Amo 3:1-15

Amo 3:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹ gbọ̀ ọ̀rọ yi ti Oluwa ti sọ si nyin, ẹnyin ọmọ Israeli, si gbogbo idile ti mo mú goke lati ilẹ Egipti wá, wipe, Ẹnyin nikan ni mo mọ̀ ninu gbogbo idile aiye: nitorina emi o bẹ̀ nyin wò nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin. Ẹni meji lè rìn pọ̀, bikòṣepe nwọn rẹ́? Kiniun yio ké ramùramù ninu igbo, bi kò ni ohun ọdẹ? ọmọ kiniun yio ha ké jade ninu ihò rẹ̀, bi kò ri nkan mu? Ẹiyẹ le lu okùn ni ilẹ, nibiti okùn didẹ kò gbe si fun u? okùn ha le ré kuro lori ilẹ, laijẹ pe o mu nkan rara? A le fun ipè ni ilu, ki awọn enia má bẹ̀ru? tulasi ha le wà ni ilu, ki o má ṣepe Oluwa li o ṣe e? Nitori Oluwa Ọlọrun kì o ṣe nkan kan, ṣugbọn o fi ohun ikọ̀kọ rẹ̀ hàn awọn woli iranṣẹ rẹ̀. Kiniun ti ké ramùramù, tani kì yio bẹ̀ru? Oluwa Ọlọrun ti sọ̀rọ, tani lè ṣe aisọtẹlẹ? Ẹ kede li ãfin Aṣdodu, ati li ãfin ni ilẹ Egipti, ki ẹ si wipe, Pè ara nyin jọ lori awọn oke nla Samaria, ki ẹ si wò irọkẹ̀kẹ nla lãrin rẹ̀, ati inilara lãrin rẹ̀. Nitori nwọn kò mọ̀ bi ati ṣe otitọ, li Oluwa wi, nwọn ti kó ìwa-ipá ati ìwa-olè jọ li ãfin wọn. Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ọta kan yio si wà yi ilẹ na ka; on o si sọ agbara rẹ kalẹ kuro lara rẹ, a o si kó ãfin rẹ wọnni. Bayi li Oluwa wi; gẹgẹ bi oluṣọ-agùtan iti gbà itan meji kuro li ẹnu kiniun, tabi ẹlà eti kan; bẹ̃li a o mu awọn ọmọ Israeli ti ngbe Samaria kuro ni igun akete, ati ni aṣọ Damasku irọ̀gbọku. Ẹ gbọ́, ẹ si jẹri si ile Jakobu, li Oluwa Ọlọrun, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi, Pe, li ọjọ ti emi o bẹ̀ irekọja Israeli wò lara rẹ̀, emi o bẹ̀ awọn pẹpẹ Beteli wò pẹlu: a o si ké iwo pẹpẹ kuro, nwọn o si wó lulẹ. Emi o si lù ile otutù pẹlu ile ẹ̃rùn; ile ehín erin yio si ṣègbe, ile nla wọnni yio si li opin, li Oluwa wi.

Amo 3:1-15 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA sọ nípa yín, gbogbo ẹ̀yin tí a kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti: OLUWA ní, “Ẹ̀yin nìkan ni mo mọ̀ láàrin gbogbo aráyé, nítorí náà, n óo jẹ yín níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín. “Ṣé eniyan meji lè jọ máa lọ sí ibìkan láìjẹ́ pé wọ́n ní àdéhùn? “Ṣé kinniun a máa bú ninu igbó láìjẹ́ pé ó ti pa ẹran? “Àbí ọmọ kinniun a máa bú ninu ihò rẹ̀ láìṣe pé ọwọ́ rẹ̀ ti ba nǹkan? “Ṣé tàkúté a máa mú ẹyẹ nílẹ̀, láìṣe pé eniyan ló dẹ ẹ́ sibẹ? “Àbí tàkúté a máa ta lásán láìṣe pé ó mú nǹkan? “Ṣé eniyan lè fọn fèrè ogun láàrin ìlú kí àyà ará ìlú má já? “Àbí nǹkan ibi lè ṣẹlẹ̀ ní ìlú láìṣe pé OLUWA ni ó ṣe é? “Dájúdájú OLUWA Ọlọrun kì í ṣe ohunkohun láì kọ́kọ́ fi han àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀. “Kinniun bú ramúramù, ta ni ẹ̀rù kò ní bà? “OLUWA Ọlọrun ti sọ̀rọ̀, ta ló gbọdọ̀ má sọ àsọtẹ́lẹ̀?” Kéde fún àwọn ibi ààbò Asiria, ati àwọn ibi ààbò ilẹ̀ Ijipti, sọ pé: “Ẹ kó ara yín jọ sí orí àwọn òkè Samaria, kí ẹ sì wo rúdurùdu ati ìninilára tí ń ṣẹlẹ̀ ninu rẹ̀. “Àwọn eniyan wọnyi ń kó nǹkan tí wọ́n fi ipá ati ìdigunjalè gbà sí ibi ààbò wọn, wọn kò mọ̀ bí à á tíí ṣe rere.” Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní: “Ọ̀tá yóo yí ilẹ̀ náà po, wọn yóo wó ibi ààbò yín, wọn yóo sì kó ìṣúra tí ó wà ní àwọn ilé ìṣúra rẹ̀.” OLUWA ní: “Bí olùṣọ́-aguntan tií rí àjẹkù ẹsẹ̀ meji péré, tabi etí kan gbà kalẹ̀ lẹ́nu kinniun, ninu odidi àgbò, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún àwọn ọmọ Israẹli, tí ń gbé Samaria: díẹ̀ ninu wọn ni yóo là, àwọn tí wọn ń sùn lórí ibùsùn olówó iyebíye.” OLUWA Ọlọrun, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní: “Ẹ gbọ́, kí ẹ sì kìlọ̀ fún ìdílé Jakọbu. Ní ọjọ́ tí n óo bá jẹ Israẹli níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, n óo jẹ pẹpẹ Bẹtẹli níyà, n óo kán àwọn ìwo tí ó wà lára pẹpẹ, wọn yóo sì bọ́ sílẹ̀. N óo wó ilé tí ẹ kọ́ fún ìgbà òtútù ati èyí tí ẹ kọ́ fún ìgbà ooru; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ilé tí ẹ fi eyín erin kọ́ ati àwọn ilé ńláńlá yín yóo parẹ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Amo 3:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run ti sọ nípa rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn Israẹli nípa àwọn ìdílé tí mo mú jáde láti Ejibiti: “Ìwọ nìkan ni ẹni tí mo yàn nínú gbogbo àwọn ìran ayé yìí; nígbà náà èmi ó jẹ ọ́ ní yà fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.” Ẹni méjì ha à le rìn pọ̀ láìjẹ́ pé wọ́n ti pinnu láti ṣe bẹ? Ǹjẹ́ Kìnnìún yóò ha bú ramúramù nínú igbó, bí kò bá ní ohun ọdẹ? Ọmọ kìnnìún yóò ha ké jáde nínú ìhó rẹ̀ bí kò bá rí ohun kan mú? Ǹjẹ́ ẹyẹ ṣubú sínú okùn ọdẹ lórí ilẹ̀ nígbà tí a kò dẹ okùn ọdẹ fún un? Okùn ọdẹ ha lè hù jáde lórí ilẹ̀ nígbà tí kò sí ohun tí yóò mú? Nígbà tí ìpè bá dún ní ìlú, àwọn ènìyàn kò ha bẹ̀rù? Tí ewu bá wa lórí ìlú kò ha ṣe OLúWA ni ó fà á? Nítòótọ́ OLúWA Olódùmarè kò ṣe ohun kan láìfi èrò rẹ̀ hàn fun àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀. Kìnnìún ti bú ramúramù ta ni kì yóò bẹ̀rù? OLúWA Olódùmarè ti sọ̀rọ̀ ta ni le ṣe àìsọ àsọtẹ́lẹ̀? Ẹ kéde ní ààfin Aṣdodu àti ní ààfin ní ilẹ̀ Ejibiti. “Ẹ kó ara yín jọ sí orí òkè ńlá Samaria; Kí ẹ sì wo ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láàrín rẹ̀ àti ìnilára láàrín àwọn ènìyàn rẹ.” “Wọn kò mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe rere,” ni OLúWA wí, “àwọn ẹni tí ó gba àwọn ìwà ipá àti olè sí ààfin rẹ̀.” Nítorí náà, báyìí ni OLúWA Olódùmarè wí: “Àwọn ọ̀tá yóò pa ilẹ̀ náà run; yóò wó ibi gíga yín palẹ̀ a ó sì ba ààfin rẹ̀ jẹ́.” Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “Bí olusọ-àgùntan ti ń gbà itan méjì kúrò ní ẹnu kìnnìún tàbí ẹ̀là etí kan bẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Israẹli, tí ń gbé Samaria kúrò ní igun ibùsùn wọn ní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Damasku.” “Gbọ́ èyí kí o sì jẹ́rìí nípa ilé Jakọbu,” ni Olúwa wí, OLúWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. “Ní ọjọ́ tí mo fìyà jẹ Israẹli lórí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, Èmi yóò pa pẹpẹ Beteli run; ìwo pẹpẹ ni a ó ké kúrò yóò sì wó lulẹ̀. Èmi yóò wó ilé òtútù lulẹ̀ pẹ̀lú ilé ooru; ilé tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ yóò ṣègbé a ó sì pa ilé ńlá náà run,” ni OLúWA wí.