Deu 23:21 - Compare All Versions

Deu 23:21 YBCV (Bibeli Mimọ)

Nigbati iwọ ba jẹ́jẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o máṣe fàsẹhin lati san a: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ yio bère rẹ̀ nitõtọ lọwọ rẹ; yio si di ẹ̀ṣẹ si ọ lọrùn.

Deu 23:21 YCE (Yoruba Bible)

“Nígbà tí ẹ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, ẹ kò gbọdọ̀ má san ẹ̀jẹ́ náà, nítorí OLUWA Ọlọrun yín yóo bèèrè rẹ̀ lọ́wọ́ yín, yóo sì di ẹ̀ṣẹ̀ sí yín lọ́rùn bí ẹ kò bá san án.

Deu 23:21 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Bí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLúWA Ọlọ́run rẹ, má ṣe lọ́ra láti san án, nítorí OLúWA Ọlọ́run rẹ yóò béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, o sì máa jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀.