Kol 3:5-7
Kol 3:5-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina ẹ mã pa ẹ̀ya-ara nyin ti mbẹ li aiye run: àgbere, iwa-ẽri, ifẹkufẹ, ifẹ buburu, ati ojukòkoro, ti iṣe ibọriṣa: Nitori ohun tí ibinu Ọlọrun fi mbọ̀wa sori awọn ọmọ alaigbọran. Ninu eyiti ẹnyin pẹlu ti nrìn nigbakan rí, nigbati ẹnyin ti wà ninu nkan wọnyi.
Kol 3:5-7 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, ẹ pa àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀yà ara yín ti ayé run: àwọn bíi àgbèrè, ìwà èérí, ìṣekúṣe, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ati ojúkòkòrò tíí ṣe ìbọ̀rìṣà. Nítorí nǹkan wọnyi ni ibinu Ọlọrun ṣe ń bọ̀. Ẹ̀yin náà ti wà lára irú àwọn eniyan wọnyi nígbà kan rí, nígbà tí ẹ̀yin náà ń ṣe nǹkan wọnyi.
Kol 3:5-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ máa pa ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ ní ayé run: àgbèrè, panṣágà, ìwà àìmọ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwọra, nítorí pé ìwọ̀nyí jásí ìbọ̀rìṣà. Lórí àwọn wọ̀nyí ni ìbínú Ọlọ́run ń bọ̀ wá. Ẹ máa ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀ nígbà tí ìgbé ayé yín sì jẹ́ apá kan ayé yìí.