Deu 6:20-23
Deu 6:20-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati ọmọ rẹ ba bi ọ lère lẹhin-ọla, wipe, Kini èredi ẹrí, ati ìlana, ati idajọ wọnyi, ti OLUWA Ọlọrun filelẹ li aṣẹ fun nyin? Nigbana ni ki iwọ ki o wi fun ọmọ rẹ pe, Ẹrú Farao li awa ti ṣe ni Egipti; OLUWA si fi ọwọ́ agbara mú wa jade lati Egipti wá. OLUWA si fi àmi ati iṣẹ-iyanu, ti o tobi ti o si buru hàn lara Egipti, lara Farao, ati lara gbogbo ara ile rẹ̀ li oju wa: O si mú wa jade lati ibẹ̀ wá, ki o le mú wa wọ̀ inu rẹ̀, lati fun wa ni ilẹ na ti o bura fun awọn baba wa.
Deu 6:20-23 Yoruba Bible (YCE)
“Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá bèèrè lọ́jọ́ iwájú pé, kí ni ìtumọ̀ àwọn ẹ̀rí ati ìlànà ati òfin tí OLUWA pa láṣẹ fun yín. Ẹ óo dá wọn lóhùn pé, ‘A ti jẹ́ ẹrú Farao ní ilẹ̀ Ijipti rí, ṣugbọn agbára ni OLUWA fi kó wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Àwa pàápàá fi ojú wa rí i bí OLUWA ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá tí wọ́n bani lẹ́rù sí àwọn ará Ijipti ati sí Farao ọba wọn, ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀. OLUWA sì kó wa jáde, kí ó lè kó wa wá sí orí ilẹ̀ tí ó ti búra láti fi fún àwọn baba wa.
Deu 6:20-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Ní ọjọ́ iwájú, bí ọmọ rẹ bá béèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin wọ̀nyí tí OLúWA Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún ọ?” Sọ fún un pé: “Ẹrú Farao ní ilẹ̀ Ejibiti ni wá tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n OLúWA fi ọwọ́ agbára ńlá yọ wá jáde lóko ẹrú Ejibiti. Lójú wa ni OLúWA tí ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu: tí ó lágbára tí ó sì ba ni lẹ́rù: lórí Ejibiti àti Farao, àti gbogbo ènìyàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó mú wa jáde láti ibẹ̀ wá láti mú wa wọ inú àti láti fún wa ní ilẹ̀ tí ó ti fì búra fún àwọn baba ńlá wa.