Amo 4:4-13
Amo 4:4-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ wá si Beteli, ki ẹ si dẹṣẹ: ẹ mu irekọja nyin pọ̀ si i ni Gilgali; ẹ si mu ẹbọ nyin wá li orowurọ̀, ati idamẹwa nyin lẹhìn ọdun mẹta. Ki ẹ si ru ẹbọ ọpẹ́ pẹlu iwukara, ẹ kede, ki ẹ si fi ọrẹ atinuwa lọ̀: nitori bẹ̃li ẹnyin fẹ́, ẹnyin ọmọ Israeli, li Oluwa Ọlọrun wi. Emi pẹlu si ti fun nyin ni mimọ́ ehín ni gbogbo ilu nyin, ati aini onjẹ, ni ibùgbe nyin gbogbo: sibẹ̀ ẹnyin kò yipadà sọdọ mi, li Oluwa wi. Ati pẹlu, emi ti fà ọwọ́ òjo sẹhìn kuro lọdọ nyin, nigbati o kù oṣù mẹta si i fun ikorè; emi si ti mu òjo rọ̀ si ilu kan, emi kò si jẹ ki o rọ̀ si ilu miràn: o rọ̀ si apakan, ibiti kò gbe rọ̀ si si rọ. Bẹ̃ni ilu meji tabi mẹta nrìn lọ si ilu kan, lati mu omi: ṣugbọn kò tẹ́ wọn lọrùn: sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi. Mo ti fi irẹ̀danù ati imúwòdú lù nyin: nigbati ọgbà nyin ati ọgbà-àjara nyin, ati igi ọ̀pọtọ́ nyin, ati igi olifi nyin npọ̀ si i, kòkoro jẹ wọn run; sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi. Mo ti rán ajàkalẹ-arùn si ãrin nyin, gẹgẹ bi ti Egipti: awọn ọdọmọkunrin nyin li emi si ti fi idà pa, nwọn si ti kó ẹṣin nyin ni igbèkun pẹlu; mo si ti jẹ ki õrùn ibùdo nyin bù soke wá si imú nyin: sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi. Mo ti bì ṣubu ninu nyin, bi Ọlọrun ti bì Sodomu on Gomorra ṣubu, ẹnyin si dàbi oguná ti a fà yọ kuro ninu ijoná: sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi. Nitorina, bayi li emi o ṣe si ọ, iwọ Israeli: ati nitoriti emi o ṣe eyi si ọ, mura lati pade Ọlọrun rẹ, iwọ Israeli. Nitori sa wò o, ẹniti o dá awọn oke nla, ti o si dá afẹ̃fẹ, ti o si sọ fun enia ohun ti erò inu rẹ̀ jasi, ti o sọ owurọ̀ di òkunkun, ti o si tẹ̀ ibi giga aiye mọlẹ, Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.
Amo 4:4-13 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “Ẹ wá sí Bẹtẹli, kí ẹ wá máa dẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀, kí ẹ sì wá fi ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ ní Giligali; ẹ máa mú ẹbọ yín wá ní àràárọ̀, ati ìdámẹ́wàá yín ní ọjọ́ kẹta kẹta. Ẹ fi burẹdi tí ó ní ìwúkàrà rú ẹbọ ọpẹ́, ẹ kéde ẹbọ àtinúwá, kí ẹ sì fọ́nnu nípa rẹ̀; nítorí bẹ́ẹ̀ ni ẹ fẹ́ máa ṣe, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. “Mo jẹ́ kí ìyàn mú ní gbogbo ìlú yín, kò sì sí oúnjẹ ní gbogbo ilẹ̀ yín; sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. N kò jẹ́ kí òjò rọ̀ mọ́, nígbà tí ìkórè ku oṣù mẹta; mò ń rọ òjò ní ìlú kan, kò sì dé ìlú keji; ó rọ̀ ní oko kan, ó dá ekeji sí, àwọn nǹkan ọ̀gbìn oko tí òjò kò rọ̀ sí sì rọ. Nítorí náà, ìlú meji tabi mẹta ń wá omi lọ sí ẹyọ ìlú kan wọn kò sì rí tó nǹkan; sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. “Mo jẹ́ kí nǹkan oko yín ati èso àjàrà yín rẹ̀ dànù, mo mú kí wọn rà; eṣú jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ ati igi olifi yín, sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. “Mo fi irú àwọn àjàkálẹ̀ àrùn tí ó jà ní Ijipti ba yín jà, mo fi idà pa àwọn ọdọmọkunrin yín lójú ogun; mo kó ẹṣin yín lọ, mo mú kí òórùn àwọn tí wọ́n kú ninu àgọ́ yín wọ̀ yín nímú; sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. Mo pa àwọn kan ninu yín run bí mo ti pa Sodomu ati Gomora run, ẹ dàbí àjókù igi tí a yọ ninu iná; sibẹsibẹ, ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. Nítorí náà, n óo jẹ yín níyà, ẹ̀yin ọmọ Israẹli; nítorí irú ìyà tí n óo fi jẹ yín, ẹ múra sílẹ̀ de ìdájọ́ Ọlọrun yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli!” Ẹ gbọ́! Ọlọrun ni ó dá òkè ńlá ati afẹ́fẹ́, tí ń fi èrò ọkàn rẹ̀ han eniyan, Ọlọrun ní ń sọ òwúrọ̀ di òru, tí sì ń rìn níbi gíga-gíga ayé; OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀!
Amo 4:4-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ẹ lọ sí Beteli láti dẹ́ṣẹ̀; ẹ lọ sí Gilgali kí ẹ sì dẹ́ṣẹ̀ sí i. Ẹ mú ẹbọ sísun yín láràárọ̀ wá, ìdámẹ́wàá yín ní ọdọọdún mẹ́ta. Kí ẹ mú ọ̀rẹ́ ìdúpẹ́ ìyẹ̀fun ìwúkàrà ti a sun kí ẹ sì mú ọrẹ àtinúwá lọ fi wọ́n yangàn, ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, nítorí èyí ni ẹ fẹ́ láti ṣe,” ni OLúWA Olódùmarè wí. “Èmi fún un yín ní mímọ́ eyín ní gbogbo ìlú yín, àti àìní oúnjẹ ní gbogbo ibùgbé yín, síbẹ̀, ẹ̀yin kò yípadà sọ́dọ̀ mi,” ni OLúWA wí. “Àti pẹ̀lú mo mú òjò dúró nígbà tí ìkórè ku oṣù mẹ́ta. Mo rán òjò sí ibùgbé kan ṣùgbọ́n kò rọ̀ sí ìlú mìíràn. Oko kan ní òjò; àwọn mìíràn kò ní ó sì gbẹ. Àwọn ènìyàn ń rìn láti ìlú kan sí ìlú mìíràn fún omi wọn kò rí mu tẹ́ wọn lọ́rùn, síbẹ̀ ẹ̀yin kò padà sí ọ̀dọ̀ mi,” ni OLúWA wí. “Lọ́pọ̀ ìgbà ni mo kọlu ọgbà àti ọgbà àjàrà yín mo fi ìrẹ̀dànù àti ìmúwòdù lù wọ́n. Eṣú sì jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ àti igi olifi yín, síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni OLúWA wí. “Mo rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí i yín bí mo ti ṣe sí Ejibiti. Mo fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín. Pẹ̀lú àwọn ẹṣin tí a kó ní ìgbèkùn. Mo kún imú yín fún òórùn ibùdó yín, síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni OLúWA wí. “Mo ti bì ṣubú nínú yín, bí Ọlọ́run ti bi Sodomu àti Gomorra ṣubú ẹ̀yin sì dàbí ògúnná tí a fa yọ kúrò nínú iná, síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni OLúWA wí. “Nítorí náà, èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí i yín, Israẹli, àti nítorí tí èmi ó ṣe èyí sí i yín, ẹ múra láti pàdé Ọlọ́run yín, ẹ̀yin Israẹli.” Ẹni tí ó dá àwọn òkè tí ó dá afẹ́fẹ́ tí ó sì fi èrò rẹ̀ hàn sí ènìyàn, ẹni tí ó yípadà sí òkùnkùn tí ó sì tẹ ibi gíga ayé. OLúWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.