Amo 4:6-9
Amo 4:6-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi pẹlu si ti fun nyin ni mimọ́ ehín ni gbogbo ilu nyin, ati aini onjẹ, ni ibùgbe nyin gbogbo: sibẹ̀ ẹnyin kò yipadà sọdọ mi, li Oluwa wi. Ati pẹlu, emi ti fà ọwọ́ òjo sẹhìn kuro lọdọ nyin, nigbati o kù oṣù mẹta si i fun ikorè; emi si ti mu òjo rọ̀ si ilu kan, emi kò si jẹ ki o rọ̀ si ilu miràn: o rọ̀ si apakan, ibiti kò gbe rọ̀ si si rọ. Bẹ̃ni ilu meji tabi mẹta nrìn lọ si ilu kan, lati mu omi: ṣugbọn kò tẹ́ wọn lọrùn: sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi. Mo ti fi irẹ̀danù ati imúwòdú lù nyin: nigbati ọgbà nyin ati ọgbà-àjara nyin, ati igi ọ̀pọtọ́ nyin, ati igi olifi nyin npọ̀ si i, kòkoro jẹ wọn run; sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi.
Amo 4:6-9 Yoruba Bible (YCE)
“Mo jẹ́ kí ìyàn mú ní gbogbo ìlú yín, kò sì sí oúnjẹ ní gbogbo ilẹ̀ yín; sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. N kò jẹ́ kí òjò rọ̀ mọ́, nígbà tí ìkórè ku oṣù mẹta; mò ń rọ òjò ní ìlú kan, kò sì dé ìlú keji; ó rọ̀ ní oko kan, ó dá ekeji sí, àwọn nǹkan ọ̀gbìn oko tí òjò kò rọ̀ sí sì rọ. Nítorí náà, ìlú meji tabi mẹta ń wá omi lọ sí ẹyọ ìlú kan wọn kò sì rí tó nǹkan; sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Mo jẹ́ kí nǹkan oko yín ati èso àjàrà yín rẹ̀ dànù, mo mú kí wọn rà; eṣú jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ ati igi olifi yín, sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi.
Amo 4:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Èmi fún un yín ní mímọ́ eyín ní gbogbo ìlú yín, àti àìní oúnjẹ ní gbogbo ibùgbé yín, síbẹ̀, ẹ̀yin kò yípadà sọ́dọ̀ mi,” ni OLúWA wí. “Àti pẹ̀lú mo mú òjò dúró nígbà tí ìkórè ku oṣù mẹ́ta. Mo rán òjò sí ibùgbé kan ṣùgbọ́n kò rọ̀ sí ìlú mìíràn. Oko kan ní òjò; àwọn mìíràn kò ní ó sì gbẹ. Àwọn ènìyàn ń rìn láti ìlú kan sí ìlú mìíràn fún omi wọn kò rí mu tẹ́ wọn lọ́rùn, síbẹ̀ ẹ̀yin kò padà sí ọ̀dọ̀ mi,” ni OLúWA wí. “Lọ́pọ̀ ìgbà ni mo kọlu ọgbà àti ọgbà àjàrà yín mo fi ìrẹ̀dànù àti ìmúwòdù lù wọ́n. Eṣú sì jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ àti igi olifi yín, síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni OLúWA wí.