Amo 9:7-15
Amo 9:7-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin kò ha dàbi awọn ọmọ Etiopia si mi, Ẹnyin ọmọ Israeli? li Oluwa wi. Emi kò ha ti mu Israeli goke ti ilẹ Egipti jade wá? ati awọn Filistini lati ilẹ Kaftori, ati awọn ara Siria lati Kiri. Kiyesi i, Oluwa Ọlọrun mbẹ lara ilẹ ọba ti o kún fun ẹ̀ṣẹ, emi o si pa a run kuro lori ilẹ; ṣugbọn emi kì yio pa ile Jakobu run tan patapata, li Oluwa wi. Wò o, nitori emi o paṣẹ, emi o si kù ile Israeli ninu awọn orilẹ-ède, bi ã ti kù ọkà ninu kọ̀nkọsọ, ṣugbọn woro kikini kì yio bọ́ sori ilẹ. Gbogbo awọn ẹlẹṣẹ ninu enia mi yio ti ipa idà kú, ti nwipe, Ibi na kì yio le wa ba, bẹ̃ni kì yio ba wa lojijì. Li ọjọ na li emi o gbe agọ Dafidi ti o ṣubu ró, emi o si dí ẹya rẹ̀; emi o si gbe ahoro rẹ̀ soke, emi o si kọ́ ọ bi ti ọjọ igbani: Ki nwọn le ni iyokù Edomu ni iní, ati ti gbogbo awọn keferi, ti a pè nipa orukọ mi, li Oluwa ti o nṣe eyi wi. Kiyesi i, ọjọ na de, li Oluwa wi, ti ẹniti ntulẹ yio le ẹniti nkorè bá, ati ẹniti o ntẹ̀ eso àjara yio le ẹniti o nfunrùgbin bá; awọn oke-nla yio si kán ọti-waini didùn silẹ, gbogbo oke kékèké yio si di yiyọ́. Emi o si tun mu igbèkun Israeli enia mi padà bọ̀, nwọn o si kọ́ ahoro ilu wọnni, nwọn o si ma gbe inu wọn; nwọn o si gbin ọgbà-àjara, nwọn o si mu ọti-waini wọn; nwọn o ṣe ọgbà pẹlu, nwọn o si jẹ eso inu wọn. Emi o si gbìn wọn si ori ilẹ wọn, a kì yio si fà wọn tu mọ kuro ninu ilẹ wọn, ti mo ti fi fun wọn, li Oluwa Ọlọrun rẹ wi.
Amo 9:7-15 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun ní, “Ṣebí bí ẹ ti jẹ́ sí mi ni àwọn ará Etiopia náà jẹ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli? Àbí kì í ṣe bí mo ti mú àwọn ará Filistia jáde láti ìlú Kafitori, tí mo mú àwọn Siria jáde láti ìlú Kiri, ni mo mú ẹ̀yin náà jáde láti Ijipti. Wò ó! Èmi OLUWA Ọlọrun ti fojú sí orílẹ̀-èdè tí ń dẹ́ṣẹ̀ lára, n óo sì pa á run lórí ilẹ̀ ayé; ṣugbọn, n kò ní run gbogbo ìran Jakọbu. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “N óo pàṣẹ pé kí wọ́n gbo gbogbo Israẹli jìgìjìgì láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè, bí ìgbà tí wọ́n bá fi ajọ̀ ku èlùbọ́, ṣugbọn kóró kan kò ní bọ́ sílẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọn ń dẹ́ṣẹ̀ láàrin àwọn eniyan mi ni ogun yóo pa, gbogbo àwọn tí wọ́n ń sọ pé, ‘Ibi kankan kò ní bá wa!’ “Ní ọjọ́ náà, n óo gbé àgọ́ Dafidi tí ó ti wó ró. N óo tún odi rẹ̀ mọ, n óo tún un kọ́ yóo sì rí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí. Àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣẹgun àwọn tí wọ́n kù ní Edomu, ati gbogbo orílẹ̀-èdè tí à ń fi orúkọ mi pè. Èmi OLUWA, tí n óo ṣe bí mo ti wí, èmi ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Ọjọ́ ń bọ̀, tí ọkà yóo so jìnwìnnì, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè kórè rẹ̀ tán kí àkókò gbígbin ọkà mìíràn tó dé. Ọgbà àjàrà yóo so, tóbẹ́ẹ̀ tí a kò ní lè fi ṣe waini tán kí àkókò ati gbin òmíràn tó dé. Ọtí waini dídùn yóo máa kán sílẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, ọtí waini yóo sì máa ṣàn jáde lára àwọn òkè kéékèèké. N óo dá ire Israẹli, àwọn eniyan mi, pada, wọn yóo tún àwọn ìlú tí wọ́n ti wó kọ́, wọn yóo sì máa gbé inú wọn. Wọn yóo gbin àjàrà, wọn yóo sì mu ọtí waini rẹ̀. Wọn yóo ṣe ọgbà, wọn yóo sì jẹ èso rẹ̀. N óo fẹsẹ̀ àwọn eniyan mi múlẹ̀ lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn, a kò sì ní ṣí wọn nípò pada mọ́ lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun yín ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Amo 9:7-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Àbá ẹ̀yin ọmọ Israẹli kò ha dàbí àwọn ọmọ Kuṣi sí mi?” ni OLúWA wí. “Èmi kò ha ti mú Israẹli gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá àti àwọn Filistini láti ilẹ̀ Kafitori àti àwọn ará Aramu láti Kiri? “Dájúdájú, ojú OLúWA Olódùmarè ń bẹ̀ lára ilẹ̀ ọba tó kún fún ẹ̀ṣẹ̀. Èmi yóò pa á run kúrò lórí ilẹ̀ Síbẹ̀ Èmi kò nípa ilé Jakọbu run pátápátá,” ni OLúWA wí. “Nítorí Èmi yóò pàṣẹ, Èmi yóò sì mi ilé Israẹli ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè bí a ti ń jọ nǹkan nínú ajọ̀ tí hóró kín ń kín kì yóò bọ́ sórí ilẹ̀. Gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn mi ni yóò ti ipa idà kú gbogbo àwọn ti ń wí pé, ‘Aburú kì yóò lé wa bá, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ká wa mọ́.’ “Ní ọjọ́ náà ní Èmi yóò gbé àgọ́ Dafidi tí ó wó ró, Èmi yóò dí odi rẹ̀ tí ó ya, Èmi yóò sì gbé ahoro rẹ̀ sókè, Èmi yóò sì kọ bí ti ọjọ́ ìgbàanì, kí wọn le jogún ìyókù Edomu àti gbogbo àwọn kèfèrí, ti a ń pè nípa orúkọ mi,” ni OLúWA, ẹni tí yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí wí. “Ọjọ́ náà ń bọ,” ni OLúWA wí, “tí ẹni tí ń tulẹ̀ yóò lé ẹni tí ń kórè bá Tí ẹni tí ń fún èso àjàrà yóò lé ẹni tí ń gbìn bá Àwọn òkè ńlá yóò sì kán ọtí wáìnì sílẹ̀ Tí yóò sì sàn láti ara àwọn òkè kéékèèkéé. Èmi yóò si tún mú ìgbèkùn Israẹli ènìyàn mi padà bọ̀. “Wọn yóò sì kọ́ ahoro ìlú, wọn yóò sì máa gbé inú wọn Wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì mu ọtí wáìnì wọn wọn yóò sì ṣe ọgbà pẹ̀lú, wọn yóò sì jẹ èso inú wọn Èmi yóò gbin Israẹli sí orí ilẹ̀ rẹ̀. A kì yóò sì fà wọn tu mọ́ láéláé kúrò ni orí ilẹ̀ ti mo fi fún wọn,” ni OLúWA Ọlọ́run rẹ wí.