Deu 29:1-29

Deu 29:1-29 Bibeli Mimọ (YBCV)

WỌNYI li ọ̀rọ majẹmu ti OLUWA palaṣẹ fun Mose lati bá awọn ọmọ Israeli dá ni ilẹ Moabu, lẹhin majẹmu ti o ti bá wọn dá ni Horebu. Mose si pè gbogbo awọn ọmọ Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti ri ohun gbogbo ti OLUWA ṣe li oju nyin ni ilẹ Egipti si Farao, ati si gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ati si ilẹ rẹ̀ gbogbo. Idanwò nla ti oju rẹ ti ri, iṣẹ-àmi, ati iṣẹ-iyanu nla wọnni: Ṣugbọn OLUWA kò fun nyin li àiya lati mọ̀, ati oju lati ri, ati etí lati gbọ́ titi di oni yi. Emi si ti mu nyin rìn li ogoji ọdún li aginjù: aṣọ nyin kò gbó mọ́ nyin li ara, bàta nyin kò si gbó mọ́ nyin ni ẹsẹ̀. Ẹnyin kò jẹ àkara, bẹ̃li ẹnyin kò mu ọti-waini, tabi ọti lile: ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe emi li OLUWA Ọlọrun nyin. Nigbati ẹnyin ti dé ihinyi, Sihoni ọba Hesboni, ati Ogu ọba Baṣani, jade ogun si wa, awa si kọlù wọn: Awa si gbà ilẹ wọn, a si fi i fun awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse ni iní. Nitorina, ẹ pa ọ̀rọ majẹmu yi mọ́, ki ẹ si ma ṣe wọn, ki ẹnyin ki o le ma ri ire ninu ohun gbogbo ti ẹnyin nṣe. Gbogbo nyin li o duro li oni niwaju OLUWA Ọlọrun nyin; awọn olori nyin, awọn ẹ̀ya nyin, awọn àgba nyin, ati awọn ijoye nyin, ani gbogbo awọn ọkunrin Israeli, Awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, awọn aya nyin, ati alejò rẹ, ti mbẹ lãrin ibudó rẹ, lati aṣẹgi rẹ dé apọnmi rẹ: Ki iwọ ki o le wọ̀ inu majẹmu OLUWA Ọlọrun rẹ, ati ibura rẹ̀, ti OLUWA Ọlọrun rẹ bá ọ ṣe li oni: Ki o le fi idi rẹ kalẹ li oni li enia kan fun ara rẹ̀, ati ki on ki o le ma ṣe Ọlọrun rẹ, bi o ti sọ fun ọ, ati bi o ti bura fun awọn baba rẹ, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu. Ki si iṣe ẹnyin nikan ni mo bá ṣe majẹmu yi ati ibura yi; Ṣugbọn ẹniti o bá wa duro nihin li oni niwaju OLUWA Ọlọrun wa, ẹniti kò sí nihin pẹlu wa li oni: (Nitoripe ẹnyin mọ̀ bi awa ti gbé ilẹ Egipti; ati bi awa ti kọja lãrin orilẹ-ède ti ẹnyin là kọja; Ẹnyin si ti ri ohun irira wọn, ati ere wọn, igi ati okuta, fadakà ati wurà, ti o wà lãrin wọn.) Ki ẹnikẹni ki o má ba wà ninu nyin, ọkunrin, tabi obinrin, tabi idile, tabi ẹ̀ya, ti àiya rẹ̀ ṣí kuro lọdọ OLUWA Ọlọrun wa li oni, lati lọ isìn oriṣa awọn orilẹ-ède wọnyi; ki gbòngbo ti nyọ orõro ati iwọ, ki o má ba wà ninu nyin; Yio si ṣe, nigbati o ba gbọ́ ọ̀rọ egún yi, ti o sure fun ara rẹ̀ ninu àiya rẹ̀, wipe, Emi o ní alafia, bi emi tilẹ nrìn ninu agídi ọkàn mi, lati run tutù pẹlu gbigbẹ: OLUWA ki yio darijì i, ṣugbọn nigbana ni ibinu OLUWA ati owú rẹ̀ yio gbona si ọkunrin na, ati gbogbo egún wọnyi ti a kọ sinu iwé yi ni yio bà lé e, OLUWA yio si nù orukọ rẹ̀ kuro labẹ ọrun. OLUWA yio si yà a si ibi kuro ninu gbogbo ẹ̀ya Israeli, gẹgẹ bi gbogbo egún majẹmu, ti a kọ sinu iwé ofin yi. Ati iran ti mbọ̀, awọn ọmọ nyin ti yio dide lẹhin nyin, ati alejò ti yio ti ilẹ jijìn wá, yio si wi, nigbati nwọn ba ri iyọnu ilẹ na, ati àrun na, ti OLUWA mu bá a; Ati pe gbogbo ilẹ rẹ̀ di imi-õrùn, ati iyọ̀, ati ijóna, ti a kò le gbìn nkan si, tabi ti kò le seso, tabi ti koriko kò le hù ninu rẹ̀, bi ibìṣubu Sodomu, ati Gomorra, Adma, ati Seboiimu, ti OLUWA bìṣubu ninu ibinu rẹ̀, ati ninu ikannu rẹ̀: Ani gbogbo orilẹ-ède yio ma wipe, Ẽṣe ti OLUWA fi ṣe bayi si ilẹ yi? Kili a le mọ̀ õru ibinu nla yi si? Nwọn o si wipe, Nitoriti nwọn kọ̀ majẹmu OLUWA, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, ti o ti bá wọn dá nigbati o mú wọn lati ilẹ Egipti jade wá. Nitoriti nwọn lọ, nwọn si bọ oriṣa, nwọn si tẹriba fun wọn, oriṣa ti nwọn kò mọ̀ rí, ti on kò si fi fun wọn. Ibinu OLUWA si rú si ilẹ na, lati mú gbogbo egún ti a kọ sinu iwé yi wá sori rẹ̀: OLUWA si fà wọn tu kuro ni ilẹ wọn ni ibinu, ati ni ikannu, ati ni irunu nla, o si lé wọn lọ si ilẹ miran, bi o ti ri li oni yi. Ti OLUWA Ọlọrun wa ni ohun ìkọkọ: ṣugbọn ohun ti afihàn ni tiwa ati ti awọn ọmọ wa lailai, ki awa ki o le ma ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi.

Deu 29:1-29 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA pàṣẹ fún Mose pé kí ó bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu mìíràn ní ilẹ̀ Moabu, yàtọ̀ sí èyí tí ó ti bá wọn dá ní òkè Horebu. Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ti rí gbogbo ohun tí OLUWA ṣe sí Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati gbogbo ilẹ̀ rẹ̀, ní ilẹ̀ Ijipti. Ẹ fi ojú yín rí àwọn ìdààmú ńláńlá tí ó bá wọn, ati àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá tí OLUWA ṣe. Ṣugbọn títí di òní yìí, OLUWA kò tíì jẹ́ kí òye ye yín, ojú yín kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni etí yín kò gbọ́ràn. Odidi ogoji ọdún ni mo fi ko yín la ààrin aṣálẹ̀ kọjá. Aṣọ kò gbó mọ yín lára, bẹ́ẹ̀ ni bàtà kò gbó mọ yín lẹ́sẹ̀. Ẹ kò jẹ oúnjẹ gidi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mu ọtí waini tabi ọtí líle, kí ẹ lè mọ̀ pé OLUWA ni OLUWA Ọlọrun yín. Nígbà tí ẹ dé ibí yìí, Sihoni, ọba Heṣiboni ati Ogu, ọba Baṣani gbógun tì wá, ṣugbọn a ṣẹgun wọn. A gba ilẹ̀ wọn, a sì fi fún ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase, gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwọn. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ máa tẹ̀lé majẹmu yìí, kí ohun gbogbo tí ẹ bá dáwọ́lé lè máa yọrí sí rere. “Gbogbo yín pátá ni ẹ dúró níwájú OLUWA Ọlọrun yín lónìí, ati gbogbo àwọn olórí ninu àwọn ẹ̀yà yín, ati àwọn àgbààgbà ati àwọn olóyè ati àwọn ọkunrin Israẹli. Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín, àwọn aya yín, ati àwọn àlejò tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ yín; àwọn tí wọn ń wá igi fun yín, ati àwọn tí wọn ń pọnmi fun yín. Kí gbogbo yín lè bá OLUWA Ọlọrun yín dá majẹmu lónìí, kí ó lè fi ìdí yín múlẹ̀ bí eniyan rẹ̀, kí ó sì máa jẹ́ Ọlọrun yín; gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín, ati bí ó ti búra fún Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu àwọn baba ńlá yín. ‘Kìí ṣe ẹ̀yin nìkan ni mò ń bá dá majẹmu yìí, tí mo sì ń búra fún, ṣugbọn ati àwọn tí wọn kò sí níhìn-ín lónìí, ati ẹ̀yin alára tí ẹ dúró níwájú OLUWA Ọlọrun yín lónìí, ni majẹmu náà wà fún.’ “Ẹ̀yin náà mọ̀ bí ayé wa ti rí ní ilẹ̀ Ijipti, ati bí a ti la ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí a gbà kọjá. Ẹ sì ti rí àwọn ohun ìríra wọn: àwọn oriṣa wọn tí wọ́n fi igi gbẹ́, èyí tí wọ́n fi òkúta gbẹ́, èyí tí wọ́n fi fadaka ṣe, ati èyí tí wọ́n fi wúrà ṣe. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí á má ṣe rí ẹnikẹ́ni ninu yín, kì báà ṣe ọkunrin tabi obinrin, tabi ìdílé kan, tabi ẹ̀yà kan, tí ọkàn rẹ̀ yóo yipada kúrò lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun yín lónìí, tí yóo sì lọ máa bọ àwọn oriṣa tí àwọn orílẹ̀-èdè náà ń bọ. Nítorí pé, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóo dàbí igi tí ń so èso tí ó korò, tí ó sì ní májèlé ninu. Kí irú ẹni tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ majẹmu má baà dá ara rẹ̀ lọ́kàn le pé ‘Kò séwu, bí mo bá fẹ́ mo lè ṣe orí kunkun kí n sì máa tẹ̀lé ìmọ̀ ara mi.’ Èyí yóo kó ìparun bá gbogbo yín, ati àwọn tí wọn ń ṣe ibi ati àwọn tí wọn ń ṣe rere. OLUWA kò ní dáríjì olúwarẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ibinu ńlá OLUWA ni yóo bá a. Gbogbo àwọn ègún tí a kọ sinu ìwé yìí yóo ṣẹ sí i lára, OLUWA yóo sì pa orúkọ olúwarẹ̀ rẹ́ kúrò láyé. OLUWA yóo dojú kọ òun nìkan, láti ṣe é ní ibi láàrin gbogbo ẹ̀yà Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ègún tí ó wà ninu majẹmu, tí a kọ sinu ìwé òfin yìí. “Nígbà tí àwọn arọmọdọmọ yín tí wọn kò tíì bí, ati àwọn àlejò tí wọ́n bá wá láti ilẹ̀ òkèèrè bá rí ìpọ́njú, ati àrùn tí OLUWA yóo dà bo ilẹ̀ náà, tí wọ́n bá rí i tí gbogbo ilẹ̀ náà ti di imí ọjọ́ ati iyọ̀, tí gbogbo rẹ di eérú, tí koríko kankan kò lè hù lórí rẹ̀, bíi ìlú Sodomu ati Gomora, Adima ati Seboimu, tí OLUWA fi ibinu ńlá parẹ́, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni yóo máa bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi sọ ilẹ̀ yìí dà báyìí? Kí ló dé tí ibinu ńlá OLUWA fi dé sórí ilẹ̀ yìí?’ Àwọn eniyan yóo sì máa dáhùn pé, ‘Nítorí pé wọn kò mú majẹmu OLUWA Ọlọrun ṣẹ, tí ó bá àwọn baba wọn dá nígbà tí ó kó wọn jáde ní ilẹ̀ Ijipti. Wọ́n ń bọ àwọn oriṣa tí wọn kò mọ̀ rí, tí OLUWA kò sì fi lé wọn lọ́wọ́. Ìdí nìyí tí inú fi bí OLUWA sí ilẹ̀ yìí, tí ó sì mú gbogbo ègún tí a kọ sinu ìwé yìí ṣẹ lé wọn lórí. OLUWA sì fi ibinu ńlá ati ìrúnú lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn, ó sì fọ́n wọn dà sórí ilẹ̀ mìíràn gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí.’ “Àwọn nǹkan àṣírí mìíràn wà, tí kò hàn sí eniyan àfi OLUWA Ọlọrun wa nìkan, ṣugbọn àwọn nǹkan tí ó fihàn wá jẹ́ tiwa ati ti àwọn ọmọ wa títí lae, kí á lè máa ṣe àwọn nǹkan tí ó wà ninu ìwé òfin yìí.

Deu 29:1-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èyí ni àwọn ìpinnu májẹ̀mú tí OLúWA pàṣẹ fún Mose láti ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli ní Moabu, ní àfikún májẹ̀mú tí ó ti ṣe pẹ̀lú u wọn ní Horebu. Mose pàṣẹ fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ó sì wí fún wọn wí pé: Ojú rẹ ti rí gbogbo ohun tí OLúWA ti ṣe ní Ejibiti sí Farao àti, sí gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀ àti sí ilẹ̀ ẹ rẹ̀. Pẹ̀lú ojú ara rẹ ni ìwọ rí àwọn ìdánwò ńlá náà, àwọn iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá. Ṣùgbọ́n títí di àsìkò yìí OLúWA kò fi ọkàn ìmòye tàbí ojú tí ó ń rí tàbí etí tí ó n gbọ́ fún ọ. Nígbà ogójì ọdún tí mò ń tọ́ yín ṣọ́nà ní aginjù, aṣọ ọ̀ rẹ kò gbó tàbí bàtà ẹsẹ̀ rẹ. O kò jẹ oúnjẹ tàbí mu wáìnì kankan tàbí rú ohun mímu mìíràn. Mo ṣe èyí kí o lè mọ̀ pé èmi ni OLúWA Ọlọ́run rẹ. Nígbà tí o dé ibí yìí, Sihoni ọba Heṣboni àti Ogu ọba Baṣani jáde wá láti bá ọ jà, ṣùgbọ́n a ṣẹ́gun wọn. A gba ilẹ̀ wọn a sì fi fún àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase bí ogún. Nítorí náà, ẹ pa májẹ̀mú yìí mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n, kí ẹ̀yin kí ó lè máa rí ire nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe. Gbogbo yín ń dúró lónìí yìí níwájú OLúWA Ọlọ́run rẹ: àwọn olórí yín, àwọn ẹ̀yà yín, àwọn àgbàgbà yín àti àwọn ìjòyè yín, àní gbogbo àwọn ọkùnrin mìíràn ní Israẹli, pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ọ̀ rẹ àti ìyàwó ò rẹ àti àwọn àjèjì tí wọ́n ń gbé ní àgọ́ ọ̀ rẹ, tí ó ké pópòpó igi rẹ, tí ó sì gbé omi rẹ. O dúró níhìn-ín yìí kí o lè wọ inú májẹ̀mú pẹ̀lú OLúWA Ọlọ́run rẹ, májẹ̀mú tí OLúWA ń ṣe pẹ̀lú rẹ lónìí yìí àti tí òun dè pẹ̀lú ìbúra, láti jẹ́wọ́ rẹ lónìí yìí bí ènìyàn an rẹ̀, pé kí ó lè jẹ́ Ọlọ́run rẹ bí ó ti ṣèlérí àti bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba à rẹ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu. Èmi ń ṣe májẹ̀mú yìí, pẹ̀lú ìbúra rẹ̀, kì í ṣe fún ìwọ nìkan tí ó dúró níbí pẹ̀lú wa lónìí níwájú OLúWA Ọlọ́run wa ṣùgbọ́n àti fún gbogbo àwọn tí kò sí níbí lónìí. Ìwọ fúnra à rẹ mọ bí a ṣe gbé ní Ejibiti àti bí a ṣe kọjá láàrín àwọn orílẹ̀-èdè nílẹ̀ ibí yìí. Ìwọ rí láàrín wọn ìríra wọn, àwọn ère àti àwọn òrìṣà igi àti ti òkúta, ti fàdákà àti ti wúrà. Rí i dájú pé kò sí ọkùnrin tàbí obìnrin, ìdílé tàbí ẹ̀yà láàrín yín lónìí tí ọkàn an rẹ̀ yóò yí kúrò lọ́dọ̀ OLúWA Ọlọ́run wa láti lọ àti láti sin àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè náà; rí i dájú pé kò sí gbòǹgbò tí ó ń mú irú èso kíkan bẹ́ẹ̀ jáde láàrín yín. Nígbà tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá gbọ́ ìbúra yìí, kí ó gbàdúrà ìbùkún sórí ara rẹ̀ nígbà náà ni kí ó ronú, “Èmi yóò wà ní àlàáfíà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fi àáké kọ́rí nípa lílọ nínú ọ̀nà ti ara à mi.” Èyí yóò mú àjálù wá sórí ilẹ̀ tútù àti sórí ilẹ̀ gbígbẹ bákan náà OLúWA kì yóò ní ìfẹ́ sí àti dáríjì í; ìbínú àti ìtara rẹ̀ yóò jó ọkùnrin náà. Gbogbo àwọn ègún tí a kọ sínú ìwé yìí yóò wá sórí i rẹ̀, OLúWA yóò sì yọ orúkọ rẹ̀ kúrò lábẹ́ ọ̀run. OLúWA yóò sì yọ òun nìkan kúrò nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli fún àjálù, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ègún májẹ̀mú tí a kọ sí inú ìwé òfin yìí. Àwọn ọmọ rẹ tí ó tẹ̀lé ìran rẹ lẹ́yìn àti àwọn àjèjì tí ó wá láti ilẹ̀ jíjìn yóò rí wàhálà tí ó wá sórí ilẹ̀ àti àwọn ààrùn pẹ̀lú tí OLúWA mú bá ọ. Gbogbo ilẹ̀ náà yóò di imí-oòrùn, àti iyọ̀, àti ìjóná tí a kò lè fi ọkàn sí, tàbí tí kò lè so èso tàbí tí koríko kò lè hù nínú u rẹ̀, yóò dàbí ìbìṣubú Sodomu àti Gomorra, Adma àti Ṣeboimu, tí OLúWA bì ṣubú nínú ìbínú rẹ̀, àti ìkáàánú rẹ̀. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóò béèrè pé, “Kí ló dé tí OLúWA fi ṣe èyí sí ilẹ̀ yìí? Kí ni a lè mọ ooru ìbínú ńlá yìí sí?” Ìdáhùn yóò sì jẹ́ báyìí: “Nítorí tí ènìyàn yìí kọ OLúWA Ọlọ́run baba wọn sílẹ̀, májẹ̀mú tí ó ti bá wọn dá nígbà tí ó mú wọn jáde wá láti Ejibiti. Wọ́n lọ wọ́n sì sin ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún wọn, ọlọ́run tí wọn kò mọ̀, ọlọ́run tí kò fi fún wọn. Nígbà náà ni ìbínú OLúWA ru sí ilẹ̀ wọn, dé bi pé ó mú gbogbo ègún tí a kọ sínú ìwé yìí wá sórí i rẹ̀. Ní ìbínú àti ní ìkáàánú, àti ní ìrunú ńlá, OLúWA sì fà wọ́n tu kúrò ní ilẹ̀ wọn, ó sì lé wọn lọ sí ilẹ̀ mìíràn, bí ó ti rí ní òní yìí.” Ohun ìkọ̀kọ̀ jẹ́ ti OLúWA Ọlọ́run wa, ṣùgbọ́n ohun tí a fihàn jẹ́ ti wa àti ti àwọn ọmọ wa títí láé, kí a lè tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí.