Kol 1:26-27
Kol 1:26-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ani ohun ijinlẹ ti o ti farasin lati aiyeraiye ati lati irandiran, ṣugbọn ti a ti fihàn nisisiyi fun awọn enia mimọ́ rẹ̀: Awọn ẹniti Ọlọrun fẹ lati fi ọrọ̀ ohun ijinlẹ yi larin awọn Keferi hàn fun, ti iṣe Kristi ninu nyin, ireti ogo
Kol 1:26-27 Yoruba Bible (YCE)
Ìjìnlẹ̀ àṣírí nìyí, ó ti wà ní ìpamọ́ láti ìgbà àtijọ́ ati láti ìrandíran, ṣugbọn Ọlọrun fihan àwọn eniyan rẹ̀ ní àkókò yìí. Àwọn ni ó wu Ọlọrun pé kí wọ́n mọ ọlá ati ògo àṣírí yìí láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. Àṣírí náà ni pé, Kristi tí ó ń gbé inú yín ni ìrètí ògo.
Kol 1:26-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó ti pa àṣírí ìjìnlẹ̀ yìí mọ́ fún ayérayé àti láti ìrandíran. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, ó ti fihàn fún àwọn ẹni mímọ́. Àwọn ẹni tí Ọlọ́run yàn láti fihàn láàrín àwọn aláìkọlà nípa ọ̀rọ̀ ògo ohun ìjìnlẹ̀ yìí, èyí tí í ṣe Kristi ìrètí ògo nínú yín.