Oni 7:1-10
Oni 7:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
ORUKỌ rere dara jù ororo ikunra; ati ọjọ ikú jù ọjọ ibi enia lọ. O dara lati lọ si ile ọ̀fọ jù ati lọ si ile àse: nitoripe eyi li opin gbogbo enia; alãye yio si pa a mọ́ li aiya rẹ̀. Ibinujẹ san jù ẹrín: nitoripe nipa ifaro oju a si mu aiya san. Aiya ọlọgbọ́n mbẹ ni ile ọ̀fọ; ṣugbọn aiya aṣiwère ni ile iré. O san lati gbọ́ ibawi ọlọgbọ́n jù ki enia ki o fetisi orin aṣiwère. Nitoripe bi itapàpa ẹgún labẹ ìkoko, bẹ̃li ẹrín aṣiwère: asan li eyi pẹlu. Nitõtọ inilara mu ọlọgbọ́n enia sinwin; ọrẹ a si ba aiya jẹ. Opin nkan san jù ipilẹṣẹ rẹ̀ lọ: ati onisuru ọkàn jù ọlọkàn igberaga. Máṣe yara li ọkàn rẹ lati binu, nitoripe ibinu simi li aiya aṣiwère. Iwọ máṣe wipe, nitori kili ọjọ iṣaju ṣe san jù wọnyi lọ? nitoripe iwọ kò fi ọgbọ́n bere niti eyi.
Oni 7:1-10 Yoruba Bible (YCE)
Orúkọ rere dára ju òróró olówó iyebíye lọ, ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ ìbí lọ. Ó dára láti lọ sí ilé àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ju ati lọ sí ibi àsè lọ, nítorí pé àwọn alààyè gbọdọ̀ máa rán ara wọn létí pé ikú ni òpin gbogbo eniyan. Gbogbo alààyè ni wọ́n gbọdọ̀ máa fi èyí sọ́kàn. Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ; lóòótọ́ ó lè mú kí ojú fàro, ṣugbọn a máa mú ayọ̀ bá ọkàn. Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, ṣugbọn ọkàn òmùgọ̀ wà ní ibi ìgbádùn. Ó dára kí eniyan fetí sí ìbáwí ọlọ́gbọ́n, ju láti máa gbọ́ orin ìyìn àwọn òmùgọ̀ lọ. Bí ẹ̀gún ṣe máa ń ta ninu iná, lábẹ́ ìkòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀rín òmùgọ̀ rí. Asán ni èyí pẹlu. Dájúdájú, ìwà ìrẹ́jẹ a máa mú kí ọlọ́gbọ́n eniyan dàbí òmùgọ̀, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a sì máa ra eniyan níyè. Òpin nǹkan sàn ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ, sùúrù sì dára ju ìwà ìgbéraga lọ. Má máa yára bínú, nítorí àyà òmùgọ̀ ni ibinu dì sí. Má máa bèèrè pé, “Kí ló dé tí ìgbà àtijọ́ fi dára ju ti ìsinsìnyìí lọ?” Irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ kò mọ́gbọ́n lọ́wọ́.
Oni 7:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Orúkọ rere sàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọ ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ tí a bí ènìyàn lọ Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju ibi àsè nítorí pé ikú jẹ́ àyànmọ́ gbogbo ènìyàn kí alààyè ní èyí ní ọkàn. Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ, ó le è mú kí ojú rẹ̀ dàrú, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí àyà rẹ le. Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ ní ilé àríyá. Ó dára láti gba ìbáwí ọlọ́gbọ́n, ju fífetísílẹ̀ sí orin òmùgọ̀ lọ. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gún ti ń dún lábẹ́ ìkòkò ni ẹ̀rín òmùgọ̀, Asán sì ni eléyìí pẹ̀lú. Ìrẹ́jẹ a máa sọ ọlọ́gbọ́n di òmùgọ̀, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì máa ń ba ìwà jẹ́ ni. Òpin ọ̀rọ̀ dára ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ, sùúrù sì dára ju ìgbéraga lọ. Má ṣe yára bínú ní ọkàn rẹ nítorí pé orí ẹsẹ̀ òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé. Má ṣe sọ wí pé, “Kí ni ìdí tí àtijọ́ fi dára ju èyí?” Nítorí pé, kò mú ọgbọ́n wá láti béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀.