Efe 5:10-11 - Compare All Versions
Efe 5:10-11 YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ si mã wadi ohun ti iṣe itẹwọgbà fun Oluwa. Ẹ má si ba aileso iṣẹ òkunkun kẹgbẹ pọ̀, ṣugbọn ẹ kuku mã ba wọn wi.
Pín
Efe 5 YBCVEfe 5:10-11 YCE (Yoruba Bible)
Kí ẹ máa wádìí ohun tí yóo wu Oluwa. Ẹ má ṣe bá àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ òkùnkùn tí kò léso rere kẹ́gbẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa bá wọn wí.
Pín
Efe 5 YCEEfe 5:10-11 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ sì máa wádìí ohun tí í ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa. Ẹ má sì ṣe bá àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn kẹ́gbẹ́ pọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa bá wọn wí.
Pín
Efe 5 BMYO