Efe 4:20-32

Efe 4:20-32 Yoruba Bible (YCE)

Ṣugbọn a kò kọ́ ẹ̀yin bẹ́ẹ̀ nípa Kristi. Ẹ ti gbọ́ nípa Jesu, a sì ti fi òtítọ́ rẹ̀ kọ yín, pé kí ẹ jìnnà sí irú ìwà àtijọ́ tí ẹ ti ń hù, ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara tíí máa tan eniyan lọ sinu ìparun. Kí Ẹ̀mí Mímọ́ sọ yín di ẹni titun ninu ọkàn yín. Kí ẹ wá gbé ẹni titun nnì tí Ọlọrun dá wọ̀, kí ẹ lè máa ṣe òdodo, kí ẹ sì máa hu ìwà mímọ́ ninu òtítọ́. Nítorí náà, ẹ fi èké ṣíṣe sílẹ̀. Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín máa bá ẹnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí gbogbo wa jẹ́ ẹ̀yà ara kan náà. Bí ẹ bá bínú, ẹ má jẹ́ kí ibinu mu yín dẹ́ṣẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ ba yín ninu ibinu. Ẹ má fi ààyè gba Èṣù. Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀ kí ó kúkú gbìyànjú láti fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣe iṣẹ́ rere, kí òun náà lè ní ohun tí yóo fún àwọn aláìní. Ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ kankan kò gbọdọ̀ ti ẹnu yín jáde. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ rere, tí ó lè jẹ́ ìrànlọ́wọ́ nígbàkúùgbà ni kí ẹ máa sọ jáde lẹ́nu. Èyí yóo ṣe àwọn tí ó bá gbọ́ ní anfaani. Ẹ má kó ìbànújẹ́ bá Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọrun, tí Ọlọrun fi ṣèdìdì yín títí di ọjọ́ ìràpadà. Ẹ níláti mú gbogbo inú burúkú, ìrúnú, ibinu, ariwo ati ìsọkúsọ kúrò láàrin yín ati gbogbo nǹkan burúkú. Ẹ máa ṣoore fún ara yín, ẹ ní ojú àánú; kí ẹ sì máa dáríjì ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti dáríjì yín nípasẹ̀ Kristi.

Efe 4:20-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ṣùgbọ́n a kò fi Kristi kọ́ yín bẹ́ẹ̀. Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ ni ẹ ti gbóhùn rẹ̀ ti a sì ti kọ́ yín nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ti ń bẹ nínú Jesu. Pé, ní tì ìwà yín àtijọ́, kí ẹ̀yin bọ́ ògbólógbòó ọkùnrin nì sílẹ̀, èyí tí ó díbàjẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀tàn; Kí ẹ sì di tuntun ni ẹ̀mí inú yín; kí ẹ sì gbé ọkùnrin tuntun ni wọ̀, èyí tí a dá ni àwòrán Ọlọ́run nínú òdodo àti ìwà mímọ́ ti òtítọ́. Nítorí náà ẹ fi èké ṣíṣe sílẹ̀, ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí ẹ̀yà ara ọmọnìkejì wa ni àwa jẹ́. Nínú ìbínú yín, ẹ máa ṣe ṣẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá ìbínú yín: Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi ààyè ẹ̀gbẹ́ kan fún Èṣù. Kí ẹni tí ń jalè má ṣe jalè mọ́: ṣùgbọ́n kí ó kúkú máa ṣe làálàá, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ ohun tí ó dára, kí òun lè ní láti pín fún ẹni tí ó ṣe aláìní. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìdíbàjẹ́ kan ti ẹnu yín jáde, ṣùgbọ́n irú èyí tí ó lè ràn ìdàgbàsókè wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n nílò, kí ó lè máa fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn tí ń gbọ́. Ẹ má sì ṣe mú Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run bínú, ẹni tí a fi ṣe èdìdì yín dé ọjọ́ ìdáǹdè. Gbogbo ìwà kíkorò àti ìbínú, àti ìrunú, àti ariwo, àti ọ̀rọ̀ búburú ni kí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, pẹ̀lú gbogbo àrankàn: Ẹ máa ṣoore fún ọmọnìkejì yín, ẹ ní ìyọ́nú, ẹ máa dáríjì ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run nínú Kristi ti dáríjì yín.