Oni 9:1-6

Oni 9:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni mo wá ronú lórí gbogbo èyí, tí mo sì parí rẹ̀ pé, olóòtọ́ àti ọlọ́gbọ́n àti ohun tí wọ́n ń ṣe wà ní ọwọ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kò sí ènìyàn tí ó mọ̀ bóyá ìfẹ́ tàbí ìríra ni ó ń dúró de òun. Àyànmọ́ kan náà ni gbogbo wọn yàn—olóòtọ́ àti ènìyàn búburú, rere àti ibi, mímọ́ àti àìmọ́, àwọn tí ó ń rú ẹbọ àti àwọn tí kò rú ẹbọ. Bí ó ti rí pẹ̀lú ènìyàn rere bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ bí ó ti rí pẹ̀lú àwọn tí ó ń ṣe ìbúra bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú àwọn tí ó ń bẹ̀rù láti ṣe ìbúra. Ohun búburú ni èyí jẹ́ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn. Ìpín kan ṣoṣo ni ó ń dúró de gbogbo wọn, ọkàn ènìyàn pẹ̀lú kún fún ibi, ìsínwín sì wà ní ọkàn wọn nígbà tí wọ́n wà láààyè àti nígbà tí wọ́n bá darapọ̀ mọ́ òkú. Ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrín alààyè ní ìrètí—kódà ààyè ajá sàn dáradára ju òkú kìnnìún lọ! Nítorí pé ẹni tí ó wà láààyè mọ̀ wí pé àwọn yóò kú ṣùgbọ́n òkú kò mọ ohun kan wọn kò ní èrè kankan mọ́, àti pé kódà ìrántí wọn tí di ohun ìgbàgbé. Ìfẹ́ wọn, ìríra wọn àti ìlara wọn ti parẹ́: láéláé kọ́ ni wọn yóò tún ní ìpín nínú ohunkóhun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn.