Oni 2:4-11
Oni 2:4-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mo ṣe iṣẹ nla fun ara mi; mo kọ́ ile pupọ fun ara mi; mo gbin ọgbà-ajara fun ara mi. Mo ṣe ọgbà ati agbala daradara fun ara mi, mo si gbin igi oniruru eso sinu wọn. Mo ṣe adagun pupọ, lati ma bomi lati inu wọn si igbo ti o nmu igi jade wá: Mo ni iranṣẹ-kọnrin ati iranṣẹ-birin, mo si ni ibile; mo si ni ini agbo malu ati agutan nlanla jù gbogbo awọn ti o wà ni Jerusalemu ṣaju mi. Mo si kó fadaka ati wura jọ ati iṣura ti ọba ati ti igberiko, mo ni awọn olorin ọkunrin ati olorin obinrin, ati didùn inu ọmọ enia, aya ati obinrin pupọ. Bẹ̃ni mo tobi, mo si pọ̀ si i jù gbogbo awọn ti o wà ṣaju mi ni Jerusalemu: ọgbọ́n mi si mbẹ pẹlu mi. Ohunkohun ti oju mi fẹ, emi kò pa a mọ́ fun wọn; emi kò si dù aiya mi li ohun ayò kan; nitoriti aiya mi yọ̀ ninu iṣẹ mi gbogbo; eyi si ni ipin mi lati inu gbogbo lãla mi. Nigbati mo wò gbogbo iṣẹ ti ọwọ mi ṣe, ati lãla ti mo ṣe lãla lati ṣe: si kiyesi i, asan ni gbogbo rẹ̀ ati imulẹmofo, ko si si ère kan labẹ õrùn.
Oni 2:4-11 Yoruba Bible (YCE)
Mo gbé àwọn nǹkan ribiribi ṣe: mo kọ́ ilé, mo gbin ọgbà àjàrà fún ara mi. Mo ní ọpọlọpọ ọgbà ati àgbàlá, mo sì gbin oríṣìíríṣìí igi eléso sinu wọn. Mo gbẹ́ adágún omi láti máa bomirin àwọn igi tí mo gbìn. Mo ra ọpọlọpọ ẹrukunrin ati ẹrubinrin, mo sì ní àwọn ọmọ ẹrú tí wọn bí ninu ilé mi, mo ní ọpọlọpọ agbo mààlúù ati agbo ẹran, ju àwọn tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi lọ. Mo kó fadaka ati wúrà jọ fún ara mi; mo gba ìṣúra àwọn ọba ati ti àwọn agbègbè ìjọba mi. Mo ní àwọn akọrin lọkunrin ati lobinrin, mo sì ní ọpọlọpọ obinrin tíí mú inú ọkunrin dùn. Nítorí náà, mo di eniyan ńlá, mo ju ẹnikẹ́ni tí ó ti wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi lọ, ọgbọ́n sì tún wà lórí mi. Kò sí ohunkohun tí ojú mi fẹ́ rí tí n kò fún un. Kò sí ìgbádùn kan tí n kò fi tẹ́ ara mi lọ́rùn, nítorí mo jẹ ìgbádùn gbogbo ohun tí mo ṣe. Èrè gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ mi nìyí. Lẹ́yìn náà, ni mo ro gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ mi, ati gbogbo làálàá mi lórí rẹ̀; sibẹ: mo wòye pé asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo rẹ̀, kò sì sí èrè kankan láyé.
Oni 2:4-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńláńlá: Mo kọ́ ilé púpọ̀ fún ara mi, mo sì gbin ọgbà àjàrà púpọ̀. Mo ṣe ọgbà àti àgbàlá, mo sì gbin onírúurú igi eléso sí inú wọn. Mo gbẹ́ adágún láti máa bu omi rin àwọn igi tí ó ń hù jáde nínú ọgbà. Mo ra àwọn ẹrú ọkùnrin àti àwọn ẹrú obìnrin, mo sì tún ní àwọn ẹrú mìíràn tí a bí sí ilé mi. Mo sì tún ní ẹran ọ̀sìn ju ẹnikẹ́ni ní Jerusalẹmu lọ. Mo kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara mi àti àwọn ohun ìṣúra ti ọba àti ìgbèríko. Mo ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin, àti dídùn inú ọmọ ènìyàn, aya àti obìnrin púpọ̀. Mo di ẹni ńlá ju ẹnikẹ́ni tí ó wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi. Nínú gbogbo èyí, ọgbọ́n mi kò fi mí sílẹ̀. Èmi kò jẹ́ kí ojú mi ṣe aláìrí ohun tí ó bá ń fẹ́. N kò sì jẹ́ kí ọkàn mi ó ṣe aláìní ìgbádùn. Ọkàn mi yọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ mi, èyí sì ni èrè fún gbogbo wàhálà mi. Síbẹ̀, nígbà tí mo wo gbogbo ohun tí ọwọ́ mi ti ṣe àti ohun tí mo ti ṣe wàhálà láti ní: gbogbo rẹ̀, asán ni. Ó dàbí ẹni gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́, kò sí èrè kan ní abẹ́ oòrùn; ọgbọ́n àti òmùgọ̀, asán ni.