Kol 2:13-17
Kol 2:13-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati ẹnyin, ẹniti o ti kú nitori ẹ̀ṣẹ nyin ati aikọla ara nyin, mo ni, ẹnyin li o si ti sọdi ãye pọ̀ pẹlu rẹ̀, o si ti dari gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin; O si ti pa iwe majẹmu nì rẹ́, ti o lodi si wa, ti a kọ ninu ofin, eyiti o lodi si wa: on li o si ti mu kuro loju ọ̀na, o si kàn a mọ agbelebu; O si ti já awọn ijọba ati agbara kuro li ara rẹ̀, o si ti dojuti wọn ni gbangba, o nyọ̀ ayọ̀ iṣẹgun lori wọn ninu rẹ̀. Nitorina ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni mã ṣe idajọ nyin niti jijẹ, tabi niti mimu, tabi niti ọjọ ase, tabi oṣù titun, tabi ọjọ isimi: Awọn ti iṣe ojiji ohun ti mbọ̀; ṣugbọn ti Kristi li ara.
Kol 2:13-17 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin tí ẹ ti di òkú nípa ẹ̀ṣẹ̀ yín, tí ẹ jẹ́ aláìkọlà nípa ti ara, ni Ọlọrun ti sọ di alààyè pẹlu Kristi. Ọlọrun ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. Ó ti pa àkọsílẹ̀ tí ó lòdì sí wa rẹ́, ó mú un kúrò, ó kàn án mọ́ agbelebu. Ó gba agbára lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí ojú ọ̀run: ati ìjọba ni, ati àwọn alágbára wọ̀n-ọn-nì; ó bọ́ wọn síhòòhò, ó fi wọ́n ṣẹ̀sín ní gbangba, nígbà tí ó ti ṣẹgun wọn lórí agbelebu. Nítorí náà ẹ má gbà fún ẹnikẹ́ni kí ó máa darí yín nípa nǹkan jíjẹ tabi nǹkan mímu, tabi nípa ọ̀rọ̀ àjọ̀dún tabi ti oṣù titun tabi ti Ọjọ́ Ìsinmi. Àwọn nǹkan wọnyi jẹ́ àwòjíìjí ohun tí ó ń bọ̀, ṣugbọn nǹkan ti Kristi ni ó ṣe pataki.
Kol 2:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àti ẹ̀yin, ẹni tí ó ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti àìkọlà ará yín, mo ní, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín; Ó sì ti pa ìwé májẹ̀mú nì rẹ́, tí ó lòdì sí wa, tí a kọ nínú òfin, èyí tí o lòdì sí wa: òun ni ó sì ti mú kúrò lójú ọ̀nà, ó sì kàn án mọ àgbélébùú. Ó sì ti gba agbára kúrò lọ́wọ́ àwọn ìjọba ẹ̀mí búburú àti àwọn alágbára gbogbo, ó sì ti dójútì wọn ní gbangba, bí ó ti ń yọ̀ fún ìṣẹ́gun lórí wọn. Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣe ìdájọ́ yín ní ti jíjẹ, tàbí ní ti mímu, tàbí ní ti ọjọ́ àsè, tàbí oṣù tuntun, àti ọjọ́ ìsinmi: Àwọn tí í ṣe òjìji ohun tí ń bọ̀; ṣùgbọ́n ní ti òtítọ́, nínú Kristi ni àti mu wọn ṣẹ.