Kol 1:9-13
Kol 1:9-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori eyi, lati ọjọ ti awa ti gbọ, awa pẹlu kò simi lati mã gbadura ati lati mã bẹ̀bẹ fun nyin pe ki ẹnyin ki o le kún fun ìmọ ifẹ rẹ̀ ninu ọgbọ́n ati imoye gbogbo ti iṣe ti Ẹmí; Ki ẹ le mã rìn ni yiyẹ niti Oluwa si ìwu gbogbo, ki ẹ ma so eso ninu iṣẹ rere gbogbo, ki ẹ si mã pọ si i ninu ìmọ Ọlọrun; Ki a fi ipá gbogbo sọ nyin di alagbara, gẹgẹ bi agbara ogo rẹ̀, sinu suru ati ipamọra gbogbo pẹlu ayọ̀; Ki a mã dupẹ lọwọ Baba, ẹniti o mu wa yẹ lati jẹ alabapin ninu ogún awọn enia mimọ́ ninu imọlẹ: Ẹniti o ti gbà wa kuro lọwọ agbara òkunkun, ti o si ṣi wa nipo sinu ijọba ayanfẹ ọmọ rẹ̀
Kol 1:9-13 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ ìròyìn yín, àwa náà kò sinmi láti máa gbadura fun yín. À ń bẹ̀bẹ̀ pé kí Ọlọrun lè jẹ́ kí ẹ mọ ìfẹ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pẹlu gbogbo ọgbọ́n, kí ó sì fun yín ní òye nípa nǹkan ti ẹ̀mí. A tún ń gbadura pé kí ìgbé-ayé yín lè jẹ́ èyí tí ó wu Oluwa lọ́nà gbogbo, kí iṣẹ́ rere yín máa pọ̀ sí i, kí ẹ máa tẹ̀síwájú ninu ìmọ̀ Ọlọrun. Ati pé kí Ọlọrun fun yín ní agbára gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ògo rẹ̀, kí ó fun yín ní ìfaradà ninu ohun gbogbo, pẹlu sùúrù ati ayọ̀. Kí ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba wa tí ó kà yín yẹ láti ní ìpín ninu ogún àwọn eniyan Ọlọrun ninu ìmọ́lẹ̀. Baba wa náà ni ó gbà wá lọ́wọ́ agbára òkùnkùn, ó sì mú wa wá sinu ìjọba àyànfẹ́ Ọmọ rẹ̀.
Kol 1:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ìdí èyí, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa yín, a kò sinmi láti máa gbàdúrà fún yin, tí a sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ìmọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ kún yín nípasẹ̀ ọgbọ́n àti òye gbogbo tí ń ṣe ti Ẹ̀mí. Àwa sì ń gbàdúrà yìí kí ẹ lè gbé irú ìgbé ayé tó yẹ fún Olúwa kí ẹ sì máa wu ú ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ sì máa so èso rere gbogbo, kí ẹ sì máa dàgbà nínú ìmọ̀ Ọlọ́run, pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀síwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀. Kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo lọ́wọ́ Baba, ẹni tí ó kà yín láti jẹ́ alábápín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́ nínú ìjọba ìmọ́lẹ̀. Nítorí tí ó ti já wa gbà kúrò nínú agbára òkùnkùn ó sì mú wa wá sí ìjọba Ọmọ tí ó fẹ́ràn.