Kol 1:11-20

Kol 1:11-20 Yoruba Bible (YCE)

Ati pé kí Ọlọrun fun yín ní agbára gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ògo rẹ̀, kí ó fun yín ní ìfaradà ninu ohun gbogbo, pẹlu sùúrù ati ayọ̀. Kí ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba wa tí ó kà yín yẹ láti ní ìpín ninu ogún àwọn eniyan Ọlọrun ninu ìmọ́lẹ̀. Baba wa náà ni ó gbà wá lọ́wọ́ agbára òkùnkùn, ó sì mú wa wá sinu ìjọba àyànfẹ́ Ọmọ rẹ̀. Nípasẹ̀ ọmọ rẹ̀ yìí ni a fi ní ìdáǹdè, àní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa. Eniyan kò lè rí Ọlọrun, ṣugbọn ọmọ yìí ni àwòrán rẹ̀, òun ni àkọ́bí ohun gbogbo tí a dá. Nítorí pé, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti dá ohun gbogbo, lọ́run ati láyé: ati ohun tí a rí, ati ohun tí a kò rí, ìbáà ṣe ìtẹ́ ọba, tabi ìjọba, tabi àwọn alágbára, tabi àwọn aláṣẹ. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti dá gbogbo nǹkan, nítorí tirẹ̀ ni a sì ṣe dá wọn. Ó ti wà ṣiwaju ohun gbogbo. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni gbogbo nǹkan sì fi wà létò. Òun ni orí fún ara, tíí ṣe ìjọ. Òun ni ìbẹ̀rẹ̀, àkọ́bí tí a jí dìde láti inú òkú, kí ó lè wà ní ipò tí ó ga ju gbogbo nǹkan lọ. Nítorí ó wu Ọlọrun pé kí ohun tí Ọlọrun tìkararẹ̀ jẹ́ máa gbé inú rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Nípa rẹ̀ ni Ọlọrun ṣe gbogbo nǹkan lọ́kan pẹlu ara rẹ̀, kí alaafia lè dé nípa ikú rẹ̀ lórí agbelebu. Gbogbo nǹkan wá wà ní ìṣọ̀kan, ìbáà ṣe nǹkan ti ayé tabi àwọn nǹkan ti ọ̀run.

Kol 1:11-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀síwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀. Kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo lọ́wọ́ Baba, ẹni tí ó kà yín láti jẹ́ alábápín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́ nínú ìjọba ìmọ́lẹ̀. Nítorí tí ó ti já wa gbà kúrò nínú agbára òkùnkùn ó sì mú wa wá sí ìjọba Ọmọ tí ó fẹ́ràn. Nínú ẹni tí a ní ìràpadà, àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Kristi ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò le rí, àkọ́bí gbogbo ẹ̀dá. Nítorí nípa rẹ̀ ní a dá ohun gbogbo: àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti ní ayé, ohun tí a rí àti èyí tí a kò rí, wọn ìbá ṣe ìtẹ́, tàbí agbára, tàbí àṣẹ, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo àti fún un. Ó ti wà ṣáájú kí ohunkóhun tó wà, nínú rẹ̀ ni a sì so ohun gbogbo papọ̀ ṣọ̀kan. Òun ni orí fún ara, èyí tí í ṣe ìjọ; òun ni ìbẹ̀rẹ̀ àti àkọ́bí nínú àwọn òkú, pé nínú ohun gbogbo kí òun lè ní ipò tí ó ga jùlọ nínú ohunkóhun. Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òun tìkára rẹ̀ lè máa gbé nínú rẹ̀. Àti nípasẹ̀ rẹ̀ láti bá ohun gbogbo làjà àwọn nǹkan tí ń bẹ láyé àti èyí tí ń bẹ ní ọ̀run, nípa mímú àlàáfíà wá nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, tí a ta sílẹ̀ lórí igi àgbélébùú.