Oni 2:9-11
Oni 2:9-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃ni mo tobi, mo si pọ̀ si i jù gbogbo awọn ti o wà ṣaju mi ni Jerusalemu: ọgbọ́n mi si mbẹ pẹlu mi. Ohunkohun ti oju mi fẹ, emi kò pa a mọ́ fun wọn; emi kò si dù aiya mi li ohun ayò kan; nitoriti aiya mi yọ̀ ninu iṣẹ mi gbogbo; eyi si ni ipin mi lati inu gbogbo lãla mi. Nigbati mo wò gbogbo iṣẹ ti ọwọ mi ṣe, ati lãla ti mo ṣe lãla lati ṣe: si kiyesi i, asan ni gbogbo rẹ̀ ati imulẹmofo, ko si si ère kan labẹ õrùn.
Oni 2:9-11 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, mo di eniyan ńlá, mo ju ẹnikẹ́ni tí ó ti wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi lọ, ọgbọ́n sì tún wà lórí mi. Kò sí ohunkohun tí ojú mi fẹ́ rí tí n kò fún un. Kò sí ìgbádùn kan tí n kò fi tẹ́ ara mi lọ́rùn, nítorí mo jẹ ìgbádùn gbogbo ohun tí mo ṣe. Èrè gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ mi nìyí. Lẹ́yìn náà, ni mo ro gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ mi, ati gbogbo làálàá mi lórí rẹ̀; sibẹ: mo wòye pé asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo rẹ̀, kò sì sí èrè kankan láyé.
Oni 2:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo di ẹni ńlá ju ẹnikẹ́ni tí ó wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi. Nínú gbogbo èyí, ọgbọ́n mi kò fi mí sílẹ̀. Èmi kò jẹ́ kí ojú mi ṣe aláìrí ohun tí ó bá ń fẹ́. N kò sì jẹ́ kí ọkàn mi ó ṣe aláìní ìgbádùn. Ọkàn mi yọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ mi, èyí sì ni èrè fún gbogbo wàhálà mi. Síbẹ̀, nígbà tí mo wo gbogbo ohun tí ọwọ́ mi ti ṣe àti ohun tí mo ti ṣe wàhálà láti ní: gbogbo rẹ̀, asán ni. Ó dàbí ẹni gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́, kò sí èrè kan ní abẹ́ oòrùn; ọgbọ́n àti òmùgọ̀, asán ni.