Kol 2:6-17
Kol 2:6-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina bi ẹnyin ti gbà Kristi Jesu Oluwa, bẹ̃ni ki ẹ mã rìn ninu rẹ̀: Ki ẹ fi gbongbo mulẹ, ki a si gbe nyin ro ninu rẹ̀, ki ẹ si fi ẹsẹ mulẹ ninu igbagbọ nyin, gẹgẹ bi a ti kọ́ nyin, ki ẹ si mã pọ̀ ninu rẹ̀ pẹlu idupẹ. Ẹ mã kiyesara ki ẹnikẹni ki o máṣe fi ìmọ ati ẹ̀tan asan dì nyin ni igbekun, gẹgẹ bi itan enia, gẹgẹ bi ipilẹṣẹ ẹkọ aiye, ti ki iṣe bi ti Kristi. Nitoripe ninu rẹ̀ ni gbogbo ẹ̀kún Iwa-Ọlọrun ngbé li ara-iyara. A si ti ṣe nyin ni kikún ninu rẹ̀, ẹniti iṣe ori fun gbogbo ijọba ati agbara: Ninu ẹniti a ti fi ikọla ti a kò fi ọwọ kọ kọ nyin ni ila, ni bibọ ara ẹ̀ṣẹ silẹ, ninu ikọla Kristi: Bi a si ti sin nyin pọ̀ pẹlu rẹ̀ ninu baptismu, ninu eyiti a si ti jí nyin dide pẹlu rẹ̀ nipa igbagbọ́ ninu iṣẹ Ọlọrun, ẹniti o jí i dide kuro ninu okú. Ati ẹnyin, ẹniti o ti kú nitori ẹ̀ṣẹ nyin ati aikọla ara nyin, mo ni, ẹnyin li o si ti sọdi ãye pọ̀ pẹlu rẹ̀, o si ti dari gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin; O si ti pa iwe majẹmu nì rẹ́, ti o lodi si wa, ti a kọ ninu ofin, eyiti o lodi si wa: on li o si ti mu kuro loju ọ̀na, o si kàn a mọ agbelebu; O si ti já awọn ijọba ati agbara kuro li ara rẹ̀, o si ti dojuti wọn ni gbangba, o nyọ̀ ayọ̀ iṣẹgun lori wọn ninu rẹ̀. Nitorina ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni mã ṣe idajọ nyin niti jijẹ, tabi niti mimu, tabi niti ọjọ ase, tabi oṣù titun, tabi ọjọ isimi: Awọn ti iṣe ojiji ohun ti mbọ̀; ṣugbọn ti Kristi li ara.
Kol 2:6-17 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gba Kristi Jesu bí Oluwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín ni ìrẹ́pọ̀ pẹlu rẹ̀. Kí ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀, kí ẹ máa dàgbà ninu rẹ̀, kí ẹ sì jẹ́ kí igbagbọ yín dúró ṣinṣin bí ẹ ti kọ́ láti ṣe, kí ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ayé ati ìtànjẹ lásán sọ yín di ẹrú gẹ́gẹ́ bí àṣà eniyan, ati ìlànà àwọn ẹ̀mí tí a kò fi ojú rí, tí ó yàtọ̀ sí ètò ti Kristi. Nítorí pé ninu Kristi tí ó jẹ́ eniyan ni ohun tí Ọlọrun fúnrarẹ̀ jẹ́, ń gbé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Ó sì ti ṣe yín ní pípé ninu rẹ̀. Òun níí ṣe orí fún gbogbo àwọn ẹ̀mí ojú ọ̀run, ìbáà ṣe ìjọba tabi àwọn aláṣẹ. Ninu Kristi yìí ni a ti kọ yín nílà, kì í ṣe ilà tí a fi ọwọ́ kọ nípa gígé ẹran-ara kúrò, ṣugbọn ilà ti Kristi; nígbà tí a sin yín ninu omi ìrìbọmi, tí ẹ tún jinde nípa igbagbọ pẹlu agbára Ọlọrun tí ó jí Kristi dìde ninu òkú. Ẹ̀yin tí ẹ ti di òkú nípa ẹ̀ṣẹ̀ yín, tí ẹ jẹ́ aláìkọlà nípa ti ara, ni Ọlọrun ti sọ di alààyè pẹlu Kristi. Ọlọrun ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. Ó ti pa àkọsílẹ̀ tí ó lòdì sí wa rẹ́, ó mú un kúrò, ó kàn án mọ́ agbelebu. Ó gba agbára lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí ojú ọ̀run: ati ìjọba ni, ati àwọn alágbára wọ̀n-ọn-nì; ó bọ́ wọn síhòòhò, ó fi wọ́n ṣẹ̀sín ní gbangba, nígbà tí ó ti ṣẹgun wọn lórí agbelebu. Nítorí náà ẹ má gbà fún ẹnikẹ́ni kí ó máa darí yín nípa nǹkan jíjẹ tabi nǹkan mímu, tabi nípa ọ̀rọ̀ àjọ̀dún tabi ti oṣù titun tabi ti Ọjọ́ Ìsinmi. Àwọn nǹkan wọnyi jẹ́ àwòjíìjí ohun tí ó ń bọ̀, ṣugbọn nǹkan ti Kristi ni ó ṣe pataki.
Kol 2:6-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, bí ẹ̀yin ti gba Jesu Kristi gẹ́gẹ́ bí Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin máa gbé nínú rẹ̀. Ẹ fi gbòǹgbò múlẹ̀, kí a sì gbé yín ró nínú rẹ̀, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ yín, bí a ti kọ́ yín, àti kí ẹ sì máa pọ̀ nínú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́. Ẹ rí dájú pé ẹnikẹ́ni kò mú yin ní ìgbèkùn pẹ̀lú ẹ̀kọ́ àròsọ àti ìmọ̀ ẹ̀tàn, èyí tí ó gbára lé ìlànà ti ènìyàn àti àgbékalẹ̀ àwọn ẹ̀mí ayé yìí tí ó yàtọ̀ sí ti Kristi. Nítorí nínú Kristi ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwàláàyè Ọlọ́run gbé ní ara, ẹ̀yin sì ní ohun gbogbo ní kíkún nínú Kristi, ẹni tí i ṣe orí fún gbogbo agbára àti àṣẹ. Nínú ẹni tí a kò fi ìkọlà tí a fi ọwọ́ kọ kọ yín ní ilà, ni bíbọ ara ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, nínú ìkọlà Kristi. Bí a ti sin yín pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìtẹ̀bọmi, tí a sì ti jí yín dìde pẹ̀lú rẹ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú agbára Ọlọ́run, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú. Àti ẹ̀yin, ẹni tí ó ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti àìkọlà ará yín, mo ní, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín; Ó sì ti pa ìwé májẹ̀mú nì rẹ́, tí ó lòdì sí wa, tí a kọ nínú òfin, èyí tí o lòdì sí wa: òun ni ó sì ti mú kúrò lójú ọ̀nà, ó sì kàn án mọ àgbélébùú. Ó sì ti gba agbára kúrò lọ́wọ́ àwọn ìjọba ẹ̀mí búburú àti àwọn alágbára gbogbo, ó sì ti dójútì wọn ní gbangba, bí ó ti ń yọ̀ fún ìṣẹ́gun lórí wọn. Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣe ìdájọ́ yín ní ti jíjẹ, tàbí ní ti mímu, tàbí ní ti ọjọ́ àsè, tàbí oṣù tuntun, àti ọjọ́ ìsinmi: Àwọn tí í ṣe òjìji ohun tí ń bọ̀; ṣùgbọ́n ní ti òtítọ́, nínú Kristi ni àti mu wọn ṣẹ.