Oni 12:1-3
Oni 12:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
RANTI ẹlẹda rẹ nisisiyi li ọjọ ewe rẹ, nigbati ọjọ ibi kò ti ide, ati ti ọdun kò ti isunmọ etile, nigbati iwọ o wipe, emi kò ni inudidùn ninu wọn; Nigbati õrùn, tabi imọlẹ, tabi oṣupa tabi awọn irawọ kò ti iṣu òkunkun, ati ti awọsanma kò ti itun pada lẹhin òjo: Li ọjọ ti awọn oluṣọ ile yio warìri, ati ti awọn ọkunrin alagbara yio tẹri wọn ba, awọn õlọ̀ yio si dakẹ nitoriti nwọn kò to nkan, ati awọn ti nwode loju ferese yio ṣu òkunkun
Oni 12:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Ranti ẹlẹ́dàá rẹ ní ìgbà èwe rẹ, kí ọjọ́ ibi tó dé, kí ọjọ́ ogbó rẹ tó súnmọ́ etílé, nígbà tí o óo wí pé, “N kò ní inú dídùn ninu wọn.” Kí oòrùn ati ìmọ́lẹ̀ ati òṣùpá ati ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn, kí ìkùukùu tó pada lẹ́yìn òjò; nígbà tí àwọn tí ń ṣọ́ ilé yóo máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, tí ẹ̀yìn àwọn alágbára yóo tẹ̀, tí àwọn òòlọ̀ yóo dákẹ́ jẹ́ẹ́, nítorí pé wọn kò pọ̀ mọ́, tí àwọn tí ń wo ìta láti ojú fèrèsé yóo máa ríran bàìbàì
Oni 12:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ ní ọjọ́ èwe rẹ, nígbà tí ọjọ́ ibi kò tí ì dé àti tí ọdún kò tí ì ní súnmọ́ etílé, nígbà tí ìwọ yóò wí pé, “Èmi kò ní ìdùnnú nínú wọn” Kí oòrùn àti ìmọ́lẹ̀ àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn, àti kí àwọsánmọ̀ tó padà lẹ́yìn òjò; Nígbà tí olùṣọ́ ilé yóò wárìrì tí àwọn ọkùnrin alágbára yóò tẹríba, nígbà tí àwọn tí ó ń lọ dákẹ́ nítorí pé wọn kò pọ̀, tí àwọn tí ń wo òde láti ojú fèrèsé yóò ṣókùnkùn