fún ohunkóhun ju èyí tí Hegai, ìwẹ̀fà ọba ẹni tí ó jẹ́ olùtọ́jú ilé àwọn obìnrin sọ pé kí ó ṣe lọ. Esteri sì rí ojúrere lọ́dọ̀ gbogbo àwọn tí ó rí i. A mú Esteri lọ síwájú ọba Ahaswerusi ní ibùgbé ọba ní oṣù kẹwàá, tí ó jẹ́ oṣù Tebeti, ní ọdún keje ìjọba rẹ̀. Esteri sì wu ọba ju àwọn obìnrin tókù lọ, Ó sì rí ojúrere àti oore-ọ̀fẹ́ gbà ju ti àwọn wúńdíá tókù lọ. Nítorí náà ó fi adé ọba dé e ní orí ó sì fi ṣe ayaba dípò Faṣti. Ọba sì ṣe àsè ńlá, àsè Esteri, fún gbogbo àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè e rẹ̀. Ó sì kéde ìsinmi jákèjádò ìgbèríko ó sì pín ẹ̀bùn fún wọn pẹ̀lú bí ọba ṣe lawọ́ tó.