Oni 3:10-13
Oni 3:10-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mo ti ri ìṣẹ́ ti Ọlọrun fi fun awọn ọmọ enia lati ma ṣíṣẹ ninu rẹ̀. O ti ṣe ohun gbogbo daradara ni ìgba tirẹ̀; pẹlupẹlu o fi aiyeraiye si wọn li aiya, bẹ̃li ẹnikan kò le ridi iṣẹ na ti Ọlọrun nṣe lati ipilẹṣẹ titi de opin. Emi mọ̀ pe kò si rere ninu wọn, bikoṣe ki enia ki o ma yọ̀, ki o si ma ṣe rere li aiya rẹ̀. Ati pẹlu ki olukulùku enia ki o ma jẹ ki o si ma mu, ki o si ma jadùn gbogbo lãla rẹ̀, ẹ̀bun Ọlọrun ni.
Oni 3:10-13 Yoruba Bible (YCE)
Mo ti mọ ẹrù ńlá tí Ọlọrun dì ru ọmọ eniyan. Ó ṣe ohun gbogbo dáradára, ní àkókò rẹ̀. Ó fi ayérayé sí ọkàn eniyan, sibẹ, ẹnikẹ́ni kò lè rídìí ohun tí Ọlọrun ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Mo mọ̀ pé kò sí ohun tí ó yẹ wọ́n ju pé kí inú wọn máa dùn, kí wọ́n sì máa ṣe rere ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn; ati pé ẹ̀bùn Ọlọrun ni pé kí olukuluku jẹ, kí ó mu, kí ó sì gbádùn lẹ́yìn làálàá rẹ̀.
Oni 3:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo ti rí àjàgà tí Ọlọ́run gbé lé ọmọ ènìyàn. Ó ti ṣe ohun gbogbo dáradára ní àsìkò tirẹ̀, ó sì ti fi èrò nípa ayérayé sí ọkàn ọmọ ènìyàn, síbẹ̀, wọn kò le ṣe àwárí ìdí ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin. Mo mọ̀ wí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ju pé kí inú wọn dùn kí wọn sì ṣe rere níwọ̀n ìgbà tí wọ́n sì wà láààyè. Wí pé: kí olúkúlùkù le è jẹ, kí wọn sì mu, kí wọn sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú gbogbo iṣẹ́ wọn ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí jẹ́.