Dan 5:1-4
Dan 5:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
BELṢASSARI, ọba se àse nla fun ẹgbẹrun awọn ijoye rẹ̀, o si nmu ọti-waini niwaju awọn ẹgbẹrun na. Bi Belṣassari ti tọ́ ọti-waini na wò, o paṣẹ pe ki nwọn ki o mu ohun-elo wura, ati ti fadaka wá, eyiti Nebukadnessari baba rẹ̀, kó jade lati inu tempili ti o wà ni Jerusalemu wá, ki ọba, ati awọn ijoye rẹ̀, awọn aya rẹ̀, ati awọn àle rẹ̀, ki o le ma muti ninu wọn. Nigbana ni nwọn mu ohun-elo wura ti a ti kó jade lati inu tempili ile Ọlọrun ti o wà ni Jerusalemu wá; ọba, ati awọn ijoye rẹ̀, awọn aya rẹ̀, ati awọn àle rẹ̀, si nmuti ninu wọn. Nwọn nmu ọti-waini, nwọn si nkọrin ìyin si awọn oriṣa wura, ati ti fadaka, ti idẹ, ti irin, ti igi, ati ti okuta.
Dan 5:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kan, Beṣasari ọba, se àsè ńlá kan fún ẹgbẹrun (1,000) ninu àwọn ìjòyè rẹ̀, ó sì ń mu ọtí níwájú wọn. Nígbà tí ó tọ́ ọtí náà wò, ó pàṣẹ pé kí wọn kó àwọn ife wúrà ati ti fadaka tí Nebukadinesari, baba rẹ̀, kó wá láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu jáde, kí òun, ati àwọn ìjòyè òun, àwọn ayaba ati àwọn obinrin òun lè máa fi wọ́n mu ọtí. Wọ́n bá kó àwọn ife wúrà ati ti fadaka tí wọ́n kó ninu tẹmpili ní Jerusalẹmu jáde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n mu ọtí. Bí wọn tí ń mu ọtí, ni wọ́n ń yin ère wúrà, ère fadaka, ère irin, ère igi, ati ère òkúta.
Dan 5:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Belṣassari, ọba ṣe àsè ńlá fún ẹgbẹ̀rún (1,000) kan nínú àwọn ọlọ́lá rẹ̀, ó sì mu wáìnì pẹ̀lú u wọn. Bí Belṣassari ṣe ń mu wáìnì, ó pàṣẹ pé kí wọn kó kọ́ọ̀bù wúrà àti ti fàdákà wá, èyí tí Nebukadnessari baba rẹ̀ kó wá láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu, kí ọba àti àwọn ọlọ́lá rẹ̀, àwọn ìyàwó àti àwọn àlè rẹ̀ kí ó ba à le fi mu wáìnì. Wọ́n sì kó kọ́ọ̀bù wúrà àti fàdákà àti fàdákà èyí tí wọ́n kó jáde láti inú tẹmpili, ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àwọn ìyàwó àti àwọn àlè rẹ̀, sì fi mu wáìnì. Bí wọ́n ṣe ń mu wáìnì bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń yin òrìṣà wúrà àti fàdákà, ti idẹ, irin, igi àti òkúta.