Oni 7:1-6
Oni 7:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
ORUKỌ rere dara jù ororo ikunra; ati ọjọ ikú jù ọjọ ibi enia lọ. O dara lati lọ si ile ọ̀fọ jù ati lọ si ile àse: nitoripe eyi li opin gbogbo enia; alãye yio si pa a mọ́ li aiya rẹ̀. Ibinujẹ san jù ẹrín: nitoripe nipa ifaro oju a si mu aiya san. Aiya ọlọgbọ́n mbẹ ni ile ọ̀fọ; ṣugbọn aiya aṣiwère ni ile iré. O san lati gbọ́ ibawi ọlọgbọ́n jù ki enia ki o fetisi orin aṣiwère. Nitoripe bi itapàpa ẹgún labẹ ìkoko, bẹ̃li ẹrín aṣiwère: asan li eyi pẹlu.
Oni 7:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Orúkọ rere dára ju òróró olówó iyebíye lọ, ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ ìbí lọ. Ó dára láti lọ sí ilé àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ju ati lọ sí ibi àsè lọ, nítorí pé àwọn alààyè gbọdọ̀ máa rán ara wọn létí pé ikú ni òpin gbogbo eniyan. Gbogbo alààyè ni wọ́n gbọdọ̀ máa fi èyí sọ́kàn. Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ; lóòótọ́ ó lè mú kí ojú fàro, ṣugbọn a máa mú ayọ̀ bá ọkàn. Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, ṣugbọn ọkàn òmùgọ̀ wà ní ibi ìgbádùn. Ó dára kí eniyan fetí sí ìbáwí ọlọ́gbọ́n, ju láti máa gbọ́ orin ìyìn àwọn òmùgọ̀ lọ. Bí ẹ̀gún ṣe máa ń ta ninu iná, lábẹ́ ìkòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀rín òmùgọ̀ rí. Asán ni èyí pẹlu.
Oni 7:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Orúkọ rere sàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọ ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ tí a bí ènìyàn lọ Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju ibi àsè nítorí pé ikú jẹ́ àyànmọ́ gbogbo ènìyàn kí alààyè ní èyí ní ọkàn. Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ, ó le è mú kí ojú rẹ̀ dàrú, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí àyà rẹ le. Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ ní ilé àríyá. Ó dára láti gba ìbáwí ọlọ́gbọ́n, ju fífetísílẹ̀ sí orin òmùgọ̀ lọ. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gún ti ń dún lábẹ́ ìkòkò ni ẹ̀rín òmùgọ̀, Asán sì ni eléyìí pẹ̀lú.