Kol 4:7-9
Kol 4:7-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gbogbo bi nkan ti ri fun mi ni Tikiku yio jẹ́ ki ẹ mọ̀, arakunrin olufẹ ati olõtọ iranṣẹ, ati ẹlẹgbẹ ninu Oluwa: Ẹniti mo ti rán si nyin nitori eyi kanna, ki ẹnyin le mọ̀ bi a ti wà, ki on ki o le tù ọkàn nyin ninu; Pẹlu Onesimu, arakunrin olõtọ ati olufẹ, ẹniti iṣe ọ̀kan ninu nyin. Awọn ni yio sọ ohun gbogbo ti a nṣe nihinyi fun nyin.
Kol 4:7-9 Yoruba Bible (YCE)
Tukikọsi, àyànfẹ́ ati arakunrin wa, yóo fun yín ní ìròyìn nípa mi. Iranṣẹ tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni ati ẹrú bí àwa náà ninu iṣẹ́ Oluwa. Nítorí èyí gan-an ni mo fi rán an wá sọ́dọ̀ yín, kí ẹ lè mọ bí gbogbo nǹkan ti ń lọ fún wa, kí ó lè fi ọkàn yín balẹ̀. Mo tún rán Onisimu, ọ̀kan ninu yín, tí òun náà jẹ́ àyànfẹ́ ati arakunrin tí ó sì ṣe é gbẹ́kẹ̀lé. Gbogbo bí nǹkan bá ti rí níhìn-ín ni wọn óo ròyìn fun yín.
Kol 4:7-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbogbo bí nǹkan ti rí fún mi ní Tikiku yóò jẹ́ kí ẹ mọ̀. Òun jẹ́ arákùnrin olùfẹ́ àti olóòtítọ́ ìránṣẹ́ àti ẹlẹgbẹ́ nínú Olúwa: Ẹni tí èmí ń rán sí yín nítorí èyí kan náà, kí ẹ̀yin lè mọ́ bí a ti wà, kí òun kí ó lè tu ọkàn yín nínú; Òun sì ń bọ̀ pẹ̀lú Onesimu, arákùnrin olóòtítọ́ àti olùfẹ́, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú yín. Àwọn ní yóò sọ ohun gbogbo tí à ń ṣe níhìn-ín-yìí fún un yín.