Dan 2:10-16
Dan 2:10-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn Kaldea si dahùn niwaju ọba, nwọn si wipe, kò si ẹnikan ti o wà li aiye ti o le fi ọ̀ran ọba hàn: kò si si ọba, oluwa, tabi ijoye kan ti o bère iru nkan bẹ̃ lọwọ amoye, tabi ọlọgbọ́n, tabi Kaldea kan ri. Ohun ti o tilẹ ṣọwọ́n ni ọba bère, kò si si ẹlomiran ti o le fi i hàn niwaju ọba bikoṣe awọn oriṣa, ibugbe ẹniti kì iṣe ninu ẹran-ara. Nitori ọ̀ran yi ni inu ọba fi bajẹ, o si binu gidigidi, o si paṣẹ pe ki nwọn ki o pa gbogbo awọn amoye Babeli run. Nigbana ni aṣẹ jade lọ pe, ki nwọn ki o pa awọn amoye; nwọn si nwá Danieli pẹlu awọn ẹgbẹ́ rẹ̀ lati pa wọn. Nigbana ni Danieli fi ìmọ ati ọgbọ́n dahùn wi fun Arioku, ti iṣe balogun ẹṣọ ọba, ẹniti nlọ pa awọn amoye Babeli. O dahùn o si wi fun Arioku, balogun ọba pe, Ẽṣe ti aṣẹ fi yá kánkán lati ọdọ ọba wá bẹ̃? Nigbana ni Arioku fi nkan na hàn fun Danieli. Nigbana ni Danieli wọle lọ, o si bère lọwọ ọba pe, ki o fi akokò fun on, o si wipe, on o fi itumọ rẹ̀ hàn fun ọba.
Dan 2:10-16 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ẹni náà láyé yìí, tí ó lè sọ ohun tí kabiyesi fẹ́ kí á sọ, kò sí ọba ńlá tabi alágbára kankan tí ó tíì bèèrè irú nǹkan yìí lọ́wọ́ pidánpidán kan, tabi lọ́wọ́ àwọn aláfọ̀ṣẹ, tabi lọ́wọ́ àwọn ará Kalidea rí. Ohun tí ọba ń bèèrè yìí le pupọ, kò sí ẹni tí ó lè ṣe é, àfi àwọn oriṣa, nítorí pé àwọn kì í ṣe ẹlẹ́ran ara.” Nítorí náà inú ọba ru, ó sì bínú gidigidi, ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run. Àṣẹ jáde lọ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n; wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wá Daniẹli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti pa wọ́n. Daniẹli bá lọ sí ọ̀dọ̀ Arioku, tí ọba pàṣẹ fún pé kí ó pa àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni; ó fi ọgbọ́n ati ìrẹ̀lẹ̀ bá a sọ̀rọ̀, ó ní, “Kí ló dé tí àṣẹ ọba fi le tó báyìí?” Arioku bá sọ bí ọ̀rọ̀ ti rí fún un. Lẹsẹkẹsẹ, Daniẹli lọ bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ọba pé kí ó dá àkókò fún òun, kí òun lè wá rọ́ àlá náà fún ọba, kí òun sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.
Dan 2:10-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn awòràwọ̀ sì dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ènìyàn kan ní ayé tí ó lè sọ nǹkan tí ọba béèrè! Kò sí ọba náà bí ó ti wù kí ó tóbi àti kí ó lágbára tó, tí í béèrè irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tàbí awòràwọ̀. Nǹkan tí ọba béèrè yìí ṣòro púpọ̀. Kò sí ẹni tí ó lè fihan ọba àfi àwọn òrìṣà, tí wọn kì í gbé láàrín ènìyàn.” Èyí mú kí ọba bínú, ó sì kanra, nítorí náà ó pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn amòye Babeli run. Nítorí náà àṣẹ yìí jáde lọ wí pé kí a pa àwọn amòye, wọ́n ránṣẹ́ pe Daniẹli pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ láti pa wọ́n. Nígbà tí Arioku, olórí àwọn olùṣọ́ ọba, jáde láti lọ pa àwọn amòye Babeli, Daniẹli sọ̀rọ̀ fún un pẹ̀lú ọgbọ́n àti òye. Ó béèrè lọ́wọ́ olórí àwọn olùṣọ́ ọba wí pé, “Èéṣe tí àṣẹ ọba fi yá kánkán bẹ́ẹ̀?” Arioku sì ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ náà fún Daniẹli. Nígbà náà ni Daniẹli wọlé tọ ọba lọ, ó sì tọrọ kí ọba fún òun ní ààyè, òun yóò fi ìtumọ̀ àlá náà hàn fún ọba.