Deu 15:6 - Compare All Versions

Deu 15:6 YBCV (Bibeli Mimọ)

Nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ yio busi i fun ọ, bi o ti ṣe ileri fun ọ: iwọ o si ma wín ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède, ṣugbọn iwọ ki yio tọrọ; iwọ o si ma ṣe olori ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède, ṣugbọn nwọn ki yio ṣe olori rẹ.

Deu 15:6 YCE (Yoruba Bible)

Nítorí OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín. Ẹ óo máa yá àwọn orílẹ̀-èdè ni nǹkan, ṣugbọn ẹ kò ní tọrọ lọ́wọ́ wọn. Ẹ óo máa jọba lórí ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, ṣugbọn wọn kò ní jọba lórí yín.

Deu 15:6 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Nítorí pé OLúWA Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín bí ó ti ṣèlérí, ẹ̀yin yóò sì máa yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ẹ kì yóò sì tọrọ. Ẹ ó ṣàkóso ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n kò sí orílẹ̀-èdè tí yóò lè jẹ ọba lé e yín lórí.