Àmì-ìdánimọ̀ YouVersion
BíbélìÀwon ètòÀwon Fídíò
Gba ohun èlò náà
Àṣàyàn Èdè
Ṣe Àwárí

Oni 2:14-15

Oni 2:14-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

Oju ọlọgbọ́n mbẹ li ori rẹ̀; ṣugbọn aṣiwère nrìn li òkunkun: emitikalami si mọ̀ pẹlu pe, iṣe kanna li o nṣe gbogbo wọn. Nigbana ni mo wi li aiya mi pe, Bi o ti nṣe si aṣiwère, bẹ̃li o si nṣe si emitikalami; nitori kili emi si ṣe gbọ́n jù? Nigbana ni mo wi li ọkàn mi pe, asan li eyi pẹlu.

Pín
Kà Oni 2

Oni 2:14-15 Yoruba Bible (YCE)

Ọlọ́gbọ́n ní ojú lágbárí, ṣugbọn ninu òkùnkùn ni òmùgọ̀ ń rìn. Sibẹ mo rí i pé, nǹkankan náà ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn. Nígbà náà ni mo sọ lọ́kàn ara mi pé, “Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí òmùgọ̀ ni yóo ṣẹlẹ̀ sí èmi náà. Kí wá ni ìwúlò ọgbọ́n mi?” Mo sọ fún ara mi pé, asán ni eléyìí pẹlu.

Pín
Kà Oni 2

Oni 2:14-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ojú ọlọ́gbọ́n ń bẹ lágbárí rẹ̀, nígbà tí aṣiwèrè ń rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n mo wá padà mọ̀ wí pé ìpín kan náà ni ó ń dúró de ìsọ̀rí àwọn ènìyàn méjèèjì. Nígbà náà ni mo rò nínú ọkàn wí pé, “Irú ìpín tí òmùgọ̀ ní yóò bá èmi náà pẹ̀lú kí wá ni ohun tí mo jẹ ní èrè nípa ọgbọ́n?” Mo sọ nínú ọkàn mi wí pé, “Asán ni eléyìí pẹ̀lú.”

Pín
Kà Oni 2
YouVersion

Ńgbà ọ́ níyànjú ó ṣì ń pè ọ́ níjà láti súnmọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́.

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Nípaa

Àwọn iṣẹ́

Oluyọọda

Blọ́ọ̀gì

Tè

Àwọn ojú-ìwé tí ó wúlò

Ìrànlọ́wọ́

Fifún ni

Àwon Èyà Bíbélì

Àwọn Bíbélì àfetígbọ́

Àwọn Èdè Bíbélì

Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní


Isẹ́ Ìránṣẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé

Life.Church
English (US)

©2025 Life.Church / YouVersion

Ìṣe ìdá kọ́ńkó̩Àwon àdéhùn
Ètò Ìpolongo Àwọn Àìléwu
FacebookTwitterInstagramYouTubePinterest

Ilé

Bíbélì

Àwon ètò

Àwon Fídíò