Kol 4:7-12
Kol 4:7-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gbogbo bi nkan ti ri fun mi ni Tikiku yio jẹ́ ki ẹ mọ̀, arakunrin olufẹ ati olõtọ iranṣẹ, ati ẹlẹgbẹ ninu Oluwa: Ẹniti mo ti rán si nyin nitori eyi kanna, ki ẹnyin le mọ̀ bi a ti wà, ki on ki o le tù ọkàn nyin ninu; Pẹlu Onesimu, arakunrin olõtọ ati olufẹ, ẹniti iṣe ọ̀kan ninu nyin. Awọn ni yio sọ ohun gbogbo ti a nṣe nihinyi fun nyin. Aristarku, ẹlẹgbẹ mi ninu tubu ki nyin, ati Marku, ọmọ arabinrin Barnaba (nipasẹ ẹniti ẹnyin ti gbà aṣẹ: bi o ba si wá sọdọ nyin, ẹ gbà a), Ati Jesu, ẹniti a npè ni Justu, ẹniti iṣe ti awọn onila. Awọn wọnyi nikan ni olubaṣiṣẹ mi fun ijọba Ọlọrun, awọn ẹniti o ti jasi itunu fun mi. Epafra, ẹniti iṣe ọkan ninu nyin, iranṣẹ Kristi, kí nyin, on nfi iwaya-ija gbadura nigbagbogbo fun nyin, ki ẹnyin ki o le duro ni pipé ati ni kíkun ninu gbogbo ifẹ Ọlọrun.
Kol 4:7-12 Yoruba Bible (YCE)
Tukikọsi, àyànfẹ́ ati arakunrin wa, yóo fun yín ní ìròyìn nípa mi. Iranṣẹ tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni ati ẹrú bí àwa náà ninu iṣẹ́ Oluwa. Nítorí èyí gan-an ni mo fi rán an wá sọ́dọ̀ yín, kí ẹ lè mọ bí gbogbo nǹkan ti ń lọ fún wa, kí ó lè fi ọkàn yín balẹ̀. Mo tún rán Onisimu, ọ̀kan ninu yín, tí òun náà jẹ́ àyànfẹ́ ati arakunrin tí ó sì ṣe é gbẹ́kẹ̀lé. Gbogbo bí nǹkan bá ti rí níhìn-ín ni wọn óo ròyìn fun yín. Arisitakọsi, ẹlẹ́wọ̀n, ẹlẹgbẹ́ mi ki yín, ati Maku, ìbátan Banaba. Ẹ ti rí ìwé gbà nípa rẹ̀. Tí ó bá dé ọ̀dọ̀ yín, kí ẹ gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀. Jesu tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Jusitu náà ki yín. Àwọn yìí nìkan ni wọ́n kọlà ninu àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi ninu iṣẹ́ ìjọba Ọlọrun. Ìtùnú ni wọ́n jẹ́ fún mi. Epafirasi, iranṣẹ Kristi Jesu, ọ̀kan ninu yín, ki yín. Nígbà gbogbo ni ó ń gbadura kíkankíkan fun yín, pé kí ẹ lè dúró ní pípé ati pé kí ẹ lè kún fún gbogbo ohun tíí ṣe ìfẹ́ Ọlọrun.
Kol 4:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbogbo bí nǹkan ti rí fún mi ní Tikiku yóò jẹ́ kí ẹ mọ̀. Òun jẹ́ arákùnrin olùfẹ́ àti olóòtítọ́ ìránṣẹ́ àti ẹlẹgbẹ́ nínú Olúwa: Ẹni tí èmí ń rán sí yín nítorí èyí kan náà, kí ẹ̀yin lè mọ́ bí a ti wà, kí òun kí ó lè tu ọkàn yín nínú; Òun sì ń bọ̀ pẹ̀lú Onesimu, arákùnrin olóòtítọ́ àti olùfẹ́, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú yín. Àwọn ní yóò sọ ohun gbogbo tí à ń ṣe níhìn-ín-yìí fún un yín. Aristarku, ẹlẹgbẹ́ mí nínú túbú kí i yín, àti Marku, ọmọ arábìnrin Barnaba (Nípasẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ti gba àṣẹ; bí ó bá sì wá sí ọ̀dọ̀ yín, ẹ gbà á). Àti Jesu, ẹni tí à ń pè ní Justu, ẹni tí ń ṣe ti àwọn onílà. Àwọn wọ̀nyí nìkan ni olùbáṣiṣẹ́ mí fún ìjọba Ọlọ́run, àwọn ẹni tí ó tí jásí ìtùnú fún mi. Epafira, ẹni tí ń ṣe ọ̀kan nínú yín àti ìránṣẹ́ Kristi Jesu kí i yín. Òun fi ìwàyáàjà gbàdúrà nígbà gbogbo fún un yín, kí ẹ̀yin kí ó lè dúró ní pípé nínú ohun gbogbo nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.