Kol 3:1-4
Kol 3:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ bi a ba ti ji nyin dide pẹlu Kristi, ẹ mã ṣafẹri awọn nkan ti mbẹ loke, nibiti Kristi gbé wà ti o joko li ọwọ́ ọtun Ọlọrun. Ẹ mã ronu awọn nkan ti mbẹ loke kì iṣe awọn nkan ti mbẹ li aiye. Nitori ẹnyin ti kú, a si fi ìye nyin pamọ́ pẹlu Kristi ninu Ọlọrun. Nigbati Kristi, ẹniti iṣe ìye wa yio farahàn, nigbana li ẹnyin pẹlu o farahàn pẹlu rẹ̀ ninu ogo.
Kol 3:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, bí a bá ti ji yín dìde pẹlu Kristi, ẹ máa lépa àwọn ohun tí ó wà lọ́run níbi tí Kristi wà, tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun. Ẹ máa lépa àwọn ohun tí ó wà lọ́run, ẹ má lépa àwọn ohun tí ó wà láyé. Nítorí ẹ ti kú, ẹ̀mí yín wà ní ìpamọ́ pẹlu Kristi ninu Ọlọrun. Nígbà tí Kristi, ẹni tíí ṣe ẹ̀mí yín bá farahàn, ẹ̀yin náà yóo farahàn pẹlu rẹ̀ ninu ògo.
Kol 3:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Níwọ́n ìgbà tí a ti jí yín dìde pẹ̀lú Kristi ẹ máa ṣàfẹ́rí àwọn nǹkan tí ń bẹ lókè, níbi tí Kristi gbé wà tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. Ẹ máa ronú àwọn ohun tí ń bẹ lókè kì í ṣe àwọn nǹkan tí ń bẹ ní ayé. Nítorí ẹ̀yin ti kú, a sì fi ìyè yín pamọ́ pẹ̀lú Kristi nínú Ọlọ́run. Nígbà tí Kristi, ẹni tí í ṣe ìyè yín yóò farahàn, nígbà náà ni ẹ̀yin pẹ̀lú yóò farahàn pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo.