Oni 2:1-8
Oni 2:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI wi ninu mi pe, wá na! emi o fi iré-ayọ̀ dan ọ wò, nitorina mã jẹ afẹ! si kiyesi i, asan li eyi pẹlu! Emi wi fun ẹrin pe, Iwère ni ọ: ati fun iré-ayọ̀ pe kili o nṣe? Mo rò ninu aiya mi lati fi ọti-waini mu ara mi le, ṣugbọn emi nfi ọgbọ́n tọ́ aiya mi: on ati fi ọwọ le iwère, titi emi o fi ri ohun ti o dara fun ọmọ enia, ti nwọn iba mã ṣe labẹ ọrun ni iye ọjọ aiye wọn gbogbo. Mo ṣe iṣẹ nla fun ara mi; mo kọ́ ile pupọ fun ara mi; mo gbin ọgbà-ajara fun ara mi. Mo ṣe ọgbà ati agbala daradara fun ara mi, mo si gbin igi oniruru eso sinu wọn. Mo ṣe adagun pupọ, lati ma bomi lati inu wọn si igbo ti o nmu igi jade wá: Mo ni iranṣẹ-kọnrin ati iranṣẹ-birin, mo si ni ibile; mo si ni ini agbo malu ati agutan nlanla jù gbogbo awọn ti o wà ni Jerusalemu ṣaju mi. Mo si kó fadaka ati wura jọ ati iṣura ti ọba ati ti igberiko, mo ni awọn olorin ọkunrin ati olorin obinrin, ati didùn inu ọmọ enia, aya ati obinrin pupọ.
Oni 2:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Mo wí ninu ọkàn mi pé, n óo dán ìgbádùn wò; n óo gbádùn ara mi, ṣugbọn, èyí pàápàá, asán ni. Mo ní, “Ẹ̀rín rínrín dàbí ìwà wèrè, ìgbádùn kò sì jámọ́ nǹkankan fún eniyan.” Mo ronú bí mo ti ṣe lè fi waini mú inú ara mi dùn, ṣugbọn tí kò ní pa ọgbọ́n mọ́ mi ninu; mo tún ronú ohun tí mo lè ṣe pẹlu ìwà òmùgọ̀ títí tí n óo fi lè rí ohun tí ó dára fún ọmọ eniyan láti máa ṣe láyé níwọ̀n àkókò díẹ̀ tí Ọlọrun fún wọn láti gbé lórí ilẹ̀ ayé. Mo gbé àwọn nǹkan ribiribi ṣe: mo kọ́ ilé, mo gbin ọgbà àjàrà fún ara mi. Mo ní ọpọlọpọ ọgbà ati àgbàlá, mo sì gbin oríṣìíríṣìí igi eléso sinu wọn. Mo gbẹ́ adágún omi láti máa bomirin àwọn igi tí mo gbìn. Mo ra ọpọlọpọ ẹrukunrin ati ẹrubinrin, mo sì ní àwọn ọmọ ẹrú tí wọn bí ninu ilé mi, mo ní ọpọlọpọ agbo mààlúù ati agbo ẹran, ju àwọn tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi lọ. Mo kó fadaka ati wúrà jọ fún ara mi; mo gba ìṣúra àwọn ọba ati ti àwọn agbègbè ìjọba mi. Mo ní àwọn akọrin lọkunrin ati lobinrin, mo sì ní ọpọlọpọ obinrin tíí mú inú ọkunrin dùn.
Oni 2:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo rò nínú ọkàn mi, “Wá nísinsin yìí, èmi yóò sì dán ọ wò pẹ̀lú ìgbádùn láti ṣe àwárí ohun tí ó dára.” Ṣùgbọ́n eléyìí náà jásí asán. “Mo wí fún ẹ̀rín pé òmùgọ̀ ni. Àti fún ìre-ayọ̀ pé kí ni ó ń ṣe?” Mo tiraka láti dun ara mi nínú pẹ̀lú ọtí wáìnì, àti láti fi ọwọ́ lé òmùgọ̀—ọkàn mi sì ń tọ́ mi pẹ̀lú ọgbọ́n. Mo fẹ́ wo ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe fún ènìyàn ní abẹ́ ọ̀run ní ìwọ̀nba ọjọ́ ayé rẹ̀. Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńláńlá: Mo kọ́ ilé púpọ̀ fún ara mi, mo sì gbin ọgbà àjàrà púpọ̀. Mo ṣe ọgbà àti àgbàlá, mo sì gbin onírúurú igi eléso sí inú wọn. Mo gbẹ́ adágún láti máa bu omi rin àwọn igi tí ó ń hù jáde nínú ọgbà. Mo ra àwọn ẹrú ọkùnrin àti àwọn ẹrú obìnrin, mo sì tún ní àwọn ẹrú mìíràn tí a bí sí ilé mi. Mo sì tún ní ẹran ọ̀sìn ju ẹnikẹ́ni ní Jerusalẹmu lọ. Mo kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara mi àti àwọn ohun ìṣúra ti ọba àti ìgbèríko. Mo ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin, àti dídùn inú ọmọ ènìyàn, aya àti obìnrin púpọ̀.