Deu 24:1-4
Deu 24:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
BI ọkunrin kan ba fẹ́ obinrin kan, ti o si gbé e niyawo, yio si ṣe, bi obinrin na kò ba ri ojurere li oju ọkunrin na, nitoriti o ri ohun alebù kan lara rẹ̀: njẹ ki o kọ iwé ikọsilẹ fun obinrin na, ki o fi i lé e lọwọ, ki o si rán a jade kuro ninu ile rẹ̀. Nigbati on ba si jade kuro ninu ile rẹ̀, on le lọ, ki o ma ṣe aya ọkunrin miran. Bi ọkọ rẹ̀ ikẹhin ba si korira rẹ̀, ti o si kọ iwé ikọsilẹ fun u, ti o si fi i lé e lọwọ, ti o si rán a jade kuro ninu ile rẹ̀; tabi bi ọkọ ikẹhin ti o fẹ́ ẹ li aya ba kú; Ọkọ rẹ̀ iṣaju, ti o rán a jade kuro, ki o máṣe tun ní i li aya lẹhin ìgba ti o ti di ẹni-ibàjẹ́ tán; nitoripe irira ni niwaju OLUWA: iwọ kò si gbọdọ mu ilẹ na ṣẹ̀, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní.
Deu 24:1-4 Yoruba Bible (YCE)
“Bí ọkunrin kan bá fẹ́ iyawo, tí iyawo náà kò bá wù ú mọ́ nítorí pé ó rí ohun àléébù kan ninu ìwà rẹ̀ tí kò tẹ́ ẹ lọ́rùn; tí ó bá já ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, tí obinrin náà jáde kúrò ní ilé rẹ̀, tí obinrin náà sì bá tirẹ̀ lọ; bí obinrin yìí bá lọ ní ọkọ mìíràn, ṣugbọn tí kò tún wu ọkọ titun náà, tí òun náà tún já ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, tí ó sì tún tì í jáde kúrò ninu ilé rẹ̀, tabi tí ọkọ keji tí obinrin yìí fẹ́ bá kú, ọkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ kò gbọdọ̀ gbà á pada mọ́ nítorí pé obinrin náà ti di aláìmọ́. Ohun ìríra ni èyí lójú OLUWA. Ẹ kò gbọdọ̀ dá irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín.
Deu 24:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ obìnrin kan, tí ó sì gbe ní ìyàwó, yóò sì ṣe, bí obìnrin náà kò bá rí ojúrere ní ojú ọkùnrin náà, nítorí ó rí ohun àìtọ́ kan lára rẹ̀, ǹjẹ́ kí ó kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún obìnrin náà, kí ó sì fi lé e lọ́wọ́, kí ó sì ran jáde kúrò nínú ilé rẹ̀, tí ó bá di ìyàwó ọkùnrin mìíràn lẹ́yìn ìgbà tí ó kúrò nílé rẹ, àti tí ọkọ rẹ̀ kejì kò bá fẹ́ràn rẹ̀ tí ó sì kọ ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ sí i, kí ó fi fún un kí ó sì lé e kúrò nílé e rẹ̀, tàbí tí ọkọ rẹ̀ kejì bá kú, nígbà náà ni ọkọ, tí ó ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kò gbọdọ̀ fẹ́ ẹ mọ́ lẹ́yìn tí ó ti di àìmọ́. Nítorí èyí ni ìríra níwájú OLúWA. Má ṣe mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sórí ilẹ̀ tí OLúWA Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ bí ogún.