Kol 1:6-8
Kol 1:6-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Eyiti o de ọdọ nyin, ani bi o ti nso eso pẹlu ni gbogbo aiye ti o si npọ si i, bi o ti nṣe ninu nyin pẹlu, lati ọjọ ti ẹnyin ti gbọ́, ti ẹnyin si ti mọ̀ ore-ọfẹ Ọlọrun li otitọ: Ani bi ẹnyin ti kọ́ lọdọ Epafra iranṣẹ ẹlẹgbẹ wa olufẹ, ẹniti iṣe olõtọ iranṣẹ Kristi nipo wa, Ti o si ròhin ifẹ nyin ninu Ẹmí fun wa pẹlu.
Kol 1:6-8 Yoruba Bible (YCE)
Ìyìn rere yìí ti dé ọ̀dọ̀ yín gẹ́gẹ́ bí ó ti dé ọ̀dọ̀ gbogbo aráyé, ó ń so èso, ó sì ń dàgbà. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí láàrin ẹ̀yin náà láti ọjọ́ tí ẹ ti gbọ́, tí ẹ sì ti mọ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun nítòótọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ ti kọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere lọ́dọ̀ Epafirasi, àyànfẹ́, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wa. Òun ni ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín ninu nǹkan ti ẹ̀mí.
Kol 1:6-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
èyí tí ó ti dé ọ̀dọ̀ yín. Káàkiri àgbáyé ni ìhìnrere yìí ń so èso tí ó sì ń dàgbà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe láàrín yín láti ọjọ́ náà tí ẹ ti gbọ́ ọ, tí ẹ sì ní ìmọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nínú gbogbo òtítọ́ rẹ̀. Ẹ̀yin ti kọ́ ọ lọ́dọ̀ Epafira, ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa olùfẹ́, ẹni tí ó jẹ́ olóòtítọ́ ìránṣẹ́ Kristi ní ipò wa. Ẹni ti ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín nínú ẹ̀mí.