Oni 7:13-18
Oni 7:13-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Wò iṣẹ Ọlọrun: nitoripe, tali o le mu eyini tọ́ ti on ṣe ni wiwọ? Li ọjọ alafia, mã yọ̀, ṣugbọn li ọjọ ipọnju, ronu pe, bi Ọlọrun ti da ekini bẹ̃li o da ekeji, niti idi eyi pe ki enia ki o máṣe ri nkan ti mbọ̀ lẹhin rẹ̀. Ohun gbogbo ni mo ri li ọjọ asan mi: olõtọ enia wà ti o ṣegbé ninu ododo rẹ̀, ati enia buburu wà ti ọjọ rẹ̀ pẹ ninu ìwa buburu rẹ̀. Iwọ máṣe ododo aṣeleke; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe fi ara rẹ ṣe ọlọgbọ́n aṣeleke: nitori kini iwọ o ṣe run ara rẹ? Iwọ máṣe buburu aṣeleke, bẹ̃ni ki iwọ ki o má ṣiwère; nitori kini iwọ o ṣe kú ki ọjọ rẹ ki o to pe? O dara ki iwọ ki o dì eyi mu; pẹlupẹlu iwọ máṣe yọ ọwọ rẹ kuro ninu eyi: nitori ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun ni yio yọ kuro ninu rẹ̀ gbogbo.
Oni 7:13-18 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ kíyèsí ọgbọ́n Ọlọrun, nítorí pé, ta ló lè tọ́ ohun tí ó bá dá ní wíwọ́? Máa yọ̀ nígbà tí ó bá dára fún ọ, ṣugbọn nígbà tí nǹkan kò bá dára, máa ranti pé Ọlọrun ló ṣe mejeeji. Nítorí náà, eniyan kò lè mọ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la. Ninu gbogbo ìgbé-ayé asán mi, mo ti rí àwọn nǹkan wọnyi: Mo ti rí olódodo tí ó ṣègbé ninu òdodo rẹ̀, mo sì ti rí eniyan burúkú tí ẹ̀mí rẹ̀ gùn, pẹlu bí ó ti ń ṣe ibi. Má jẹ́ kí òdodo rẹ pọ̀ jù, má sì gbọ́n ní àgbọ́njù; kí ni o fẹ́ pa ara rẹ fún? Má ṣe burúkú jù, má sì jẹ́ òmùgọ̀. Ki ni o fẹ́ pa ara rẹ lọ́jọ́ àìpé fún? Di ekinni mú ṣinṣin, má sì jẹ́ kí ekeji bọ́ lọ́wọ́ rẹ; nítorí ẹni tí ó bá bẹ̀rù Ọlọrun yóo ní ìlọsíwájú.
Oni 7:13-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe: “Ta ni ó le è to ohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́?” Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn, ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò ó Ọlọ́run tí ó dá èkínní náà ni ó dá èkejì nítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwárí ohun kankan nípa ọjọ́ iwájú rẹ̀. Nínú ayé àìní ìtumọ̀ yìí ni mo ti rí gbogbo èyí: Ènìyàn olóòtítọ́, ọkùnrin olódodo ń parun nínú òtítọ́ rẹ̀ ìkà ènìyàn sì ń gbé ìgbé ayé pípẹ́ nínú ìkà rẹ̀. Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọ tàbí ọlọ́gbọ́n jùlọ kí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run? Ìwọ ma ṣe búburú jùlọ kí ìwọ má sì ṣe aṣiwèrè Èéṣe tí ìwọ yóò fi kú kí ọjọ́ rẹ tó pé Ó dára láti mú ọ̀kan kí o má sì ṣe fi èkejì sílẹ̀ Ọkùnrin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run yóò bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àrékérekè.