Deu 32:1-20
Deu 32:1-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
FETISILẸ, ẹnyin ọrun, emi o si sọ̀rọ; si gbọ́ ọ̀rọ ẹnu mi, iwọ aiye: Ẹkọ́ mi yio ma kán bi ojò ohùn mi yio ma sẹ̀ bi ìri; bi òjo winiwini sara eweko titun, ati bi ọ̀wara òjo sara ewebẹ̀: Nitoriti emi o kokikí orukọ OLUWA kiri: ẹ fi ọlá fun Ọlọrun wa. Apata na, pipé ni iṣẹ rẹ̀; nitoripe idajọ ni gbogbo ọ̀na rẹ̀: Ọlọrun otitọ ati alàiṣegbe, ododo ati otitọ li on. Nwọn ti bà ara wọn jẹ́ lọdọ rẹ̀, nwọn ki iṣe ọmọ rẹ̀, àbuku wọn ni; iran arekereke ati wiwọ́ ni nwọn. Bayi li ẹnyin o ha san ẹsan fun OLUWA, ẹnyin aṣiwere enia ati alaigbọn? On ha kọ́ ni baba rẹ ti o rà ọ? on li o dá ọ, on li o si fi ẹsẹ̀ rẹ mulẹ? Ranti ọjọ́ igbãni, ronu ọdún iraniran: bi baba rẹ lere yio si fihàn ọ; bi awọn àgba rẹ, nwọn o si sọ fun ọ. Nigbati Ọga-ogo pín iní fun awọn orilẹ-ède, nigbati o tu awọn ọmọ enia ká, o pàla awọn enia na gẹgẹ bi iye awọn ọmọ Israeli. Nitoripe ipín ti OLUWA li awọn enia rẹ̀; Jakobu ni ipín iní rẹ̀. O ri i ni ilẹ aṣalẹ̀, ati ni aginjù nibiti ẹranko nke; o yi i ká, o tọju rẹ̀, o pa a mọ́ bi ẹyin oju rẹ̀: Bi idì ti irú itẹ́ rẹ̀, ti iràbaba sori ọmọ rẹ̀, ti inà iyẹ́-apa rẹ̀, ti igbé wọn, ti ima gbé wọn lọ lori iyẹ́-apa rẹ̀: Bẹ̃ni OLUWA nikan ṣamọ̀na rẹ̀, kò si sí oriṣa pẹlu rẹ̀. O mu u gùn ibi giga aiye, ki o le ma jẹ eso oko; o si jẹ ki o mu oyin lati inu apata wá, ati oróro lati inu okuta akọ wá; Ori-amọ́ malu, ati warà agutan, pẹlu ọrá ọdọ-agutan, ati àgbo irú ti Baṣani, ati ewurẹ, ti on ti ọrá iwe alikama; iwọ si mu ẹ̀jẹ eso-àjara, ani ọti-waini. Ṣugbọn Jeṣuruni sanra tán, o si tapa: iwọ sanra tán, iwọ kì tan, ọrá bò ọ tán: nigbana li o kọ̀ Ọlọrun ti o dá a, o si gàn Apata ìgbala rẹ̀. Nwọn fi oriṣa mu u jowú, ohun irira ni nwọn fi mu u binu. Nwọn rubọ si iwin-buburu ti ki iṣe Ọlọrun, si oriṣa ti nwọn kò mọ̀ rí, si oriṣa ti o hù ni titun, ti awọn baba nyin kò bẹ̀ru. Apata ti o bi ọ ni iwọ kò ranti, iwọ si ti gbagbé Ọlọrun ti o dá ọ. OLUWA si ri i, o si korira wọn, nitori ìwa-imunibinu awọn ọmọkunrin rẹ̀, ati ti awọn ọmọbinrin rẹ̀. O si wipe, Emi o pa oju mi mọ́ kuro lara wọn, emi o si ma wò bi igbẹhin wọn yio ti ri; nitori iran alagídi ni nwọn, awọn ọmọ ninu ẹniti kò sí igbagbọ.
Deu 32:1-20 Yoruba Bible (YCE)
Ó ní: “Tẹ́tísílẹ̀, ìwọ ọ̀run, mo fẹ́ sọ̀rọ̀; gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ, ìwọ ayé. Kí ẹ̀kọ́ mi kí ó máa rọ̀ bí òjò, àní, bí ọ̀wààrà òjò tíí dẹ ewébẹ̀ lọ́rùn; kí ó sì máa sẹ̀ bí ìrì, bí òjò wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ tíí tu koríko lára. Nítorí pé n óo polongo orúkọ OLUWA, àwọn eniyan rẹ yóo sì sọ nípa títóbi rẹ̀. “Pípé ni iṣẹ́ ọwọ́ OLUWA, àpáta ààbò yín, gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀tọ́. Olódodo ni Ọlọrun, ẹni tí kì í ṣe àṣìṣe, ẹ̀tọ́ ní í máa ń ṣe nígbà gbogbo. Ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Israẹli ti hu ìwà aiṣododo sí i, ẹ kò sì yẹ ní ẹni tí à bá máa pè ní ọmọ rẹ̀ mọ́, nítorí àbùkù yín; ẹ̀yin ìran ọlọ̀tẹ̀ ati ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí. Ṣé irú ohun tí ó yẹ kí ẹ fi san án fún OLUWA nìyí, ẹ̀yin ìran òmùgọ̀ ati aláìnírònú ẹ̀dá wọnyi? Ṣebí òun ni baba yín, tí ó da yín, Tí ó da yín tán, tí ó sì fi ìdí yín múlẹ̀. “Ẹ ranti ìgbà àtijọ́, ẹ ṣe akiyesi ọpọlọpọ ọdún tí ó ti kọjá. Ẹ bèèrè lọ́wọ́ baba yín, yóo fihàn yín, Ẹ bi àwọn àgbààgbà yín, wọn yóo sì sọ fun yín. Nígbà tí Ọlọrun ọ̀gá ògo pín ilẹ̀ ìní fún àwọn orílẹ̀-èdè, ó ṣètò ibi tí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan yóo máa gbé, gẹ́gẹ́ bí ìdílé kọ̀ọ̀kan láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Nítorí pé ìpín OLUWA ni àwọn eniyan rẹ̀, ó yan àwọn ọmọ Jakọbu ní ohun ìní fún ara rẹ̀. “Ninu aṣálẹ̀ ni ó ti rí wọn, níbi tí kò sí igi tabi koríko, àfi kìkì yanrìn. Ó yí wọn ká, ó sì ń tọ́jú wọn, Ó sì dáàbò bò wọ́n bí ẹyin ojú rẹ̀. Bí ẹyẹ idì tií tú ìtẹ́ rẹ̀ ká, láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ bí à á tíí fò, tíí sì í na apá rẹ̀ láti hán wọn tí wọ́n bá fẹ́ já bọ́, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ń ṣe sí Israẹli. OLUWA nìkan ṣoṣo ni ó ṣáájú àwọn eniyan rẹ̀, láìsí ìrànlọ́wọ́ oriṣa kankan. “Ó fi wọ́n jọba lórí àwọn òkè ayé, ó sì fún wọn ní èso ilẹ̀ jẹ. Ó pèsè oyin fún wọn láti inú àpáta, ó sì mú kí igi olifi hù fún wọn lórí ilẹ̀ olókùúta. Wọn rí ọpọlọpọ wàrà lára mààlúù wọn, ati ọ̀pọ̀ omi wàrà lára ewúrẹ́ wọn, ó fún wọn ní ọ̀rá ọ̀dọ́ aguntan ati ti àgbò, ó fún wọn ní mààlúù Baṣani, ati ewúrẹ́, ati ọkà tí ó dára jùlọ, ati ọpọlọpọ ọtí waini. “Ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Jeṣuruni, ẹ yó tán, ẹ wá tàpá sí àṣẹ; ẹ rí jẹ, ẹ rí mu, ẹ sì lókun lára; ẹ wá gbàgbé Ọlọrun tí ó da yín, ẹ sì ń pẹ̀gàn àpáta ìgbàlà yín! Wọ́n fi ìbọ̀rìṣà wọn sọ OLUWA di òjòwú; wọ́n fi ìwà burúkú wọn mú kí ibinu OLUWA wọn ru sókè. Wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí rúbọ sí àwọn ẹ̀mí burúkú, Àwọn oriṣa tí wọn kò mọ̀ rí, tí àwọn baba wọn kò sì bọ rí. Ẹ gbàgbé àpáta ìgbàlà yín, ẹ gbàgbé Ọlọrun tí ó da yín. “Nígbà tí OLUWA rí ohun tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣe, ó kọ̀ wọ́n sílẹ̀, nítorí pé, wọ́n mú un bínú. Ó ní, ‘N óo mójú kúrò lára wọn, n óo sì máa wò bí ìgbẹ̀yìn wọn yóo ti rí. Nítorí olóríkunkun ni wọ́n, àwọn alaiṣootọ ọmọ!
Deu 32:1-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Fetísílẹ̀, Ẹ̀yin ọ̀run, èmi yóò sọ̀rọ̀; ẹ gbọ́, ìwọ ayé, ọ̀rọ̀ ẹnu mi. Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ ọ̀ mi máa rọ̀ bí òjò, kí àwọn ọ̀rọ̀ mi máa sọ̀kalẹ̀ bí ìrì, bí òjò wíníwíní sára ewéko tuntun, bí ọ̀wààrà òjò sára ohun ọ̀gbìn. Èmi yóò kókìkí orúkọ OLúWA, Háà, ẹ yin títóbi Ọlọ́run wa! Òun ni àpáta, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ pípé, gbogbo ọ̀nà an rẹ̀ jẹ́ òdodo. Ọlọ́run olóòtítọ́ tí kò ṣe àṣìṣe kan, Ó dúró ṣinṣin, òdodo àti òtítọ́ ni òun. Wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìbàjẹ́ sọ́dọ̀ ọ rẹ̀; fún ìtìjú u wọn, wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ìran tí ó yí sí apá kan tí ó sì dorí kodò. Ṣé báyìí ni ẹ̀yin yóò ṣe san an fún OLúWA, Háà, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìgbọ́n ènìyàn? Ǹjẹ́ òun kọ́ ni baba yín, Ẹlẹ́dàá yín, tí ó dá a yín tí ó sì mọ yín? Rántí ìgbà láéláé; wádìí àwọn ìran tí ó ti kọjá. Béèrè lọ́wọ́ baba à rẹ yóò sì sọ fún ọ, àwọn àgbàgbà rẹ, wọn yóò sì ṣàlàyé fún ọ. Nígbà tí Ọ̀gá-ògo fi ogún àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn, nígbà tí ó pín onírúurú ènìyàn, ó sì gbé ààlà kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iye ọmọkùnrin Israẹli. Nítorí ìpín OLúWA ni àwọn ènìyàn an rẹ̀, Jakọbu ni ìpín ìní i rẹ̀. Ní aginjù ni ó ti rí i, ní aginjù níbi tí ẹranko kò sí. Ó yíká, ó sì tọ́jú rẹ̀, ó pa á mọ́ bí ẹyin ojú u rẹ̀. Bí idì ti í ru ìtẹ́ rẹ̀ ti ó sì ń rábàbà sórí ọmọ rẹ̀, tí ó na ìyẹ́ apá rẹ̀ láti gbé wọn ki ó sì gbé wọn sórí ìyẹ́ apá rẹ̀. OLúWA ṣamọ̀nà; kò sì sí ọlọ́run àjèjì pẹ̀lú rẹ̀. Ó mú gun ibi gíga ayé ó sì fi èso oko bọ́ ọ. Ó sì jẹ́ kí ó mú oyin láti inú àpáta wá, àti òróró láti inú akọ òkúta wá, Pẹ̀lú u wàràǹkàṣì àti wàrà àgùntàn àti ti àgbò ẹran àti pẹ̀lú ọ̀rá ọ̀dọ́-àgùntàn àti ewúrẹ́, pẹ̀lú àgbò irú u ti Baṣani tí ó sì mu ẹ̀jẹ̀ èso àjàrà, àní àti wáìnì. Jeṣuruni sanra tán ó sì tàpá; ìwọ sanra tán, ìwọ ki tan, ọ̀rá sì bò ọ́ tán. O kọ Ọlọ́run tí ó dá ọ o sì kọ àpáta ìgbàlà rẹ. Wọ́n sì fi òrìṣà mú un jowú, ohun ìríra ni wọ́n fi mú un bínú. Wọ́n rú ẹbọ sí iwin búburú, tí kì í ṣe Ọlọ́run, ọlọ́run tí wọn kò mọ̀ rí, ọlọ́run tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ farahàn láìpẹ́, ọlọ́run tí àwọn baba yín kò bẹ̀rù. Ìwọ kò rántí àpáta, tí ó bí ọ; o sì gbàgbé Ọlọ́run tí ó dá ọ. OLúWA sì rí èyí ó sì kọ̀ wọ́n, nítorí tí ó ti bínú nítorí ìwà ìmúnibínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ. Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú mi mọ́ kúrò lára wọn, èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí; nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí, àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú wọn.