Amo 9:13
Amo 9:13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kiyesi i, ọjọ na de, li Oluwa wi, ti ẹniti ntulẹ yio le ẹniti nkorè bá, ati ẹniti o ntẹ̀ eso àjara yio le ẹniti o nfunrùgbin bá; awọn oke-nla yio si kán ọti-waini didùn silẹ, gbogbo oke kékèké yio si di yiyọ́.
Pín
Kà Amo 9Amo 9:13 Yoruba Bible (YCE)
“Ọjọ́ ń bọ̀, tí ọkà yóo so jìnwìnnì, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè kórè rẹ̀ tán kí àkókò gbígbin ọkà mìíràn tó dé. Ọgbà àjàrà yóo so, tóbẹ́ẹ̀ tí a kò ní lè fi ṣe waini tán kí àkókò ati gbin òmíràn tó dé. Ọtí waini dídùn yóo máa kán sílẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, ọtí waini yóo sì máa ṣàn jáde lára àwọn òkè kéékèèké.
Pín
Kà Amo 9