Amo 3:4-8
Amo 3:4-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kiniun yio ké ramùramù ninu igbo, bi kò ni ohun ọdẹ? ọmọ kiniun yio ha ké jade ninu ihò rẹ̀, bi kò ri nkan mu? Ẹiyẹ le lu okùn ni ilẹ, nibiti okùn didẹ kò gbe si fun u? okùn ha le ré kuro lori ilẹ, laijẹ pe o mu nkan rara? A le fun ipè ni ilu, ki awọn enia má bẹ̀ru? tulasi ha le wà ni ilu, ki o má ṣepe Oluwa li o ṣe e? Nitori Oluwa Ọlọrun kì o ṣe nkan kan, ṣugbọn o fi ohun ikọ̀kọ rẹ̀ hàn awọn woli iranṣẹ rẹ̀. Kiniun ti ké ramùramù, tani kì yio bẹ̀ru? Oluwa Ọlọrun ti sọ̀rọ, tani lè ṣe aisọtẹlẹ?
Amo 3:4-8 Yoruba Bible (YCE)
“Ṣé kinniun a máa bú ninu igbó láìjẹ́ pé ó ti pa ẹran? “Àbí ọmọ kinniun a máa bú ninu ihò rẹ̀ láìṣe pé ọwọ́ rẹ̀ ti ba nǹkan? “Ṣé tàkúté a máa mú ẹyẹ nílẹ̀, láìṣe pé eniyan ló dẹ ẹ́ sibẹ? “Àbí tàkúté a máa ta lásán láìṣe pé ó mú nǹkan? “Ṣé eniyan lè fọn fèrè ogun láàrin ìlú kí àyà ará ìlú má já? “Àbí nǹkan ibi lè ṣẹlẹ̀ ní ìlú láìṣe pé OLUWA ni ó ṣe é? “Dájúdájú OLUWA Ọlọrun kì í ṣe ohunkohun láì kọ́kọ́ fi han àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀. “Kinniun bú ramúramù, ta ni ẹ̀rù kò ní bà? “OLUWA Ọlọrun ti sọ̀rọ̀, ta ló gbọdọ̀ má sọ àsọtẹ́lẹ̀?”
Amo 3:4-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ Kìnnìún yóò ha bú ramúramù nínú igbó, bí kò bá ní ohun ọdẹ? Ọmọ kìnnìún yóò ha ké jáde nínú ìhó rẹ̀ bí kò bá rí ohun kan mú? Ǹjẹ́ ẹyẹ ṣubú sínú okùn ọdẹ lórí ilẹ̀ nígbà tí a kò dẹ okùn ọdẹ fún un? Okùn ọdẹ ha lè hù jáde lórí ilẹ̀ nígbà tí kò sí ohun tí yóò mú? Nígbà tí ìpè bá dún ní ìlú, àwọn ènìyàn kò ha bẹ̀rù? Tí ewu bá wa lórí ìlú kò ha ṣe OLúWA ni ó fà á? Nítòótọ́ OLúWA Olódùmarè kò ṣe ohun kan láìfi èrò rẹ̀ hàn fun àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀. Kìnnìún ti bú ramúramù ta ni kì yóò bẹ̀rù? OLúWA Olódùmarè ti sọ̀rọ̀ ta ni le ṣe àìsọ àsọtẹ́lẹ̀?