Oni 1:13-15
Oni 1:13-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mo si fi aiya mi si ati ṣe afẹri on ati wadi ọgbọ́n niti ohun gbogbo ti a nṣe labẹ ọrun, lãla kikan yi li Ọlorun fi fun awọn ọmọ enia lati ṣe lãla ninu rẹ̀. Mo ti ri iṣẹ gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn; si kiyesi i, asan ni gbogbo rẹ̀ ati imulẹmofo. Eyi ti o wọ́, a kò le mu u tọ́: ati iye àbuku, a kò le kà a.
Oni 1:13-15 Yoruba Bible (YCE)
Mo fi tọkàntọkàn pinnu láti fi ọgbọ́n wádìí gbogbo ohun tí eniyan ń ṣe láyé. Làálàá lásán ni iṣẹ́ tí Ọlọrun fún ọmọ eniyan ṣe lórí ilẹ̀ ayé. Mo ti wo gbogbo nǹkan tí eniyan ń ṣe láyé, wò ó, asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo rẹ̀. Ohun tí ó bá ti wọ́, ẹnìkan kò lè tọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò lè ka ohun tí kò bá sí.
Oni 1:13-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo fi àsìkò mi sílẹ̀ láti kọ́ àti láti ṣe àwárí pẹ̀lú ọgbọ́n, gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀run. Háà! Ẹrù wúwo tí Ọlọ́run ti gbé lé àwọn ènìyàn: Èmi ti rí ohun gbogbo tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn, gbogbo rẹ̀ kò ní ìtumọ̀ bí ẹní gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni. Ohun tí ó ti wọ́ kò le è ṣe é tọ́ mọ́, ohun tí kò sí kò le è ṣe é kà.