Oni 7:1-3
Oni 7:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
ORUKỌ rere dara jù ororo ikunra; ati ọjọ ikú jù ọjọ ibi enia lọ. O dara lati lọ si ile ọ̀fọ jù ati lọ si ile àse: nitoripe eyi li opin gbogbo enia; alãye yio si pa a mọ́ li aiya rẹ̀. Ibinujẹ san jù ẹrín: nitoripe nipa ifaro oju a si mu aiya san.
Oni 7:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Orúkọ rere dára ju òróró olówó iyebíye lọ, ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ ìbí lọ. Ó dára láti lọ sí ilé àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ju ati lọ sí ibi àsè lọ, nítorí pé àwọn alààyè gbọdọ̀ máa rán ara wọn létí pé ikú ni òpin gbogbo eniyan. Gbogbo alààyè ni wọ́n gbọdọ̀ máa fi èyí sọ́kàn. Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ; lóòótọ́ ó lè mú kí ojú fàro, ṣugbọn a máa mú ayọ̀ bá ọkàn.
Oni 7:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Orúkọ rere sàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọ ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ tí a bí ènìyàn lọ Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju ibi àsè nítorí pé ikú jẹ́ àyànmọ́ gbogbo ènìyàn kí alààyè ní èyí ní ọkàn. Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ, ó le è mú kí ojú rẹ̀ dàrú, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí àyà rẹ le.