Est 10:1-3
Est 10:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
AHASWERUSI ọba si fi owo ọba le ilẹ fun gbogbo ilẹ, ati gbogbo erekùṣu okun. Ati gbogbo iṣe agbara rẹ̀, ati ti ipa rẹ̀, ati ìrohin titobi Mordekai, bi ọba ti sọ ọ di nla, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Media ati Persia? Nitori Mordekai ara Juda li o ṣe igbakeji Ahaswerusi ọba, o si tobi ninu awọn Ju, o si ṣe itẹwọgbà lọdọ ọ̀pọlọpọ ninu awọn arakunrin rẹ̀, o nwá ire awọn enia rẹ̀, o si nsọ̀rọ alafia fun gbogbo awọn iru-ọmọ rẹ̀.
Est 10:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Ọba Ahasu-erusi pàṣẹ pé kí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jìnnà ati àwọn tí wọn ń gbé etíkun máa san owó orí. Gbogbo iṣẹ́ agbára ati ipá rẹ̀, ati bí ó ṣe gbé Modekai ga sí ipò ọlá, ni a kọ sinu ìwé ìtàn àwọn ọba Media ati ti Pasia. Modekai tíí ṣe Juu ni igbákejì sí Ahasu-erusi ọba. Ó tóbi, ó sì níyì pupọ láàrin àwọn Juu, nítorí pé ó ń wá ire àwọn eniyan rẹ̀, ó sì ń sọ̀rọ̀ alaafia fún gbogbo wọn.
Est 10:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọba Ahaswerusi sì fi owó ọba lélẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ ọba, dé erékùṣù Òkun Àti gbogbo ìṣe agbára àti títóbi rẹ̀, papọ̀ pẹ̀lú ìròyìn títóbi Mordekai ní èyí tí ọba ti gbé e ga, kò ha wà nínú àkọsílẹ̀ ìwé ọdọọdún ọba ti Media àti ti Persia? Mordekai ará Júù ni ó jẹ́ igbákejì ọba Ahaswerusi, ó tóbi láàrín àwọn Júù, ó sì jẹ́ ẹni iyì lọ́dọ̀ àwọn Júù ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀, nítorí tí ó ń ṣiṣẹ́ fún ìre àwọn ènìyàn an rẹ̀, ó sì ń sọ̀rọ̀ fún àlàáfíà gbogbo àwọn Júù.