Oni 2:1-17

Oni 2:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

EMI wi ninu mi pe, wá na! emi o fi iré-ayọ̀ dan ọ wò, nitorina mã jẹ afẹ! si kiyesi i, asan li eyi pẹlu! Emi wi fun ẹrin pe, Iwère ni ọ: ati fun iré-ayọ̀ pe kili o nṣe? Mo rò ninu aiya mi lati fi ọti-waini mu ara mi le, ṣugbọn emi nfi ọgbọ́n tọ́ aiya mi: on ati fi ọwọ le iwère, titi emi o fi ri ohun ti o dara fun ọmọ enia, ti nwọn iba mã ṣe labẹ ọrun ni iye ọjọ aiye wọn gbogbo. Mo ṣe iṣẹ nla fun ara mi; mo kọ́ ile pupọ fun ara mi; mo gbin ọgbà-ajara fun ara mi. Mo ṣe ọgbà ati agbala daradara fun ara mi, mo si gbin igi oniruru eso sinu wọn. Mo ṣe adagun pupọ, lati ma bomi lati inu wọn si igbo ti o nmu igi jade wá: Mo ni iranṣẹ-kọnrin ati iranṣẹ-birin, mo si ni ibile; mo si ni ini agbo malu ati agutan nlanla jù gbogbo awọn ti o wà ni Jerusalemu ṣaju mi. Mo si kó fadaka ati wura jọ ati iṣura ti ọba ati ti igberiko, mo ni awọn olorin ọkunrin ati olorin obinrin, ati didùn inu ọmọ enia, aya ati obinrin pupọ. Bẹ̃ni mo tobi, mo si pọ̀ si i jù gbogbo awọn ti o wà ṣaju mi ni Jerusalemu: ọgbọ́n mi si mbẹ pẹlu mi. Ohunkohun ti oju mi fẹ, emi kò pa a mọ́ fun wọn; emi kò si dù aiya mi li ohun ayò kan; nitoriti aiya mi yọ̀ ninu iṣẹ mi gbogbo; eyi si ni ipin mi lati inu gbogbo lãla mi. Nigbati mo wò gbogbo iṣẹ ti ọwọ mi ṣe, ati lãla ti mo ṣe lãla lati ṣe: si kiyesi i, asan ni gbogbo rẹ̀ ati imulẹmofo, ko si si ère kan labẹ õrùn. Mo si yi ara mi pada lati wò ọgbọ́n, ati isinwin ati iwère: nitoripe kili ọkunrin na ti mbọ lẹhin ọba yio le ṣe? eyi ti a ti ṣe tan nigbani ni yio ṣe. Nigbana ni mo ri pe ọgbọ́n ta wère yọ, to iwọn bi imọlẹ ti ta òkunkun yọ. Oju ọlọgbọ́n mbẹ li ori rẹ̀; ṣugbọn aṣiwère nrìn li òkunkun: emitikalami si mọ̀ pẹlu pe, iṣe kanna li o nṣe gbogbo wọn. Nigbana ni mo wi li aiya mi pe, Bi o ti nṣe si aṣiwère, bẹ̃li o si nṣe si emitikalami; nitori kili emi si ṣe gbọ́n jù? Nigbana ni mo wi li ọkàn mi pe, asan li eyi pẹlu. Nitoripe iranti kò si fun ọlọgbọ́n pẹlu aṣiwère lailai; ki a wò o pe, bi akoko ti o kọja, bẹ̃li ọjọ ti mbọ, a o gbagbe gbogbo rẹ̀. Ọlọgbọ́n ha ṣe nkú bi aṣiwère? Nitorina mo korira ìwa-laiye: nitoripe iṣẹ ti a ṣe labẹ õrun: ibi ni fun mi: nitoripe asan ni gbogbo rẹ̀ ati imulẹmofo.

Oni 2:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Mo wí ninu ọkàn mi pé, n óo dán ìgbádùn wò; n óo gbádùn ara mi, ṣugbọn, èyí pàápàá, asán ni. Mo ní, “Ẹ̀rín rínrín dàbí ìwà wèrè, ìgbádùn kò sì jámọ́ nǹkankan fún eniyan.” Mo ronú bí mo ti ṣe lè fi waini mú inú ara mi dùn, ṣugbọn tí kò ní pa ọgbọ́n mọ́ mi ninu; mo tún ronú ohun tí mo lè ṣe pẹlu ìwà òmùgọ̀ títí tí n óo fi lè rí ohun tí ó dára fún ọmọ eniyan láti máa ṣe láyé níwọ̀n àkókò díẹ̀ tí Ọlọrun fún wọn láti gbé lórí ilẹ̀ ayé. Mo gbé àwọn nǹkan ribiribi ṣe: mo kọ́ ilé, mo gbin ọgbà àjàrà fún ara mi. Mo ní ọpọlọpọ ọgbà ati àgbàlá, mo sì gbin oríṣìíríṣìí igi eléso sinu wọn. Mo gbẹ́ adágún omi láti máa bomirin àwọn igi tí mo gbìn. Mo ra ọpọlọpọ ẹrukunrin ati ẹrubinrin, mo sì ní àwọn ọmọ ẹrú tí wọn bí ninu ilé mi, mo ní ọpọlọpọ agbo mààlúù ati agbo ẹran, ju àwọn tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi lọ. Mo kó fadaka ati wúrà jọ fún ara mi; mo gba ìṣúra àwọn ọba ati ti àwọn agbègbè ìjọba mi. Mo ní àwọn akọrin lọkunrin ati lobinrin, mo sì ní ọpọlọpọ obinrin tíí mú inú ọkunrin dùn. Nítorí náà, mo di eniyan ńlá, mo ju ẹnikẹ́ni tí ó ti wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi lọ, ọgbọ́n sì tún wà lórí mi. Kò sí ohunkohun tí ojú mi fẹ́ rí tí n kò fún un. Kò sí ìgbádùn kan tí n kò fi tẹ́ ara mi lọ́rùn, nítorí mo jẹ ìgbádùn gbogbo ohun tí mo ṣe. Èrè gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ mi nìyí. Lẹ́yìn náà, ni mo ro gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ mi, ati gbogbo làálàá mi lórí rẹ̀; sibẹ: mo wòye pé asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo rẹ̀, kò sì sí èrè kankan láyé. Nítorí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa ìwà ọlọ́gbọ́n, ìwà wèrè ati ìwà òmùgọ̀. Mo rò ó pé kí ni ẹnìkan lè ṣe lẹ́yìn èyí tí ọba ti ṣe ṣáájú rẹ̀? Mo wá rí i pé bí ìmọ́lẹ̀ ti dára ju òkùnkùn lọ ni ọgbọ́n dára ju ìwà wèrè lọ. Ọlọ́gbọ́n ní ojú lágbárí, ṣugbọn ninu òkùnkùn ni òmùgọ̀ ń rìn. Sibẹ mo rí i pé, nǹkankan náà ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn. Nígbà náà ni mo sọ lọ́kàn ara mi pé, “Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí òmùgọ̀ ni yóo ṣẹlẹ̀ sí èmi náà. Kí wá ni ìwúlò ọgbọ́n mi?” Mo sọ fún ara mi pé, asán ni eléyìí pẹlu. Nítorí pé àtọlọ́gbọ́n, àtòmùgọ̀, kò sẹ́ni tíí ranti wọn pẹ́ lọ títí. Nítorí pé ní ọjọ́ iwájú, gbogbo wọn yóo di ẹni ìgbàgbé patapata. Ẹ wo bí ọlọ́gbọ́n ti í kú bí òmùgọ̀. Nítorí náà mo kórìíra ayé, nítorí gbogbo nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀ láyé ń bà mí ninu jẹ́, nítorí pé asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo wọn.

Oni 2:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Mo rò nínú ọkàn mi, “Wá nísinsin yìí, èmi yóò sì dán ọ wò pẹ̀lú ìgbádùn láti ṣe àwárí ohun tí ó dára.” Ṣùgbọ́n eléyìí náà jásí asán. “Mo wí fún ẹ̀rín pé òmùgọ̀ ni. Àti fún ìre-ayọ̀ pé kí ni ó ń ṣe?” Mo tiraka láti dun ara mi nínú pẹ̀lú ọtí wáìnì, àti láti fi ọwọ́ lé òmùgọ̀—ọkàn mi sì ń tọ́ mi pẹ̀lú ọgbọ́n. Mo fẹ́ wo ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe fún ènìyàn ní abẹ́ ọ̀run ní ìwọ̀nba ọjọ́ ayé rẹ̀. Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńláńlá: Mo kọ́ ilé púpọ̀ fún ara mi, mo sì gbin ọgbà àjàrà púpọ̀. Mo ṣe ọgbà àti àgbàlá, mo sì gbin onírúurú igi eléso sí inú wọn. Mo gbẹ́ adágún láti máa bu omi rin àwọn igi tí ó ń hù jáde nínú ọgbà. Mo ra àwọn ẹrú ọkùnrin àti àwọn ẹrú obìnrin, mo sì tún ní àwọn ẹrú mìíràn tí a bí sí ilé mi. Mo sì tún ní ẹran ọ̀sìn ju ẹnikẹ́ni ní Jerusalẹmu lọ. Mo kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara mi àti àwọn ohun ìṣúra ti ọba àti ìgbèríko. Mo ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin, àti dídùn inú ọmọ ènìyàn, aya àti obìnrin púpọ̀. Mo di ẹni ńlá ju ẹnikẹ́ni tí ó wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi. Nínú gbogbo èyí, ọgbọ́n mi kò fi mí sílẹ̀. Èmi kò jẹ́ kí ojú mi ṣe aláìrí ohun tí ó bá ń fẹ́. N kò sì jẹ́ kí ọkàn mi ó ṣe aláìní ìgbádùn. Ọkàn mi yọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ mi, èyí sì ni èrè fún gbogbo wàhálà mi. Síbẹ̀, nígbà tí mo wo gbogbo ohun tí ọwọ́ mi ti ṣe àti ohun tí mo ti ṣe wàhálà láti ní: gbogbo rẹ̀, asán ni. Ó dàbí ẹni gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́, kò sí èrè kan ní abẹ́ oòrùn; ọgbọ́n àti òmùgọ̀, asán ni. Nígbà náà ni mo tún bẹ̀rẹ̀ sí ọgbọ́n, àti ìsínwín àti àìgbọ́n kí ni ọba tí ó jẹ lẹ́yìn tí ọba kan kú le è ṣe ju èyí tí ọba ìṣáájú ti ṣe lọ. Mo sì ri wí pé ọgbọ́n dára ju òmùgọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ ti dára ju òkùnkùn lọ. Ojú ọlọ́gbọ́n ń bẹ lágbárí rẹ̀, nígbà tí aṣiwèrè ń rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n mo wá padà mọ̀ wí pé ìpín kan náà ni ó ń dúró de ìsọ̀rí àwọn ènìyàn méjèèjì. Nígbà náà ni mo rò nínú ọkàn wí pé, “Irú ìpín tí òmùgọ̀ ní yóò bá èmi náà pẹ̀lú kí wá ni ohun tí mo jẹ ní èrè nípa ọgbọ́n?” Mo sọ nínú ọkàn mi wí pé, “Asán ni eléyìí pẹ̀lú.” Nítorí pé ọlọ́gbọ́n ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí i òmùgọ̀, a kì yóò rántí rẹ̀ fún ìgbà pípẹ́; gbogbo wọn ni yóò di ohun ìgbàgbé ní ọjọ́ tó ń bọ̀. Ikú tí ó pa aṣiwèrè náà ni yóò pa ọlọ́gbọ́n ènìyàn. Nítorí náà, mo kórìíra ìwàláàyè, nítorí pé iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ní abẹ́ oòrùn ti mú ìdààmú bá mi. Gbogbo rẹ̀ asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.