Oni 4:13-16
Oni 4:13-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Otoṣi ipẹ̃rẹ ti o ṣe ọlọgbọ́n, o san jù arugbo ati aṣiwère ọba lọ ti kò mọ̀ bi a ti igbà ìmọran. Nitoripe lati inu tubu li o ti jade wá ijọba; bi a tilẹ ti bi i ni talaka ni ijọba rẹ̀. Mo ri gbogbo alãye ti nrìn labẹ õrun, pẹlu ipẹ̃rẹ ekeji ti yio dide duro ni ipò rẹ̀. Kò si opin gbogbo awọn enia na, ani fun gbogbo awọn ti on wà ṣiwaju wọn: awọn pẹlu ti mbọ̀ lẹhin kì yio yọ̀ si i. Nitõtọ asan li eyi pẹlu ati imulẹmofo.
Oni 4:13-16 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọ́gbọ́n ọdọmọde tí ó jẹ́ talaka, sàn ju òmùgọ̀ àgbàlagbà ọba, tí kò jẹ́ gba ìmọ̀ràn lọ, kì báà jẹ́ pé láti ọgbà ẹ̀wọ̀n ni òmùgọ̀ ọba náà ti bọ́ sórí ìtẹ́, tabi pé láti inú ìran talaka ni a ti bí i. Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn kiri láyé ati ọdọmọde náà tí yóo gba ipò ọba. Àwọn eniyan tí ó jọba lé lórí pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní òǹkà; sibẹ, àwọn ìran tí ó bá dé lẹ́yìn kò ní máa yọ̀ nítorí rẹ̀. Dájúdájú asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí.
Oni 4:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Òtòṣì ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ tí ó ṣe ọlọ́gbọ́n, ó sàn ju arúgbó àti aṣiwèrè ọba lọ tí kò mọ bí yóò ti ṣe gba ìmọ̀ràn, Nítorí pé láti inú túbú ni ó ti jáde láti jẹ ọba, bí a tilẹ̀ bí i ní tálákà ní ìjọba rẹ̀. Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn lábẹ́ oòrùn, pẹ̀lú ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ kejì tí yóò gba ipò ọba yìí. Gbogbo àwọn tí ó wà níwájú wọn kò sì lópin, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ní ó jẹ ọba lé lórí, ẹni tí ó wà ní ipò yìí kò dùn mọ́ àwọn tí ó tẹ̀lé wọn nínú. Asán ni eléyìí pẹ̀lú jẹ́, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.