Amo 7:1-17
Amo 7:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
BAYI li Oluwa Ọlọrun ti fi hàn mi; si wò o, o dá ẽṣú ni ibẹ̀rẹ irú-soke idàgba ikẹhin, si wò o, idàgba ikẹhìn lẹhìn ike-kuro ti ọba nì. O si ṣe, ti nwọn jẹ koriko ilẹ na tan, nigbana ni mo wipe, Oluwa Ọlọrun, darijì, emi bẹ̀ ọ: Jakobu yio ha ṣe le dide? nitori ẹnikekere li on. Oluwa ronupiwàda nitori eyi: Kì yio ṣe, li Oluwa wi. Bayi li Oluwa Ọlọrun ti fi hàn mi: si wò o, Oluwa Ọlọrun pè lati fi iná jà, o si jó ibú nla nì run, o si jẹ apakan run. Nigbana ni mo wipe, Oluwa Ọlọrun, dawọ duro, emi bẹ̀ ọ: Jakobu yio ha ṣe le dide? nitori ẹnikekere li on. Oluwa ronupiwàda nitori eyi: Eyi pẹlu kì yio ṣe, li Oluwa Ọlọrun wi. Bayi li on fi hàn mi: si wò o, Oluwa duro lori odi kan, ti a fi okùn-ìwọn ti o run mọ, ti on ti okùn-ìwọn ti o run li ọwọ́ rẹ̀. Oluwa si wi fun mi pe, Amosi, kini iwọ ri? Emi si wipe, Okùn-ìwọn kan ti o run ni. Nigbana ni Oluwa wipe, Wò o, emi o fi okùn-ìwọn rirun kan le ilẹ lãrin Israeli enia mi: emi kì yio si tun kọja lọdọ wọn mọ: Ibi giga Israeli wọnni yio si di ahoro: ati ibi mimọ́ Israeli wọnni yio di ahoro; emi o si fi idà dide si ile Jeroboamu. Nigbana ni Amasiah, alufa Beteli ranṣẹ si Jeroboamu ọba Israeli, wipe, Amosi ti ditẹ̀ si ọ lãrin ile Israeli: ilẹ kò si le gba gbogbo ọ̀rọ rẹ̀. Nitori bayi li Amosi wi, Jeroboamu yio ti ipa idà kú, nitõtọ Israeli li a o si fà lọ si igbèkun kuro ni ilẹ rẹ̀. Amasiah sọ fun Amosi pẹlu pe, Iwọ ariran, lọ, salọ si ilẹ Juda, si ma jẹun nibẹ̀, si ma sọtẹlẹ nibẹ̀: Ṣugbọn máṣe sọtẹlẹ̀ mọ ni Beteli: nitori ibi mimọ́ ọba ni, ãfin ọba si ni. Nigbana ni Amosi dahùn, o si wi fun Amasiah pe, Emi ki iṣe woli ri, bẹ̃ni emi kì iṣe ọmọ woli, ṣugbọn olùṣọ-agùtan li emi ti iṣe ri, ati ẹniti iti ma ká eso ọpọ̀tọ: Oluwa si mu mi, bi mo ti ntọ̀ agbo-ẹran lẹhìn, Oluwa si wi fun mi pe, Lọ, sọtẹlẹ̀ fun Israeli enia mi. Njẹ nisisiyi, iwọ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: Iwọ wipe, Máṣe sọtẹlẹ̀ si Israeli, má si jẹ ki ọ̀rọ rẹ kán silẹ si ile Isaaki. Nitorina bayi li Oluwa wi; Obinrin rẹ yio di panṣagà ni ilu, ati awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati awọn ọmọ rẹ obinrin, yio ti ipa idà ṣubu; ilẹ rẹ li a o si fi okùn pin; iwọ o si kú ni ilẹ aimọ́: nitõtọ, a o si kó Israeli lọ ni igbèkun kuro ni ilẹ rẹ̀.
Amo 7:1-17 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA Ọlọrun fi ìran kan hàn mí! Ó ń kó ọ̀wọ́ eṣú jọ ní àkókò tí koríko ìkẹyìn bẹ̀rẹ̀ sí yọ sókè, lẹ́yìn tí wọ́n ti gé koríko ti ọba tán. Nígbà tí àwọn eṣú náà ti jẹ gbogbo koríko ilẹ̀ náà tán, mo ní, “OLUWA Ọlọrun, jọ̀wọ́ dáríjì àwọn eniyan rẹ. Báwo ni àwọn ọmọ Jakọbu yóo ṣe là, nítorí pé wọ́n kéré níye?” OLUWA bá yí ìpinnu rẹ̀ pada, ó ní, “Ohun tí o rí kò ní ṣẹlẹ̀.” OLUWA Ọlọrun tún fi ìran mìíràn hàn mí: mo rí i tí Ọlọrun pe iná láti fi jẹ àwọn eniyan rẹ̀ níyà. Iná náà jó ibú omi, ráúráú ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jó ilẹ̀ pàápàá. Nígbà náà ni mo dáhùn pé: “OLUWA Ọlọrun, jọ̀wọ́, dáwọ́ dúró. Báwo ni àwọn ọmọ Jakọbu yóo ṣe là, nítorí wọ́n kéré níye?” OLUWA bá yí ìpinnu rẹ̀ pada, ó ní, “Ohun tí o rí kò ní ṣẹlẹ̀.” OLUWA Ọlọrun tún fi ìran mìíràn hàn mí: mo rí i tí OLUWA mú okùn ìwọ̀n àwọn mọlémọlé lọ́wọ́; ó dúró lẹ́bàá ògiri tí a ti fi okùn ìwọ̀n àwọn mọlémọlé wọ̀n. Ó bi mí pé: “Amosi, kí ni o rí?” Mo bá dáhùn pé, “Okùn ìwọ̀n àwọn mọlémọlé.” Ó ní: “Wò ó! Mo ti fi okùn ìwọ̀n àwọn mọlémọlé sí ààrin àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi; n kò ní fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́. Gbogbo ibi gíga Isaaki yóo di ahoro, ilé mímọ́ Israẹli yóo parun, n óo yọ idà sí ìdílé ọba Jeroboamu.” Nígbà náà ni Amasaya, alufaa Bẹtẹli, ranṣẹ sí Jeroboamu, ọba Israẹli pé: “Amosi ń dìtẹ̀ mọ́ ọ láàrin àwọn ọmọ Israẹli, ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóo sì ba gbogbo ilẹ̀ yìí jẹ́. Ó ń wí pé, ‘Jeroboamu yóo kú sójú ogun, gbogbo ilé Israẹli ni a óo sì kó lẹ́rú lọ.’ ” Amasaya sọ fún Amosi pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, ìwọ aríran, pada lọ sí ilẹ̀ Juda, máa lọ sọ àsọtẹ́lẹ̀ níbẹ̀, kí wọ́n sì máa fún ọ ní oúnjẹ. Má sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní Bẹtẹli mọ́, nítorí ibi mímọ́ ni, fún ọba ati fún gbogbo orílẹ̀-èdè.” Amosi bá dáhùn, ó ní: “Èmi kì í ṣe wolii tabi ọmọ wolii, darandaran ni mí, èmi a sì tún máa tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́. OLUWA ló pè mí níbi iṣẹ́ mi, òun ló ní kí n lọ máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún Israẹli, eniyan òun. Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA nisinsinyii, ṣé o ní kí n má sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli mọ́, kí n má sì waasu fún àwọn ọmọ Isaaki mọ́? Nítorí náà, gbọ́ ohun tí OLUWA sọ: ‘Iyawo rẹ yóo di aṣẹ́wó láàrin ìlú, àwọn ọmọ rẹ lọkunrin ati lobinrin yóo kú sójú ogun, a óo pín ilẹ̀ rẹ fún àwọn ẹlòmíràn; ìwọ pàápàá yóo sì kú sí ilẹ̀ àwọn alaigbagbọ; láìṣe àní àní, a óo kó àwọn ọmọ Israẹli lọ sí ìgbèkùn.’ ”
Amo 7:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èyí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè fihàn mí: Ó pèsè ọwọ́ eṣú lẹ́yìn ìgbà tí a kórè ìpín ọba, ní ìgbà ti èso ẹ̀ẹ̀kejì ń jáde bọ̀. Nígbà tí wọ́n jẹ koríko ilẹ̀ náà mọ́ féfé nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “OLúWA Olódùmarè, mo bẹ̀ ọ́, dáríjì! Báwo ni Jakọbu yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!” OLúWA ronúpìwàdà nípa èyí. “Èyí kò ni ṣẹlẹ̀,” ni OLúWA wí. Èyí ni ohun ti OLúWA Olódùmarè fihàn mí: OLúWA Olódùmarè ń pè fún ìdájọ́ pẹ̀lú iná; ó jó ọ̀gbun ńlá rún, ó sì jẹ ilẹ̀ run. Nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “OLúWA Olódùmarè jọ̀wọ́ má ṣe ṣe é! Báwo ni Jakọbu yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!” OLúWA ronúpìwàdà nípa èyí. “Èyí náà kò ní ṣẹlẹ̀,” ni OLúWA Olódùmarè wí. Èyí ni ohun tí ó fihàn mí: Olúwa dúró ní ẹ̀gbẹ́ odi ti a fi okùn ìwọ̀n mọ́, ti òun ti okùn ìwọ̀n tí ó rún ni ọwọ́ rẹ̀. OLúWA sì bi mi pé, “Amosi, kí ni ìwọ rí?” Mo dáhùn pé, “Okùn ìwọ̀n.” Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Wò ó, Èmí ń gbé okùn ìwọ̀n kalẹ̀ láàrín àwọn Israẹli ènìyàn mi; Èmi kì yóò sì tún kọjá lọ́dọ̀ wọn mọ́. “Ibi gíga Isaaki wọ̀n-ọn-nì yóò sì di ahoro àti ibi mímọ Israẹli wọ̀n-ọn-nì yóò di ahoro. Èmi yóò sì fi idà dìde sí ilé Jeroboamu.” Nígbà náà Amasiah àlùfáà Beteli ránṣẹ́ sí Jeroboamu ọba Israẹli, wí pé: “Amosi ti dìde láti dìtẹ̀ sí ọ ni àárín gbùngbùn Israẹli. Ilẹ̀ kò sì le gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nítorí èyí ni ohun ti Amosi ń sọ: “ ‘Jeroboamu yóò ti ipa idà kú, Lóòtítọ́ Israẹli yóò lọ sí ìgbèkùn, jìnnà kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’ ” Nígbà náà ni Amasiah sọ fún Amosi pé, “Lọ jáde, ìwọ aríran! Padà sí ilẹ̀ àwọn Juda. Kí o máa jẹun rẹ níbẹ̀, kí o sì máa sọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀. Má ṣe sọtẹ́lẹ̀ mọ ni Beteli nítorí ibi mímọ́ ọba ni àti ibi tẹmpili ìjọba rẹ̀.” Amosi dá Amasiah lóhùn pé, “Èmi kì í ṣe wòlíì tàbí àwọn ọmọ wòlíì, ṣùgbọ́n mo jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn, mo sì ń ṣe ìtọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ sikamore. Ṣùgbọ́n OLúWA mu mi bí mo ti ń tọ́ agbo ẹran lẹ́yìn, ó sì wí fun mi pé, ‘Lọ sọtẹ́lẹ̀ fun àwọn Israẹli ènìyàn mi.’ Nítorí náà nísinsin yìí, gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA. Ìwọ wí pé, “ ‘Má ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí Israẹli Má sì ṣe wàásù sí ilé Isaaki.’ “Nítorí náà, èyí ni ohun ti OLúWA wí: “ ‘Ìyàwó rẹ yóò di panṣágà ni ìlú, àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú. A ó fi okùn wọn ilẹ̀ rẹ, a ó sì pín in àti ìwọ pẹ̀lú yóò kú ni ilẹ̀ àìmọ́. Israẹli yóò sì lọ sí ìgbèkùn, kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’ ”