Dan 7:1-14
Dan 7:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI ọdun kini Belṣassari, ọba Babeli, ni Danieli lá alá, ati iran ori rẹ̀ lori akete rẹ̀: nigbana ni o kọwe alá na, o si sọ gbogbo ọ̀rọ na. Danieli dahùn, o si wipe, Mo ri ni iran mi li oru, si kiyesi i, afẹfẹ mẹrẹrin ọrun njà loju okun nla. Ẹranko mẹrin nla si ti inu okun jade soke, nwọn si yatọ si ara wọn. Ẹranko kini dabi kiniun, o si ni iyẹ-apa idì: mo si wò titi a fi fà iyẹ-apa rẹ̀ wọnni tu, a si gbé e soke kuro ni ilẹ, a mu ki o fi ẹsẹ duro bi enia, a si fi aiya enia fun u. Sa si kiyesi, ẹranko miran, ekeji, ti o dabi ẹranko beari, o si gbé ara rẹ̀ soke li apakan, o si ni egungun-ìha mẹta lẹnu rẹ̀ larin ehin rẹ̀: nwọn si wi fun u bayi pe, Dide ki o si jẹ ẹran pipọ. Lẹhin eyi, mo ri, si kiyesi i, ẹranko miran, gẹgẹ bi ẹkùn, ti o ni iyẹ-apa ẹiyẹ mẹrin li ẹhin rẹ̀; ẹranko na ni ori mẹrin pẹlu; a si fi agbara ijọba fun u. Lẹhin eyi, mo ri ni iran oru, si kiyesi i, ẹranko kẹrin ti o burujù, ti o si lẹrù, ti o si lagbara gidigidi; o si ni ehin irin nla: o njẹ o si nfọ tũtu, o si fi ẹsẹ rẹ̀ tẹ̀ iyokù mọlẹ: o si yatọ si gbogbo awọn ẹranko ti o ṣiwaju rẹ̀; o si ni iwo mẹwa. Mo si kiyesi awọn iwo na, si wò o, iwo kekere miran kan si jade larin wọn, niwaju eyiti a fa mẹta tu ninu awọn iwo iṣaju: si kiyesi i, oju gẹgẹ bi oju enia wà lara iwo yi, ati ẹnu ti nsọ ohun nlanlà. Mo si wò titi a fi sọ̀ itẹ́ wọnni kalẹ titi Ẹni-àgba ọjọ na fi joko, aṣọ ẹniti o fún gẹgẹ bi ẹ̀gbọn owu, irun ori rẹ̀ si dabi irun agutan ti o mọ́: itẹ rẹ̀ jẹ ọwọ iná, ayika-kẹkẹ rẹ̀ si jẹ jijo iná. Iṣàn iná nṣẹyọ, o si ntu jade lati iwaju rẹ̀ wá; awọn ẹgbẹ̃gbẹrun nṣe iranṣẹ fun u, ati awọn ẹgbẹgbarun nigba ẹgbarun duro niwaju rẹ̀: awọn onidajọ joko, a si ṣi iwe wọnni silẹ. Nigbana ni mo wò nitori ohùn ọ̀rọ nla ti iwo na nsọ: mo si wò titi a fi pa ẹranko na, a si pa ara rẹ̀ run, a si sọ ọ sinu ọwọ iná ti njo. Bi o ṣe ti awọn ẹranko iyokù ni, a ti gba agbara wọn kuro: nitori a ti yàn akokò ati ìgba fun wọn bi olukulùku yio ti pẹ tó. Mo ri ni iran oru, si kiyesi i, ẹnikan bi Ọmọ enia wá pẹlu awọsanma ọrun, o si wá sọdọ Ẹni-Àgba ọjọ na, nwọn si mu u sunmọ iwaju rẹ̀. A si fi agbara ijọba fun u, ati ogo, ati ijọba, ki gbogbo enia, ati orilẹ, ati ède, ki o le ma sìn i; agbara ijọba rẹ̀ si jẹ agbara ijọba ainipẹkun, eyiti a kì yio rekọja, ati ijọba rẹ̀, eyiti a kì yio le parun.
Dan 7:1-14 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọdún kinni tí Beṣasari jọba ní Babiloni, Daniẹli lá àlá, o sì rí àwọn ìran kan nígbà tí ó sùn lórí ibùsùn rẹ̀. Ó bá kọ kókó ohun tí ó rí lójú àlá náà sílẹ̀. Ó ní, “Bí mo ti sùn ní alẹ́, mo rí i lójúran pé afẹ́fẹ́ tí ń fẹ́ láti igun mẹrẹẹrin ayé ń rú omi òkun ńlá sókè. Àwọn ẹranko ńláńlá mẹrin bá jáde láti inú òkun. Ọ̀kan kò jọ̀kan ni àwọn mẹrẹẹrin. Ekinni dàbí kinniun, ó sì ní ìyẹ́ bíi ti idì. Mò ń wò ó títí tí ìyẹ́ rẹ̀ fi fà tu. A gbé e dìde lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ mejeeji bí eniyan. Ó sì ń ronú bí eniyan. “Ẹranko keji dàbí àmọ̀tẹ́kùn, ó gbé ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kan sókè. Ó gbé egungun ìhà mẹta há ẹnu, ó wa eyín mọ́ ọn. Mo sì gbọ́ tí ẹnìkan sọ fún un pé, ‘Dìde, kí o sì máa jẹ ẹran sí i.’ “Bí mo ti ń wò mo tún rí ẹranko mìíràn tí ó dàbí ẹkùn, òun náà ní ìyẹ́ mẹrin lẹ́yìn. Ó ní orí mẹrin. A sì fún un ní agbára láti jọba. “Lẹ́yìn èyí, ninu ìran tí mo rí ní òru náà, ẹranko kẹrin tí mo rí jáni láyà, ó bani lẹ́rù, ó sì lágbára pupọ. Ó tóbi, irin sì ni eyín rẹ̀. A máa fọ́ nǹkan túútúú, á jẹ ẹ́ ní àjẹrun, á sì fi ẹsẹ̀ tẹ àjẹkù rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀, ìwo mẹ́wàá ni ó ní. Bí mo ti ń ronú nípa àwọn ìwo rẹ̀, ni mo rí i tí ìwo kékeré kan tún hù láàrin wọn, ìwo mẹta fà tu níwájú rẹ̀ ninu àwọn ìwo ti àkọ́kọ́. Ìwo kékeré yìí ní ojú bí eniyan, ó sì ní ẹnu tí ó fi ń sọ ọ̀rọ̀ ńláńlá. “Bí mo ti ń wo ọ̀kánkán, mo rí àwọn ìtẹ́ kan tí a tẹ́. Ẹni Ayérayé sì jókòó lórí ìtẹ́ tirẹ̀, aṣọ rẹ̀ funfun bíi ẹ̀gbọ̀n òwú. Irun orí rẹ̀ náà dàbí irun aguntan funfun, ìtẹ́ rẹ̀ ń jó bí ahọ́n iná, kẹ̀kẹ́ abẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sì dàbí iná. Iná ń ṣàn jáde bí odò níwájú rẹ̀. Ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹrun ni àwọn tí ń ṣe iranṣẹ fún un, ọ̀kẹ́ àìmọye sì ni àwọn tí wọ́n dúró níwájú rẹ̀. Ìdájọ́ bẹ̀rẹ̀, a sì ṣí àwọn ìwé sílẹ̀. “Mo wò yíká nítorí ọ̀rọ̀ ńláńlá tí ìwo kékeré yìí ń fi ẹnu sọ, mo sì rí i tí wọ́n pa ẹranko náà, tí wọ́n sì jó òkú rẹ̀ níná. Ní ti àwọn ẹranko tí ó kù, a gba àṣẹ wọn, ṣugbọn a dá wọn sí fún àkókò kan, àní fún ìgbà díẹ̀. “Ninu ìran, lóru, mo rí ẹnìkan tí ó rí bí Ọmọ Eniyan ninu awọsanma, ó lọ sí ọ̀dọ̀ Ẹni Ayérayé náà, ó sì fi ara rẹ̀ hàn níwájú rẹ̀. A sì fún Ẹni Ayérayé ní àṣẹ, ògo ati ìjọba, pé kí gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà máa sìn ín. Àṣẹ ayérayé tí kò lè yẹ̀ ni àṣẹ rẹ̀, ìjọba rẹ̀ kò sì lè parun.
Dan 7:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọdún àkọ́kọ́ Belṣassari ọba Babeli, Daniẹli lá àlá kan, ìran náà sì wá sí ọkàn an rẹ̀ bí ó ṣe sùn sórí ibùsùn un rẹ̀, ó sì kọ àlá náà sílẹ̀. Daniẹli sọ pé, “Nínú ìran mi lóru mo wò ó, mo sì rí afẹ́fẹ́ ọ̀run mẹ́rin tí ó ń ru omi Òkun ńlá sókè. Ẹranko ńlá mẹ́rin tí ó yàtọ̀ sí ara wọn, jáde láti inú Òkun náà. “Ẹranko kìn-ín-ní dàbí i kìnnìún, ó sì ní ìyẹ́ apá a idì: mo sì wò títí a fi fa ìyẹ́ apá rẹ̀ náà tu, a sì gbé e sókè kúrò ní ilẹ̀, a mú kí ó fi ẹsẹ̀ dúró bí ènìyàn, a sì fi àyà ènìyàn fún un. “Mo sì tún rí ẹranko kejì, ó rí bí irú ẹranko ńlá beari kan tí ó ń gbé ilẹ̀ òtútù; o gbé ara sókè ní apá kan, ó sì ní egungun ìhà mẹ́ta láàrín ẹ̀yìn in rẹ̀, wọ́n sì sọ fún un pé, ‘Dìde kí o sì jẹ ẹran tó pọ̀!’ “Lẹ́yìn ìgbà náà, mo tún rí ẹranko kẹta ó rí bí àmọ̀tẹ́kùn. Ẹranko náà ní ìyẹ́ bí i ti ẹyẹ ní ẹ̀yìn, ó sì ní orí mẹ́rin, a sì fún un ní agbára láti ṣe ìjọba. “Lẹ́yìn èyí, nínú ìran mi ní òru mo tún rí ẹranko kẹrin, ó dẹ́rùbà ni, ó dáyà fo ni, ó sì lágbára gidigidi. Ó ní eyín irin ńlá; ó ń jẹ, ó sì ń fọ́ túútúú, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tókù mọ́lẹ̀. Ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko ti ìṣáájú, ó sì ní ìwo mẹ́wàá. “Bí mo ṣe ń ronú nípa ìwo náà, nígbà náà ni mo rí ìwo mìíràn, tí ó kéré tí ó jáde wá ní àárín wọn; mẹ́ta lára àwọn ìwo ti àkọ́kọ́ sì fàtu níwájú u rẹ̀. Ìwo yìí ní ojú bí i ojú ènìyàn àti ẹnu tí ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga. “Bí mo ṣe ń wò, “a gbé ìtẹ́ ọba kan kalẹ̀, ẹni ìgbàanì jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú; irun orí rẹ̀ funfun bí òwú, ìtẹ́ ọba rẹ̀ rí bí ọwọ́ iná. Àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ ń jó bí i iná. Odò iná ń sàn, ó ń jáde ní iwájú rẹ̀ wá, Àwọn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún un; Ọ̀nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún nígbà ẹgbàárùn-ún dúró níwájú rẹ̀. Àwọn onídàájọ́ jókòó, a sì ṣí ìwé wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀. “Nígbà náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ní wò, nítorí àwọn ọ̀rọ̀ ìgbéraga tí ìwo náà ń sọ, mo wò títí a fi pa ẹranko náà, a sì pa á run, a sì jù ú sínú iná tí ń jó. A sì gba ìjọba lọ́wọ́ àwọn ẹranko yòókù, ṣùgbọ́n a fún wọn láààyè láti wà fún ìgbà díẹ̀. “Nínú ìran mi ní òru mo wò, mo rí ẹnìkan tí ó dúró sí iwájú u mi, ó rí bí Ọmọ ènìyàn, ó ń bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ ọ̀run, ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ ẹni ìgbàanì, a sì mú u wá sí iwájú rẹ̀. A sì fi ìjọba, ògo àti agbára ilẹ̀ ọba fún un; gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè àti èdè gbogbo wọn wólẹ̀ fún un. Ìjọba rẹ̀, ìjọba ayérayé ni, èyí tí kò le è kọjá, ìjọba rẹ̀ kò sì le è díbàjẹ́ láéláé.