Deu 5:8-10
Deu 5:8-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ kò gbọdọ yá ere fun ara rẹ, tabi aworán apẹrẹ kan ti mbẹ loke ọrun, tabi ti mbẹ ni ilẹ nisalẹ, tabi ti mbẹ ninu omi ni isalẹ ilẹ: Iwọ kò gbọdọ tẹ̀ ori rẹ ba fun wọn, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn: nitoripe emi OLUWA Ọlọrun rẹ Ọlọrun owú ni mi, ti mbẹ̀ ẹ̀ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, ati lara iran kẹta ati ẹkẹrin ninu awọn ti o korira mi. Emi a si ma ṣe ãnu fun ẹgbẹgbẹrun awọn ti o fẹ́ mi, ti nwọn si pa ofin mi mọ́.
Deu 5:8-10 Yoruba Bible (YCE)
“ ‘O kò gbọdọ̀ yá èrekére kankan fún ara rẹ, kì báà jẹ́ ní àwòrán ohunkohun tí ó wà ní ojú ọ̀run tabi ti ohun tí ó wà lórí ilẹ̀, tabi èyí tí ó wà ninu omi ní abẹ́ ilẹ̀. O kò gbọdọ̀ tẹríba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ sìn wọ́n, nítorí pé Ọlọrun tíí máa ń jowú ni èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. Èmi a máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ ati ọmọ ọmọ, títí dé ìran kẹta ati ìran kẹrin ninu àwọn tí wọ́n kórìíra mi. Ṣugbọn èmi a máa fi ìfẹ́ mi, tí kì í yẹ̀, hàn sí ẹgbẹẹgbẹrun àwọn tí wọ́n fẹ́ràn mi, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé òfin mi.
Deu 5:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ ní òkè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀. Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n; nítorí Èmi OLúWA Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí, tí ń bẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wò lára àwọn ọmọ, láti ìran kẹta títí dé ẹ̀kẹrin nínú àwọn tí ó kórìíra mi. Èmi a sì máa fi àánú hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́.